AISAYA 25
25
Orin Ìyìn
1OLUWA, ìwọ ni Ọlọrun mi.
N óo gbé ọ ga:
n óo yin orúkọ rẹ.
Nítorí pé o ti ṣe àwọn nǹkan ìyanu,
o ti ṣe àwọn ètò láti ìgbà àtijọ́,
o mú wọn ṣẹ pẹlu òtítọ́.
2O sọ àwọn ìlú di òkítì àlàpà
o sì ti pa àwọn ìlú olódi run.
O wó odi gíga àwọn àjèjì, kúrò lẹ́yìn ìlú,
ẹnikẹ́ni kò sì ní tún un kọ́ mọ́.
3Nítorí náà àwọn alágbára yóo máa yìn ọ́
ìlú àwọn orílẹ̀-èdè aláìláàánú yóo bẹ̀rù rẹ.
4Nítorí pé ìwọ ni ibi ìsádi fún talaka,
ibi ìsápamọ́sí fún aláìní lákòókò ìṣòro.
Ìwọ ni ibi ààbò nígbà òjò,
ati ìbòòji ninu oòrùn.
Nítorí bí ìjì ti rí lára ògiri
bẹ́ẹ̀ ni ibinu aláìláàánú rí;
5ó dàbí ooru ninu aṣálẹ̀.
O pa àwọn àjèjì lẹ́nu mọ́;
bí òjìji ìkùukùu tií sé ooru mọ́,
bẹ́ẹ̀ ni o ṣe dá orin mọ́ àwọn oníjàgídíjàgan lẹ́nu.
Ọlọrun se Àsè Ńlá
6OLUWA àwọn ọmọ ogun yóo fi àwọn ẹran ọlọ́ràá se àsè kan fún gbogbo orílẹ̀-èdè; yóo pa àwọn ẹran àbọ́pa, pẹlu ọtí waini, ẹran àbọ́pa tí ó sanra, tí ó kún fún mùdùnmúdùn, ati ọtí waini tí ó dára. 7Lórí òkè yìí, OLUWA yóo fa aṣọ tí a ta bo àwọn eniyan lójú ya, àní aṣọ tí a dà bo gbogbo orílẹ̀-èdè mọ́lẹ̀. 8Yóo gbé ikú mì títí lae, OLUWA yóo nu omijé nù kúrò lójú gbogbo eniyan. Yóo mú ẹ̀gàn àwọn eniyan rẹ̀ kúrò, ní gbogbo ilẹ̀ ayé. OLUWA ló sọ bẹ́ẹ̀.#a 1 Kọr 15:54; b Ifi 7:17; 21:4
9Wọn óo máa wí ní ọjọ́ náà pé, “Ọlọrun wa nìyí; a ti ń dúró dè é kí ó lè gbà wá, OLUWA nìyí; òun ni a ti ń dúró dè. Ẹ jẹ́ kí á máa yọ̀, kí inú wa sì dùn nítorí ìgbàlà rẹ̀.”
Ọlọrun Yóo Jẹ Moabu Níyà
10Nítorí OLUWA yóo na ọwọ́ ààbò rẹ̀ sórí òkè yìí. Ṣugbọn àwọn ará Moabu yóo di àtẹ̀mọ́lẹ̀ lórí ilẹ̀ wọ́n, bíi koríko tí a tẹ̀ mọ́lẹ̀ lórí ààtàn. 11Wọn óo na ọwọ́ ní ààrin rẹ̀ bí ìgbà tí ẹni tí ń lúwẹ̀ẹ́ bá nawọ́ ninu omi. Ṣugbọn OLUWA yóo rẹ ìgbéraga wọn sílẹ̀, ọwọ́ wọn yóo sì rọ. 12OLUWA yóo bi odi gíga rẹ̀ wó, yóo wó o palẹ̀, yóo sì sọ ọ́ di erùpẹ̀ ilẹ̀.#Ais 15:1–16:14; Jer 48:1-47; Isi 25:8-11; Amos 2:1-3 Sef 2:8-11
Àwon tá yàn lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí:
AISAYA 25: YCE
Ìsàmì-sí
Pín
Daako
Ṣé o fẹ́ fi àwọn ohun pàtàkì pamọ́ sórí gbogbo àwọn ẹ̀rọ rẹ? Wọlé pẹ̀lú àkántì tuntun tàbí wọlé pẹ̀lú àkántì tí tẹ́lẹ̀
Bible Society of Nigeria © 1900/2010