AISAYA 24
24
OLUWA Yóo Jẹ Ilẹ̀ Ayé Níyà
1Ẹ wò ó! OLUWA yóo fọ́ gbogbo ayé wómúwómú
yóo sì sọ ọ́ di ahoro.
Yóo dojú rẹ̀ rú,
yóo sì fọ́n àwọn eniyan inú rẹ̀ ká.
2Ohun tí ó ṣẹlẹ̀ sí àwọn ará ìlú ni yóo ṣẹlẹ̀ sí alufaa;
ohun tí ó ṣẹlẹ̀ sí ẹrú yóo ṣẹlẹ̀ sí olówó rẹ̀;
ohun tí ó ṣe ọmọ-ọ̀dọ̀ ni yóo ṣe ọ̀gá rẹ̀;
ohun tí ó ṣe ẹni tí ń rà ni yóo ṣe ẹni tí ń tà.
Ohun tí ó ṣe ẹni tí ń yá ni lówó
ni yóo ṣe ẹni tí à ń yá lówó.
Ohun tí ó ṣe onígbèsè ni yóo ṣe ẹni tí a jẹ lówó.
3Ogun yóo kó ilé ayé,
yóo di òfo patapata.
Nítorí OLUWA ni ó sọ bẹ́ẹ̀.
4Ilẹ̀ ń ṣọ̀fọ̀, gbogbo nǹkan ń rọ.
Ayé ń joró, ó sì ń ṣá
àwọn ọ̀run ń joró pẹlu.
5Àwọn tí ń gbé inú ayé ti ba ilé ayé jẹ́,
nítorí pé wọ́n ti rú àwọn òfin
wọ́n ti tàpá sí àwọn ìlànà
wọ́n sì da majẹmu ayérayé.
6Nítorí náà ègún ń pa ayé run lọ.
Àwọn eniyan inú rẹ̀ ń jìyà ẹ̀ṣẹ̀ wọn,
iná ń jó àwọn olùgbé inú rẹ̀,
eniyan díẹ̀ ni ó sì kù.
7Ọtí waini ń ṣọ̀fọ̀.
Igi èso àjàrà ń joró,
gbogbo àwọn tí ń ṣe àríyá ti ń kẹ́dùn.
8Ìró ìlù ayọ̀ ti dákẹ́,
ariwo àwọn alárìíyá ti dópin.
Àwọn tí ń tẹ dùùrù ti dáwọ́ dúró.
9Wọn kò mu ọtí níbi tí wọ́n ti ń kọrin mọ́
ọtí líle sì korò lẹ́nu àwọn tí ń mu ún.
10Ìlú ìdàrúdàpọ̀ ti wó palẹ̀, ó ti dòfo,
gbogbo ìlẹ̀kùn ilé ti tì, kò sì sí ẹni tí ó lè wọlé.
11Ariwo ta lóde nítorí kò sí ọtí waini,
oòrùn ayọ̀ ti wọ̀;
ayọ̀ di àwátì ní ilẹ̀ náà.
12Gbogbo ìlú ti di ahoro,
wọ́n ti wó ẹnu ibodè ìlú wómúwómú.
13Bẹ́ẹ̀ ní yóo rí ní ilẹ̀ ayé,
láàrin àwọn orílẹ̀-èdè
bí igi olifi tí a ti gbọn gbogbo èso rẹ̀ sílẹ̀,
lẹ́yìn tí a ti kórè tán ninu ọgbà àjàrà.
14Wọ́n gbé ohùn wọn sókè, wọ́n ń kọrin ayọ̀,
wọ́n ń yin OLUWA lógo láti ìhà ìwọ̀-oòrùn wá.
15Nítorí náà ẹ fi ògo fún OLUWA ní ìhà ìlà-oòrùn;
ẹ̀yin tí ń gbé etí òkun,
ẹ fògo fún OLUWA Ọlọrun Israẹli.
16Láti òpin ayé ni a ti ń gbọ́ ọpọlọpọ orin ìyìn,
wọ́n ń fi ògo fún Olódodo.
Ṣugbọn èmi sọ pé:
“Mò ń rù, mò ń joro,
mò ń joro, mo gbé!
Nítorí pé àwọn ọ̀dàlẹ̀ ń dalẹ̀,
wọ́n ń dalẹ̀, wọ́n ń hùwà àgàbàgebè.”
17Ẹ̀rù ati kòtò, ati tàkúté ń bẹ níwájú yín ẹ̀yin tí ẹ̀ ń gbé ilẹ̀ ayé.
18Ẹni tí ẹ̀rù bá bà tí ó sá,
yóo já sinu kòtò,
ẹni tí ó bá rá pálá jáde ninu kòtò
yóo kó sinu tàkúté.
Nítorí pé àwọn fèrèsé ojú ọ̀run ti ṣí,
àwọn ìpilẹ̀ṣẹ̀ ayé sì mì tìtì.
19Ayé ti fọ́, ayé ti fàya,
ayé sì mì tìtì.
20Ayé ń ta gbọ̀n-ọ́n-gbọ̀n-ọ́n bí ọ̀mùtí,
ó ń mì bí abà oko.
Ẹrù ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀ wọ̀ ọ́ lọ́rùn,
ó wó lulẹ̀, kò ní dìde mọ́.
21Ní àkókò náà,
OLUWA yóo fìyà jẹ àwọn ogun ọ̀run, lọ́run;
ati àwọn ọba ayé, lórí ilẹ̀ ayé.
22A óo gbá gbogbo wọn jọ pọ̀ sinu kòtò bí ẹlẹ́wọ̀n,
wọn óo wà ní àtìmọ́lé ninu ẹ̀wọ̀n.
Lẹ́yìn ọpọlọpọ ọjọ́, a óo fìyà jẹ wọ́n.
23Òṣùpá yóo dààmú,
ìtìjú yóo sì bá oòrùn.
Nítorí OLUWA àwọn ọmọ-ogun yóo jọba
lórí òkè Sioni ati ní Jerusalẹmu.
Yóo sì fi ògo rẹ̀ hàn
níwájú àwọn àgbààgbà wọn.
Àwon tá yàn lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí:
AISAYA 24: YCE
Ìsàmì-sí
Pín
Daako
Ṣé o fẹ́ fi àwọn ohun pàtàkì pamọ́ sórí gbogbo àwọn ẹ̀rọ rẹ? Wọlé pẹ̀lú àkántì tuntun tàbí wọlé pẹ̀lú àkántì tí tẹ́lẹ̀
Bible Society of Nigeria © 1900/2010