1
AISAYA 43:19
Yoruba Bible
Ẹ wò ó! Mò ń ṣe nǹkan titun ó ti yọ jáde nisinsinyii, àbí ẹ kò ṣe akiyesi rẹ̀? N óo la ọ̀nà ninu aginjù, n óo sì mú kí omi máa ṣàn ninu aṣálẹ̀.
Ṣe Àfiwé
Ṣàwárí AISAYA 43:19
2
AISAYA 43:2
Nígbà tí o bá ń la ibú omi kọjá, n óo wà pẹlu rẹ; nígbà tí o bá la odò ńlá kọjá, kò ní bò ọ́ mọ́lẹ̀, nígbà tí o bá ń kọjá ninu iná, kò ní jó ọ. Ahọ́n iná kò ní jó ọ run.
Ṣàwárí AISAYA 43:2
3
AISAYA 43:18
ÓLUWA ní, “Ẹ gbàgbé àwọn ohun àtijọ́, kí ẹ sì mú ọkàn kúrò ninu ohun tí ó ti kọjá.
Ṣàwárí AISAYA 43:18
4
AISAYA 43:1
Ṣugbọn nisinsinyii, Jakọbu, gbọ́ nǹkan tí OLUWA ẹlẹ́dàá rẹ wí, Israẹli, gbọ́ ohun tí ẹni tí ó dá ọ sọ. Ó ní, “Má bẹ̀rù, nítorí mo ti rà ọ́ pada; mo ti pè ọ́ ní orúkọ rẹ, èmi ni mo ni ọ́.
Ṣàwárí AISAYA 43:1
5
AISAYA 43:4
Nítorí pé o ṣọ̀wọ́n lójú mi, o níyì, mo sì fẹ́ràn rẹ, mo fi àwọn eniyan rọ́pò rẹ; mo sì fi ẹ̀mí àwọn orílẹ̀-èdè dípò ẹ̀mí rẹ.
Ṣàwárí AISAYA 43:4
6
AISAYA 43:3
Nítorí èmi ni OLUWA Ọlọrun rẹ, Ẹni Mímọ́ Israẹli, Olùgbàlà rẹ. Mo fi Ijipti, lélẹ̀, láti rà ọ́ pada, mo sì fi Etiopia ati Seba lélẹ̀ mo ti fi ṣe pàṣípààrọ̀ rẹ.
Ṣàwárí AISAYA 43:3
7
AISAYA 43:5
Má bẹ̀rù nítorí mo wà pẹlu rẹ, n óo kó àwọn ọmọ rẹ wá láti ìlà oòrùn, n óo sì ko yín jọ láti ìwọ̀ oòrùn.
Ṣàwárí AISAYA 43:5
8
AISAYA 43:25
Èmi, èmi ni mo pa ẹ̀ṣẹ̀ yín rẹ́, nítorí ti ara mi; n kò sì ní ranti àwọn ẹ̀ṣẹ̀ yín mọ́.
Ṣàwárí AISAYA 43:25
9
AISAYA 43:10
OLUWA ní, “Ẹ̀yin ni ẹlẹ́rìí mi, ẹ̀yin ni iranṣẹ mi tí mo yàn; kí ẹ lè mọ̀ mí, kí ẹ sì gbà mí gbọ́, kí ó sì ye yín pé, Èmi ni. A kò dá Ọlọrun kankan ṣáájú mi, òmíràn kò sì ní wáyé lẹ́yìn mi.
Ṣàwárí AISAYA 43:10
10
AISAYA 43:11
“Èmi ni OLUWA, kò sí olùgbàlà kan, yàtọ̀ sí mi.
Ṣàwárí AISAYA 43:11
11
AISAYA 43:13
Èmi ni Ọlọrun, láti ìsinsìnyìí lọ, Èmi ni. Kò sí ẹnìkan tí ó lè gba eniyan kalẹ̀ lọ́wọ́ mi: Ta ni le dínà ohun tí mo bá níí ṣe?”
Ṣàwárí AISAYA 43:13
12
AISAYA 43:20-21
Àwọn ẹranko ìgbẹ́ yóo máa yìn mí lógo, ati àwọn ọ̀fàfà ati ògòǹgò; nítorí pé mo ti ṣe odò ńlá fún wọn ninu aṣálẹ̀, kí àwọn àyànfẹ́ mi lè máa rí omi mu: Àwọn tí mo fọwọ́ mi dá fún ara mi, kí wọ́n lè kéde ògo mi.
Ṣàwárí AISAYA 43:20-21
13
AISAYA 43:6-7
N óo pàṣẹ fún ìhà àríwá pé, ‘Dá wọn sílẹ̀.’ N óo sọ fún ìhà gúsù pé, ‘O kò gbọdọ̀ dá wọn dúró.’ Kó àwọn ọmọ mi ọkunrin wá láti òkèèrè, sì kó àwọn ọmọ mi obinrin wá láti òpin ayé, gbogbo àwọn tí à ń fi orúkọ mi pè, àwọn tí mo dá fún ògo mi, àwọn tí mo fi ọwọ́ mi ṣẹ̀dá wọn.”
Ṣàwárí AISAYA 43:6-7
14
AISAYA 43:16-17
OLUWA tí ó la ọ̀nà sí ojú òkun, tí ó la ọ̀nà lórí agbami ńlá; ẹni tí ó kó kẹ̀kẹ́ ogun ati ẹṣin jáde, ogun, ati àwọn ọmọ-ogun; wọ́n dùbúlẹ̀ wọn kò lè dìde mọ́, wọ́n kú bí iná fìtílà.
Ṣàwárí AISAYA 43:16-17
15
AISAYA 43:15
Èmi ni OLUWA, Ẹni Mímọ́ yín, Ẹlẹ́dàá Israẹli, Ọba yín.”
Ṣàwárí AISAYA 43:15
Ilé
Bíbélì
Àwon ètò
Àwon Fídíò