Ṣá ti gbà pé o jẹ̀bi,
ati pé o ti ṣọ̀tẹ̀ sí èmi OLUWA Ọlọrun rẹ.
O ti fi ògo rẹ wọ́lẹ̀ fún àwọn àjèjì oriṣa,
lábẹ́ gbogbo igi tútù;
o kò sì gbọ́ràn sí mi lẹ́nu.
Èmi OLUWA ni mo sọ bẹ́ẹ̀.’
“Ẹ yipada, ẹ̀yin alaiṣootọ ọmọ, nítorí èmi ni Oluwa yín. N óo yan ẹnìkọ̀ọ̀kan ninu yín láti inú ìlú kọ̀ọ̀kan, n óo mú meji meji láti inú agbo ilé kọ̀ọ̀kan, n óo sì ko yín wá sí Sioni.