1
ÌFIHÀN 8:1
Yoruba Bible
Nígbà tí Ọ̀dọ́ Aguntan náà tú èdìdì keje, gbogbo ohun tí ó wà ní ọ̀run parọ́rọ́ fún bí ìdajì wakati kan.
Ṣe Àfiwé
Ṣàwárí ÌFIHÀN 8:1
2
ÌFIHÀN 8:7
Ekinni fun kàkàkí rẹ̀. Ni yìnyín ati iná pẹlu ẹ̀jẹ̀ bá tú dà sórí ilẹ̀ ayé. Ìdámẹ́ta ayé bá jóná, ati ìdámẹ́ta àwọn igi ati gbogbo koríko tútù.
Ṣàwárí ÌFIHÀN 8:7
3
ÌFIHÀN 8:13
Mo tún rí ìran yìí. Mo gbọ́ tí idì kan tí ń fò ní agbede meji ọ̀run ń kígbe pé, “Ó ṣe! Ó ṣe! Ó ṣe fún gbogbo ẹ̀yin tí ẹ̀ ń gbé orí ilẹ̀ ayé nígbà tí kàkàkí tí àwọn angẹli mẹta yòókù fẹ́ fun bá dún!”
Ṣàwárí ÌFIHÀN 8:13
4
ÌFIHÀN 8:8
Angẹli keji fun kàkàkí rẹ̀. Ni a bá ju nǹkankan tí ó dàbí òkè gíga tí ó ń jóná sinu òkun. Ó bá sọ ìdámẹ́ta òkun di ẹ̀jẹ̀.
Ṣàwárí ÌFIHÀN 8:8
5
ÌFIHÀN 8:10-11
Angẹli kẹta fun kàkàkí rẹ̀. Ìràwọ̀ ńlá kan bá já bọ́ láti ọ̀run. Ó bẹ̀rẹ̀ sí jóná bí ògùṣọ̀. Ó bá já sinu ìdámẹ́ta àwọn odò ati ìsun omi. Orúkọ ìràwọ̀ náà ni “Igi-kíkorò.” Ó mú kí ìdámẹ́ta omi korò, ọ̀pọ̀ eniyan ni ó sì kú nítorí oró tí ó wà ninu omi.
Ṣàwárí ÌFIHÀN 8:10-11
6
ÌFIHÀN 8:12
Angẹli kẹrin fun kàkàkí rẹ̀, ìdámẹ́ta oòrùn kò bá lè ràn mọ́; ati ìdámẹ́ta òṣùpá, ati ìdámẹ́ta àwọn ìràwọ̀. Ìdámẹ́ta wọn ṣókùnkùn, kò bá sí ìmọ́lẹ̀ fún ìdámẹ́ta ọ̀sán ati ìdámẹ́ta òru.
Ṣàwárí ÌFIHÀN 8:12
Ilé
Bíbélì
Àwon ètò
Àwon Fídíò