Àwọn eniyan tí ó kù, tí wọn kò kú ninu àjàkálẹ̀ àrùn yìí kò ronupiwada. Wọn kò kọ iṣẹ́ ọwọ́ wọn tí wọn ń bọ sílẹ̀. Ṣugbọn wọ́n tún ń sin àwọn ẹ̀mí burúkú, ati oriṣa wúrà, ti fadaka, ti idẹ, ti òkúta, ati ti igi. Àwọn oriṣa tí kò lè ríran, wọn kò lè gbọ́ràn, bẹ́ẹ̀ ni wọn kò lè rìn. Àwọn eniyan náà kò ronupiwada kúrò ninu ìwà ìpànìyàn, ìwà oṣó, ìwà àgbèrè ati ìwà olè wọn.