ÌFIHÀN 8
8
Ọ̀dọ́ Aguntan Tú Èdìdì Keje
1Nígbà tí Ọ̀dọ́ Aguntan náà tú èdìdì keje, gbogbo ohun tí ó wà ní ọ̀run parọ́rọ́ fún bí ìdajì wakati kan. 2Mo bá rí àwọn angẹli meje tí wọn máa ń dúró níwájú Ọlọrun, a fún wọn ní kàkàkí meje.
3Angẹli mìíràn tún dé, ó dúró lẹ́bàá pẹpẹ ìrúbọ. Ó mú àwo turari tí wọ́n fi wúrà ṣe lọ́wọ́. A fún un ní turari pupọ kí ó fi rúbọ pẹlu adura gbogbo àwọn eniyan Ọlọrun lórí pẹpẹ ìrúbọ wúrà tí ó wà níwájú ìtẹ́ náà.#a Amos 9:1; b Eks 30:1,3 4Èéfín turari ati adura àwọn eniyan Ọlọrun gòkè lọ siwaju Ọlọrun láti ọwọ́ angẹli náà. 5Angẹli náà bá mú àwo turari yìí, ó bu iná láti orí pẹpẹ ìrúbọ kún inú rẹ̀, ó bá jù ú sí orí ilẹ̀ ayé. Ààrá bá bẹ̀rẹ̀ sí sán, mànàmáná ń kọ, ilẹ̀ bẹ̀rẹ̀ sí mì tìtì.#a Lef 16:12; Isi 10:2; b Eks 19:16; Ifi 11:19; 16:18
Àwọn Kàkàkí Mẹfa
6Àwọn angẹli meje tí wọ́n mú kàkàkí meje lọ́wọ́ bá múra láti fun kàkàkí wọn.
7Ekinni fun kàkàkí rẹ̀. Ni yìnyín ati iná pẹlu ẹ̀jẹ̀ bá tú dà sórí ilẹ̀ ayé. Ìdámẹ́ta ayé bá jóná, ati ìdámẹ́ta àwọn igi ati gbogbo koríko tútù.#Ọgb 11:5–12:2 #Eks 9:23-25; Isi 38:22
8Angẹli keji fun kàkàkí rẹ̀. Ni a bá ju nǹkankan tí ó dàbí òkè gíga tí ó ń jóná sinu òkun. Ó bá sọ ìdámẹ́ta òkun di ẹ̀jẹ̀. 9Ìdámẹ́ta gbogbo ohun ẹlẹ́mìí tí ó wà ninu òkun ni wọ́n kú. Ìdámẹ́ta àwọn ọkọ̀ ojú òkun ni wọ́n sì fọ́ túútúú.
10Angẹli kẹta fun kàkàkí rẹ̀. Ìràwọ̀ ńlá kan bá já bọ́ láti ọ̀run. Ó bẹ̀rẹ̀ sí jóná bí ògùṣọ̀. Ó bá já sinu ìdámẹ́ta àwọn odò ati ìsun omi.#Ais 14:12 11Orúkọ ìràwọ̀ náà ni “Igi-kíkorò.” Ó mú kí ìdámẹ́ta omi korò, ọ̀pọ̀ eniyan ni ó sì kú nítorí oró tí ó wà ninu omi.#Jer 9:15
12Angẹli kẹrin fun kàkàkí rẹ̀, ìdámẹ́ta oòrùn kò bá lè ràn mọ́; ati ìdámẹ́ta òṣùpá, ati ìdámẹ́ta àwọn ìràwọ̀. Ìdámẹ́ta wọn ṣókùnkùn, kò bá sí ìmọ́lẹ̀ fún ìdámẹ́ta ọ̀sán ati ìdámẹ́ta òru.#Ais 13:10; Isi 32:7; Jọel 2:10, 31; 3:15
13Mo tún rí ìran yìí. Mo gbọ́ tí idì kan tí ń fò ní agbede meji ọ̀run ń kígbe pé, “Ó ṣe! Ó ṣe! Ó ṣe fún gbogbo ẹ̀yin tí ẹ̀ ń gbé orí ilẹ̀ ayé nígbà tí kàkàkí tí àwọn angẹli mẹta yòókù fẹ́ fun bá dún!”
Àwon tá yàn lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí:
ÌFIHÀN 8: YCE
Ìsàmì-sí
Pín
Daako
Ṣé o fẹ́ fi àwọn ohun pàtàkì pamọ́ sórí gbogbo àwọn ẹ̀rọ rẹ? Wọlé pẹ̀lú àkántì tuntun tàbí wọlé pẹ̀lú àkántì tí tẹ́lẹ̀
Bible Society of Nigeria © 1900/2010