ÌFIHÀN 7

7
Ọ̀kẹ́ Meje Ó Lé Ẹgbaaji (144,000) Eniyan Israẹli
1Lẹ́yìn èyí, mo rí àwọn angẹli mẹrin tí wọ́n dúró ní igun mẹrẹẹrin ayé, tí wọ́n di afẹ́fẹ́ mẹrẹẹrin ayé mú kí afẹ́fẹ́ má baà fẹ́ lórí ilẹ̀ ayé ati lórí òkun ati lára gbogbo igi.#Jer 49:36; Dan 7:2; Sak 6:5 2Mo bá tún rí angẹli mìíràn tí ó gòkè wá láti ìhà ìlà oòrùn, tí ó mú èdìdì Ọlọrun alààyè lọ́wọ́. Ó kígbe lóhùn rara sí àwọn angẹli mẹrẹẹrin tí a fún ní agbára láti ṣe ayé ní jamba. 3Ó ní, “Ẹ má ì tíì ṣe ilẹ̀ ayé ati òkun ati àwọn igi ní jamba títí tí a óo fi fi èdìdì sí àwọn iranṣẹ Ọlọrun wa níwájú.”#Isi 9:4,6 4Mo gbọ́ iye àwọn tí a fi èdìdì sí níwájú, wọ́n jẹ́ ọ̀kẹ́ meje eniyan ó lé ẹgbaaji (144,000) láti inú gbogbo ẹ̀yà ọmọ Israẹli: 5-8Láti inú ẹ̀yà Juda ẹgbaafa (12,000) ni a fi èdìdì sí níwájú, láti inú ẹ̀yà Reubẹni, ẹgbaafa (12,000), láti inú ẹ̀yà Gadi, ẹgbaafa (12,000); láti inú ẹ̀yà Aṣeri, ẹgbaafa (12,000), láti inú ẹ̀yà Nafutali, ẹgbaafa (12,000) láti inú ẹ̀yà Manase, ẹgbaafa (12,000), láti inú ẹ̀yà Simeoni, ẹgbaafa (12,000), láti inú ẹ̀yà Lefi, ẹgbaafa (12,000), láti inú ẹ̀yà Isakari, ẹgbaafa (12,000), láti inú ẹ̀yà Sebuluni ẹgbaafa (12,000), láti inú ẹ̀yà Josẹfu, ẹgbaafa (12,000), láti inú ẹ̀yà Bẹnjamini, ẹgbaafa (12,000).
Àwọn Aṣẹ́gun láti Gbogbo Orílẹ̀-Èdè
9Lẹ́yìn náà, mo rí ọ̀pọ̀ eniyan tí ẹnikẹ́ni kò lè kà láti gbogbo orílẹ̀-èdè ati ẹ̀yà, ati oríṣìíríṣìí èdè, wọ́n dúró níwájú ìtẹ́ náà ati níwájú Ọ̀dọ́ Aguntan. Wọ́n wọ aṣọ funfun. Wọ́n mú imọ̀ ọ̀pẹ lọ́wọ́. 10Wọ́n wá ń kígbe pé, “Ti Ọlọrun wa tí ó jókòó lórí ìtẹ́, ati ti Ọ̀dọ́ Aguntan ni ìgbàlà.” 11Gbogbo àwọn angẹli tí ó dúró yí ìtẹ́ náà ká, ati àwọn àgbààgbà mẹrinlelogun ati àwọn ẹ̀dá alààyè mẹrin dojúbolẹ̀ níwájú ìtẹ́ náà, wọ́n júbà Ọlọrun. 12Wọ́n ń wí pé, “Amin! Ìyìn, ògo, ọgbọ́n, ọpẹ́, ọlá, agbára ati ipá ni fún Ọlọrun wa lae ati laelae. Amin!”
13Ọ̀kan ninu àwọn àgbààgbà mẹrinlelogun yìí bi mí pé, “Ta ni àwọn wọnyi tí a wọ̀ ní aṣọ funfun? Níbo ni wọ́n sì ti wá?”
14Mo bá dá a lóhùn pé, “Alàgbà, ìwọ ni ó mọ̀ wọ́n.”#Dan 12:1; Mat 24:21; Mak 13:19
Ó wá sọ fún mi pé, “Àwọn wọnyi ni wọ́n ti kọjá ninu ọpọlọpọ ìpọ́njú. Wọ́n ti fọ aṣọ wọn, wọ́n ti sọ wọ́n di funfun ninu ẹ̀jẹ̀ Ọ̀dọ́ Aguntan. 15Nítorí èyí ni wọ́n ṣe wà níwájú ìtẹ́ Ọlọrun, tí wọn ń júbà tọ̀sán-tòru ninu Tẹmpili rẹ̀. Ẹni tí ó jókòó lórí ìtẹ́ náà yóo máa bá wọn gbé. 16Ebi kò ní pa wọ́n mọ́, bẹ́ẹ̀ ni òùngbẹ kò ní gbẹ wọ́n mọ́. Oòrùn kò ní pa wọ́n mọ́, ooru kankan kò sì ní mú wọn mọ́.#Ais 49:10 17Nítorí Ọ̀dọ́ Aguntan tí ó wà láàrin ìtẹ́ náà ni yóo máa ṣe olùtọ́jú wọn, yóo máa dà wọ́n lọ síbi ìsun omi ìyè.
Ọlọrun yóo wá nu gbogbo omijé kúrò ní ojú wọn.”#a O. Daf 23:1; Isi 34:23; b O. Daf 23:2; Ais 49:10; d Ais 25:8

Àwon tá yàn lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí:

ÌFIHÀN 7: YCE

Ìsàmì-sí

Pín

Daako

None

Ṣé o fẹ́ fi àwọn ohun pàtàkì pamọ́ sórí gbogbo àwọn ẹ̀rọ rẹ? Wọlé pẹ̀lú àkántì tuntun tàbí wọlé pẹ̀lú àkántì tí tẹ́lẹ̀