1
Esek 18:32
Bibeli Mimọ
YBCV
Nitoripe emi kò ni inu didùn si ikú ẹniti o kú, ni Oluwa Ọlọrun wi: nitorina ẹ yi ara nyin pada, ki ẹ si yè.
Ṣe Àfiwé
Ṣàwárí Esek 18:32
2
Esek 18:20
Ọkàn ti o ba ṣẹ̀, on o kú. Ọmọ kì yio rù aiṣedẽde baba, bẹ̃ni baba kì yio rù aiṣedẽde ọmọ: ododo olododo yio wà lori rẹ̀, ìwa buburu enia buburu yio si wà lori rẹ̀.
Ṣàwárí Esek 18:20
3
Esek 18:31
Ẹ ta gbogbo irekọja nyin nù kuro lọdọ nyin, nipa eyiti ẹnyin fi rekọja; ẹ si dá ọkàn titun ati ẹmi titun fun ara nyin: nitori kini ẹnyin o ṣe kú, ile Israeli?
Ṣàwárí Esek 18:31
4
Esek 18:23
Emi ha ni inu-didùn rara pe ki enia buburu ki o kú? ni Oluwa Ọlọrun wi: kò ṣepe ki o yipada kuro ninu ọ̀na rẹ̀, ki o si yè?
Ṣàwárí Esek 18:23
5
Esek 18:21
Ṣugbọn bi enia buburu yio ba yipada kuro ninu gbogbo ẹ̀ṣẹ rẹ̀ ti o ti da, ti o si pa gbogbo aṣẹ mi mọ, ti o si ṣe eyi ti o tọ́, ati eyiti o yẹ, yiyè ni yio yè, on kì yio kú.
Ṣàwárí Esek 18:21
6
Esek 18:9
Ti o ti rìn ninu aṣẹ mi, ti o si ti pa idajọ mi mọ, lati hùwa titọ́; on ṣe olõtọ, yiyè ni yio yè, ni Oluwa Ọlọrun wi.
Ṣàwárí Esek 18:9