Õrùn ati oṣupa yio ṣu òkunkun, ati awọn irawọ̀ yio fà titàn wọn sẹhin.
Oluwa yio si ké ramùramù lati Sioni wá, yio si fọ ohùn rẹ̀ jade lati Jerusalemu wá; awọn ọrun ati aiye yio si mì: ṣugbọn Oluwa yio ṣe ãbò awọn enia rẹ̀, ati agbara awọn ọmọ Israeli.