NJẸ Kora, ọmọ Ishari, ọmọ Kohati, ọmọ Lefi, ati Datani on Abiramu, awọn ọmọ Eliabu, ati On, ọmọ Peleti, awọn ọmọ Reubeni, dìmọ:
Nwọn si dide niwaju Mose, pẹlu ãdọtalerugba ọkunrin ninu awọn ọmọ Israeli, ijoye ninu ijọ, awọn olorukọ ninu ajọ, awọn ọkunrin olokikí