1
Owe 13:20
Bibeli Mimọ
Ẹniti o mba ọlọgbọ́n rìn yio gbọ́n; ṣugbọn ẹgbẹ awọn aṣiwere ni yio ṣegbe.
Ṣe Àfiwé
Ṣàwárí Owe 13:20
2
Owe 13:3
Ẹniti o pa ẹnu rẹ̀ mọ́, o pa ẹmi rẹ̀ mọ́; ṣugbọn ẹniti o ṣi ète rẹ̀ pupọ yio ni iparun.
Ṣàwárí Owe 13:3
3
Owe 13:24
Ẹniti o ba fà ọwọ paṣan sẹhin, o korira ọmọ rẹ̀; ṣugbọn ẹniti o fẹ ẹ a ma tète nà a.
Ṣàwárí Owe 13:24
4
Owe 13:12
Ireti pipẹ mu ọkàn ṣàisan; ṣugbọn nigbati ifẹ ba de, igi ìye ni.
Ṣàwárí Owe 13:12
5
Owe 13:6
Ododo pa aduro-ṣinṣin li ọ̀na mọ́; ṣugbọn ìwa-buburu ni imuni ṣubu sinu ẹ̀ṣẹ.
Ṣàwárí Owe 13:6
6
Owe 13:11
Ọrọ̀ ti a fi ìwa-asan ni yio fàsẹhin; ṣugbọn ẹniti o fi iṣẹ-ọwọ kojọ ni yio ma pọ̀ si i.
Ṣàwárí Owe 13:11
7
Owe 13:10
Nipa kiki igberaga ni ìja ti iwá; ṣugbọn lọdọ awọn ti a fi ìmọ hàn li ọgbọ́n wà.
Ṣàwárí Owe 13:10
8
Owe 13:22
Enia rere fi ogún silẹ fun awọn ọmọ ọmọ rẹ̀; ṣugbọn ọrọ̀ ẹlẹṣẹ̀ li a tò jọ fun olododo
Ṣàwárí Owe 13:22
9
Owe 13:1
ỌLỌGBỌ́N ọmọ gbà ẹkọ́ baba rẹ̀; ṣugbọn ẹlẹgàn kò gbọ́ ibawi.
Ṣàwárí Owe 13:1
10
Owe 13:18
Oṣi ati itiju ni fun ẹniti o kọ̀ ẹkọ́; ṣugbọn ẹniti o ba fetisi ibawi li a o bu ọlá fun.
Ṣàwárí Owe 13:18
Ilé
Bíbélì
Àwon ètò
Àwon Fídíò