1
2 Ọba 6:17
Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní
BMYO
Eliṣa sì gbàdúrà, “OLúWA, la ojú rẹ̀ kí ó ba à lè ríran.” Nígbà náà OLúWA la ojú ìránṣẹ́ náà, ó sì wò, ó sì rí òkè ńlá tí ó kún fún ẹṣin àti kẹ̀kẹ́ iná gbogbo yí Eliṣa ká.
Ṣe Àfiwé
Ṣàwárí 2 Ọba 6:17
2
2 Ọba 6:16
“Má ṣe bẹ̀rù,” wòlíì náà dáhùn, “Àwọn tí ó wà pẹ̀lú wa, wọ́n pọ̀ ju àwọn tí ó wà pẹ̀lú wọn lọ.”
Ṣàwárí 2 Ọba 6:16
3
2 Ọba 6:15
Nígbà tí ìránṣẹ́ ènìyàn Ọlọ́run dìde ó sì jáde lọ ní òwúrọ̀ kùtùkùtù ọjọ́ kejì, ogun pẹ̀lú ẹṣin àti kẹ̀kẹ́ wọn ti yí ìlú náà ká. “Yé è, olúwa mi! Kí ni kí àwa kí ó ṣe?” ìránṣẹ́ náà béèrè.
Ṣàwárí 2 Ọba 6:15
4
2 Ọba 6:18
Bí àwọn ọ̀tá ṣe ń sọ̀kalẹ̀ wá níwájú rẹ, Eliṣa gbàdúrà sí OLúWA pé. “Bu ìfọ́jú lu àwọn ènìyàn wọ̀nyí,” OLúWA sì ṣe gẹ́gẹ́ bí Eliṣa ti béèrè.
Ṣàwárí 2 Ọba 6:18
5
2 Ọba 6:6
Ènìyàn Ọlọ́run sì béèrè pé, “Níbo ni ó bọ́ sí?” Nígbà tí ó fi ibẹ̀ hàn án, Eliṣa gé igi kan ó sì jù ú síbẹ̀, ó sì mú irin náà fò lójú omi.
Ṣàwárí 2 Ọba 6:6
6
2 Ọba 6:5
Bí ọ̀kan ṣe gé igi náà, àáké irin náà bọ́ sínú omi, ó kígbe sókè pé, “O! Olúwa mi, mo yá a ni!”
Ṣàwárí 2 Ọba 6:5
7
2 Ọba 6:7
Ó wí pé, “Gbé e jáde.” Lẹ́yìn náà ọkùnrin náà na ọwọ́ rẹ̀ jáde ó sì mú un.
Ṣàwárí 2 Ọba 6:7