1
2 Ọba 7:1
Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní
BMYO
Eliṣa wí pé, “Gbọ́ ọ̀rọ̀ OLúWA. Èyí ni ohun tí OLúWA sọ, ‘Ní àsìkò yìí ní ọ̀la, a ó ta òsùwọ̀n ìyẹ̀fun barle kíkúnná kan ní ṣékélì kan àti méjì òsùwọ̀n ọkà barle fún ṣékélì kan ní ẹnu-bodè Samaria.’ ”
Ṣe Àfiwé
Ṣàwárí 2 Ọba 7:1
2
2 Ọba 7:3
Nísinsin yìí àwọn ọkùnrin mẹ́rin kan wà pẹ̀lú ẹ̀tẹ̀ ní ẹnu àbáwọlé ibodè ìlú. Wọ́n wí fún olúkúlùkù pé, “Kí ni ó dé tí àwa yóò fi jókòó síbí títí àwa yóò fi kú?
Ṣàwárí 2 Ọba 7:3
3
2 Ọba 7:2
Ìjòyè kan ẹni tí ọwọ́ ọba ń fi ara tì dáhùn wí fún ènìyàn Ọlọ́run pé, “Ẹ wò ó, tí OLúWA bá tilẹ̀ ṣí fèrèsé ọ̀run sílẹ̀, ṣé èyí lè rí bẹ́ẹ̀?” Eliṣa dáhùn pé, “Ìwọ yóò rí i pẹ̀lú ojú rẹ, ṣùgbọ́n ìwọ kò ní jẹ nǹkan kan lára rẹ̀!”
Ṣàwárí 2 Ọba 7:2