1
Oniwaasu 8:15
Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní
Nítorí náà mo kan sáárá sí ìgbádùn ayé, nítorí pé kò sí ohun tí ó dára fún ènìyàn ní abẹ́ oòrùn ju pé kí ó jẹ, kí ó mu, kí inú rẹ̀ sì dùn lọ. Nígbà náà ni ìdùnnú yóò bá a rìn nínú iṣẹ́ ẹ rẹ̀, ní gbogbo ọjọ́ ayé ti Ọlọ́run tí fi fún un lábẹ́ oòrùn.
Ṣe Àfiwé
Ṣàwárí Oniwaasu 8:15
2
Oniwaasu 8:12
Bí ènìyàn búburú tó dẹ́ṣẹ̀ nígbà ọgọ́rùn-ún tilẹ̀ wà láààyè fún ìgbà pípẹ́, mo mọ̀ wí pé yóò dára fún ẹni tí ó bẹ̀rù Ọlọ́run, tí ó bẹ̀rù níwájú rẹ̀.
Ṣàwárí Oniwaasu 8:12
3
Oniwaasu 8:6
Ohun gbogbo ni ó ní àsìkò àti ọ̀nà tí ó tọ́ láti ṣe, ṣùgbọ́n, òsì ènìyàn pọ̀ sí orí ara rẹ̀.
Ṣàwárí Oniwaasu 8:6
4
Oniwaasu 8:8
Kò sí ẹni tí ó lágbára lórí afẹ́fẹ́ láti gbà á dúró nítorí náà, kò sí ẹni tí ó ní agbára lórí ọjọ́ ikú rẹ̀. Bí ó ti jẹ́ wí pé kò sí ẹni tí a dá sílẹ̀ nígbà ogun, bẹ́ẹ̀ náà ni ìkà kò ní fi àwọn tí ó ń ṣe é sílẹ̀; bí ó ti jẹ́ wí pé kò sí ẹni tí a dá sílẹ̀ nígbà ogun, bẹ́ẹ̀ náà ni ìwà búburú kò le gba àwọn tí ó ń ṣe é sílẹ̀.
Ṣàwárí Oniwaasu 8:8
5
Oniwaasu 8:11
Nígbà tí a kò bá tètè ṣe ìdájọ́ fún ẹlẹ́ṣẹ̀ kíákíá, ọkàn àwọn ènìyàn a máa kún fún ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìmọ̀ láti ṣe ibi.
Ṣàwárí Oniwaasu 8:11
6
Oniwaasu 8:14
Ohun mìíràn tún wà tí kò ní ìtumọ̀, tí ó ń ṣẹlẹ̀ láyé olódodo tí ó ń gba ohun tí ó tọ́ sí òṣìkà àti ènìyàn búburú tí ó ń gba ohun tí ó tọ́ sí olódodo. Mo sọ wí pé eléyìí gan an kò ní ìtumọ̀.
Ṣàwárí Oniwaasu 8:14
7
Oniwaasu 8:7
Níwọ́n ìgbà tí kò sí ẹni tí ó mọ ọjọ́-ọ̀lá, ta ni ó le è sọ fún un ohun tí ó ń bọ̀?
Ṣàwárí Oniwaasu 8:7
Ilé
Bíbélì
Àwon ètò
Àwon Fídíò