Nígbà náà ni OLúWA dáhùn pé:
“Kọ ìṣípayá náà sílẹ̀
kí o sì fi hàn ketekete lórí wàláà
kí ẹni tí ń kà á, lè máa sáré.
Nítorí ìṣípayá náà jẹ́ tí ìgbà kan tí a múra sílẹ̀ dè;
yóò máa yára sí ìgbẹ̀yìn
kí yóò sìsọ èké.
Bí o tilẹ̀ lọ́ra, dúró dè é;
nítorí, dájúdájú, yóò dé, kí yóò sí pẹ́.”