SAMUẸLI KINNI 27

27
Dafidi láàrin Àwọn Ará Filistia
1Dafidi rò ní ọkàn rẹ̀ pé Saulu yóo pa òun ní ọjọ́ kan, nítorí náà ohun tí ó dára jù ni kí òun sá àsálà lọ sí ilẹ̀ àwọn ará Filistia. Ó ní Saulu yóo dẹ́kun láti máa wá òun kiri ní ilẹ̀ Israẹli, òun óo sì fi bẹ́ẹ̀ bọ́ lọ́wọ́ rẹ̀. 2Dafidi ati àwọn ọmọ ogun rẹ̀ tí wọ́n jẹ́ ẹgbẹta (600), bá lọ sọ́dọ̀ Akiṣi, ọmọ Maoki, ọba Gati. 3Wọ́n ń gbé Gati pẹlu àwọn ará ilé wọn. Àwọn aya Dafidi mejeeji, Ahinoamu ará Jesireeli ati Abigaili ará Kamẹli, opó Nabali, sì wà pẹlu rẹ̀ níbẹ̀. 4Nígbà tí Saulu gbọ́ pé Dafidi ti sá àsálà lọ sí Gati, ó dẹ́kun láti máa wá a kiri.
5Dafidi sì sọ fún Akiṣi pé, “Bí mo bá rí ojurere rẹ, jọ̀wọ́ fún mi ní ààyè ní ọ̀kan ninu àwọn ìletò agbègbè yìí kí n máa gbé. Kí ló dé tí èmi iranṣẹ rẹ yóo máa gbé inú ìlú kan náà pẹlu rẹ?” 6Akiṣi fún un ní ìlú Sikilagi, nítorí náà ni Sikilagi fi jẹ́ ti àwọn ọba Juda títí di òní yìí. 7Dafidi gbé ní ilẹ̀ àwọn ará Filistia fún ọdún kan ati oṣù mẹrin.
8Ní àkókò náà, Dafidi ati àwọn ọmọ ogun rẹ̀ gbógun ti àwọn ará Geṣuri, ati àwọn ará Girisi ati àwọn Amaleki, tí wọ́n ti ń gbé ibẹ̀ fún ìgbà pípẹ́, títí dé Ṣuri ati ilẹ̀ Ijipti. 9Dafidi pa gbogbo wọn, lọkunrin ati lobinrin, ó sì kó àwọn aguntan, mààlúù, kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ ati ràkúnmí wọn, ati aṣọ wọn, ó sì pada lọ bá Akiṣi. 10Bí Akiṣi bá bèèrè pé, “Àwọn wo ni ẹ kógun lọ bá lónìí?” Dafidi á sì dáhùn pé, “Ìhà gúsù Juda ni, tabi kí ó sọ wí pé ìhà gúsù Jerameeli tabi ìhà gúsù Keni.” 11Dafidi kò dá ẹnìkankan sí yálà ọkunrin tabi obinrin kí wọ́n má baà mú ìròyìn ohun tí ó ṣẹlẹ̀ lọ sí Gati, bẹ́ẹ̀ ni Dafidi ń ṣe ní gbogbo ìgbà tí ó ń gbé ààrin àwọn ará Filistia. 12Ṣugbọn Akiṣi gba Dafidi gbọ́, ó sì wí ninu ara rẹ̀ pé, “Àwọn ọmọ Israẹli, eniyan rẹ̀, kórìíra rẹ̀ lọpọlọpọ, nítorí náà yóo jẹ́ iranṣẹ mi laelae.”

Àwon tá yàn lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí:

SAMUẸLI KINNI 27: YCE

Ìsàmì-sí

Pín

Daako

None

Ṣé o fẹ́ fi àwọn ohun pàtàkì pamọ́ sórí gbogbo àwọn ẹ̀rọ rẹ? Wọlé pẹ̀lú àkántì tuntun tàbí wọlé pẹ̀lú àkántì tí tẹ́lẹ̀