SAMUẸLI KINNI 28

28
1Nígbà tí ó ṣe, àwọn ará Filistia kó ara wọn jọ láti bá Israẹli jagun. Akiṣi sọ fún Dafidi pé, “Ìwọ ati àwọn ọkunrin tí wọ́n wà pẹlu rẹ yóo jà fún mi.”
2Dafidi dáhùn pé, “Ó dára, o óo sì rí ohun tí èmi iranṣẹ rẹ lè ṣe.”
Akiṣi bá ní, òun óo fi Dafidi ṣe olùṣọ́ òun títí lae.
Saulu Lọ Ṣe Àyẹ̀wò lọ́dọ̀ Abókùúsọ̀rọ̀
3Samuẹli ti kú, àwọn Israẹli ti ṣọ̀fọ̀ rẹ̀, wọ́n sì ti sin ín sí Rama ìlú rẹ̀. Saulu ti lé gbogbo àwọn abókùúsọ̀rọ̀ ati àwọn oṣó kúrò ní ilẹ̀ Israẹli.#1 Sam 25:1 #Lef 20:27; Diut 18:10-11
4Àwọn ará Filistia sì kó ara wọn jọ, wọ́n pa ibùdó sí Ṣunemu. Saulu náà kó àwọn ọmọ ogun rẹ̀ jọ, wọ́n pa ibùdó sí Giliboa. 5Nígbà tí Saulu rí àwọn ọmọ ogun Filistini, àyà rẹ̀ já, ẹ̀rù sì bà á lọpọlọpọ. 6Nígbà tí Saulu bèèrè lọ́wọ́ OLUWA ohun tí yóo ṣe, OLUWA kò dá a lóhùn yálà nípa àlá tabi nípa Urimu tabi nípasẹ̀ àwọn wolii.#Nọm 27:21 7Saulu bá sọ fún àwọn iranṣẹ rẹ̀ pé, “Ẹ bá mi wá obinrin kan tí ó bá jẹ́ abókùúsọ̀rọ̀, kí n lè lọ ṣe àyẹ̀wò lọ́dọ̀ rẹ̀.”
Wọn sì sọ fún un pé, “Obinrin kan wà ní Endori tí ó jẹ́ abókùúsọ̀rọ̀.”
8Saulu pa ara dà, ó wọ aṣọ mìíràn, òun pẹlu àwọn ọkunrin meji kan lọ sọ́dọ̀ obinrin náà ní òru, Saulu sì sọ fún obinrin náà pé, “Lo ẹ̀mí abókùúsọ̀rọ̀ rẹ láti pe ẹni tí mo bá sọ fún ọ wá.”
9Obinrin náà dáhùn pé, “Kí ló dé tí o fi ń dẹ tàkúté fún mi láti pa mí? O ṣá mọ ohun tí Saulu ọba ṣe, tí ó lé gbogbo àwọn abókùúsọ̀rọ̀ ati àwọn oṣó kúrò ní Israẹli.”
10Saulu bá búra ní orúkọ OLUWA pé, “Bí OLUWA ti ń bẹ, ibi kan kò ní ṣẹlẹ̀ sí ọ nítorí èyí.”
11Obinrin náà dáhùn pé, “Ta ni kí n pè fún ọ?”#Sir 46:20
Saulu dáhùn pe, “Pe Samuẹli fún mi.”
12Nígbà tí obinrin náà rí Samuẹli, ó kígbe lóhùn rara pé, “Kí ló dé tí o fi tàn mí? Àṣé Saulu ọba ni ọ́.”
13Saulu bá sọ fún un pé, “Má bẹ̀rù, sọ ohun tí o rí fún mi.”
Obinrin náà dáhùn pé, “Mo rí ẹbọra kan, tí ń jáde bọ̀ láti inú ilẹ̀.”
14Saulu bèèrè pé, “Báwo ló rí?”
Obinrin náà dáhùn pé, “Ọkunrin arúgbó kan ló ń bọ̀, ó sì fi aṣọ bora.”
Saulu mọ̀ pé Samuẹli ni, ó sì tẹríba.
15Samuẹli bi Saulu pé, “Kí ló dé tí o fi ń yọ mí lẹ́nu? Kí ló dé tí o fi gbé mi dìde?”
Saulu dáhùn pé, “Mo wà ninu ìpọ́njú ńlá nítorí pé àwọn ará Filistia ń bá mi jagun, Ọlọrun sì ti kọ̀ mí sílẹ̀, nítorí pé kò fún mi ní ìtọ́sọ́nà, yálà láti ẹnu wolii kan ni, tabi lójú àlá. Nítorí náà ni mo ṣe pè ọ́, pé kí o lè sọ ohun tí n óo ṣe fún mi.”
16Samuẹli dáhùn pé, “Kí ló dé tí o fi ń bi mí, nígbà tí OLUWA ti kọ̀ ọ́ sílẹ̀, tí ó sì ti di ọ̀tá rẹ? 17OLUWA ti ṣe sí ọ gẹ́gẹ́ bí ọ̀rọ̀ tí ó sọ láti ẹnu mi. Ó ti gba ìjọba náà kúrò lọ́wọ́ rẹ, ó sì ti fún Dafidi, aládùúgbò rẹ.#1 Sam 15:28 18O ṣàìgbọràn sí àṣẹ OLUWA, nítorí pé, o kò pa gbogbo àwọn ará Amaleki ati àwọn nǹkan ìní wọn run. Ìdí nìyí tí OLUWA fi ṣe àwọn nǹkan wọnyi sí ọ lónìí. 19OLUWA yóo fa ìwọ ati Israẹli lé àwọn ará Filistia lọ́wọ́. Ní ọ̀la ni ìwọ ati àwọn ọmọ rẹ yóo kú; OLUWA yóo sì fa àwọn ọmọ ogun Israẹli lé àwọn ará Filistia lọ́wọ́.”
20Lẹ́sẹ̀kan náà, Saulu ṣubú lulẹ̀ gbalaja, nítorí pé ohun ti Samuẹli sọ dẹ́rùbà á gidigidi, àárẹ̀ sì mú un nítorí pé, kò jẹun ní gbogbo ọ̀sán ati òru náà. 21Nígbà tí obinrin náà rí i pé ó wà ninu ọpọlọpọ ìbànújẹ́, ó sọ fún un pé, “Oluwa mi, mo fi ẹ̀mí mi wéwu láti ṣe ohun tí o bèèrè. 22Ǹjẹ́, nisinsinyii, jọ̀wọ́ ṣe ohun tí mò ń tọrọ lọ́wọ́ rẹ fún mi. Jẹ́ kí n tọ́jú oúnjẹ fún ọ, kí o jẹ ẹ́, kí o lè lókun nígbà tí o bá ń lọ.”
23Saulu kọ̀, kò fẹ́ jẹun. Ṣugbon àwọn iranṣẹ rẹ̀ ati obinrin náà bẹ̀ ẹ́ kí ó jẹun. Ó gbà, ó dìde nílẹ̀, ó sì jókòó lórí ibùsùn. 24Obinrin náà yára pa ẹgbọ̀rọ̀ mààlúù tí ó ń sìn, ó sì ṣe burẹdi díẹ̀ láì fi ìwúkàrà sí i. 25Ó gbé e kalẹ̀ níwájú wọn; Saulu ati àwọn iranṣẹ rẹ̀ jẹ ẹ́, wọ́n sì jáde lọ ní òru náà.

Àwon tá yàn lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí:

SAMUẸLI KINNI 28: YCE

Ìsàmì-sí

Pín

Daako

None

Ṣé o fẹ́ fi àwọn ohun pàtàkì pamọ́ sórí gbogbo àwọn ẹ̀rọ rẹ? Wọlé pẹ̀lú àkántì tuntun tàbí wọlé pẹ̀lú àkántì tí tẹ́lẹ̀