JOHANU KEJI 1
1
Ìkíni
1Èmi Alàgbà ni mo kọ ìwé yìí sí àyànfẹ́ arabinrin ati àwọn ọmọ rẹ̀, àwọn tí mo fẹ́ràn nítòótọ́. Kì í ṣe èmi nìkan ni mo fẹ́ràn rẹ̀, ati gbogbo àwọn tí wọ́n mọ òtítọ́ ni; 2nítorí òtítọ́ tí ó ń gbé inú wa, tí ó sì wà pẹlu wa yóo wà títí lae.
3Oore-ọ̀fẹ́, àánú ati alaafia láti ọ̀dọ̀ Ọlọrun Baba ati láti ọ̀dọ̀ Jesu Kristi Ọmọ Baba yóo wà pẹlu wa ninu òtítọ́ ati ìfẹ́.
Ẹ Máa Gbé Inú Ẹ̀kọ́ Kristi
4Mo láyọ̀ pupọ nítorí mo ti rí àwọn tí wọn ń gbé ìgbé-ayé òtítọ́ ninu àwọn ọmọ rẹ, gẹ́gẹ́ bí a ti gba òfin lọ́dọ̀ Baba. 5Nisinsinyii mo bẹ̀ ọ́, arabinrin, kì í ṣe pé mò ń kọ òfin titun sí ọ, yàtọ̀ sí èyí tí a ti níláti ìbẹ̀rẹ̀, pé kí á fẹ́ràn ọmọnikeji wa.#Joh 13:34; 15:12,17 6Èyí ni ìfẹ́, pé kí á máa gbé ìgbé-ayé gẹ́gẹ́ bí àwọn òfin Ọlọrun. Bí ẹ ti gbọ́ láti ìbẹ̀rẹ̀, òfin yìí ni pé kí ẹ máa rìn ninu ìfẹ́.
7Ọpọlọpọ àwọn ẹlẹ́tàn ti dé inú ayé, àwọn tí kò jẹ́wọ́ pé Jesu Kristi wá ninu ara eniyan. Àwọn yìí ni ẹlẹ́tàn ati alátakò Kristi. 8Ẹ ṣọ́ra kí ẹ má baà pa iṣẹ́ tí ẹ ti ṣe run, kí ẹ lè gba èrè kíkún.
9Ẹnikẹ́ni tí kò bá máa gbé inú ẹ̀kọ́ Kristi, ṣugbọn tí ó bá tayọ rẹ̀, kò mọ Ọlọrun. Ẹni tí ó bá ń gbé inú ẹ̀kọ́ Kristi mọ Baba ati Ọmọ. 10Bí ẹnikẹ́ni bá wá sọ́dọ̀ yín tí kò mú ẹ̀kọ́ yìí wá, ẹ má gbà á sílé. Ẹ má tilẹ̀ kí i, “Kú ààbọ̀.” 11Ẹni tí ó bá kí i di alábàápín ninu àwọn iṣẹ́ burúkú rẹ̀.
Ìdágbére
12Àwọn nǹkan tí mo fẹ́ ba yín sọ pọ̀, ṣugbọn n kò fẹ́ kọ ọ́ sinu ìwé. Mo ní ìrètí ati wá sọ́dọ̀ yín, kí á baà lè jọ sọ̀rọ̀ lojukooju, kí ayọ̀ wa lè di kíkún.
13Àwọn ọmọ àyànfẹ́ arabinrin rẹ kí ọ.
Àwon tá yàn lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí:
JOHANU KEJI 1: YCE
Ìsàmì-sí
Pín
Daako
Ṣé o fẹ́ fi àwọn ohun pàtàkì pamọ́ sórí gbogbo àwọn ẹ̀rọ rẹ? Wọlé pẹ̀lú àkántì tuntun tàbí wọlé pẹ̀lú àkántì tí tẹ́lẹ̀
Bible Society of Nigeria © 1900/2010