JOHANU KẸTA Ọ̀rọ̀ Iṣaaju
Ọ̀rọ̀ Iṣaaju
Ọkunrin kan tí ń jẹ́ Gaiyu, tí ó jẹ́ adarí ìjọ, ni “Alàgbà” kan kọ Ìwé Kẹta Johanu sí. Ẹni tí ó kọ ìwé yìí yin Gaiyu nítorí ìrànlọ́wọ́ tí ó ṣe fún àwọn onigbagbọ mìíràn. Ó sì kìlọ̀ fún un nípa ọkunrin kan tí ń jẹ́ Diotirefe.
Àwọn Ohun tí ó wà ninu Ìwé yìí ní Ìsọ̀rí-ìsọ̀rí
Ọ̀rọ̀ iṣaaju 1-4
Yíyin Gaiyu 5-8
Bíbu ẹnu àtẹ́ lu Diotirefe 9-10
Ọ̀rọ̀ dáradára nípa Demeteriu 11-12
Ọ̀rọ̀ ìparí 13-15
Àwon tá yàn lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí:
JOHANU KẸTA Ọ̀rọ̀ Iṣaaju: YCE
Ìsàmì-sí
Pín
Daako
Ṣé o fẹ́ fi àwọn ohun pàtàkì pamọ́ sórí gbogbo àwọn ẹ̀rọ rẹ? Wọlé pẹ̀lú àkántì tuntun tàbí wọlé pẹ̀lú àkántì tí tẹ́lẹ̀
Bible Society of Nigeria © 1900/2010