ÌṢE ÀWỌN APOSTELI 16:25-26

ÌṢE ÀWỌN APOSTELI 16:25-26 YCE

Nígbà tí ó di ọ̀gànjọ́, Paulu ati Sila ń gbadura, wọ́n ń kọrin sí Ọlọrun. Àwọn ẹlẹ́wọ̀n yòókù ń dẹtí sí wọn. Lójijì ni ilẹ̀ mì tìtì, tóbẹ́ẹ̀ tí ìpìlẹ̀ ilé ẹ̀wọ̀n mì. Lọ́gán gbogbo ìlẹ̀kùn ṣí; gbogbo ẹ̀wọ̀n tí a fi de àwọn ẹlẹ́wọ̀n sì tú.