ÌṢE ÀWỌN APOSTELI 16

16
Timoti ba Paulu ati Sila lọ
1Paulu dé Dabe ati Listira. Onigbagbọ kan tí ń jẹ́ Timoti wà níbẹ̀. Ìyá rẹ̀ jẹ́ Juu tí ó gba Jesu gbọ́; ṣugbọn Giriki ni baba rẹ̀. 2Àwọn arakunrin ní Listira ati Ikoniomu ròyìn Timoti yìí dáradára. 3Òun ni ó wu Paulu láti mú lọ sí ìrìn-àjò rẹ̀, nítorí náà, ó mú un, ó kọ ọ́ nílà nítorí àwọn Juu tí ó wà ní agbègbè ibẹ̀; nítorí gbogbo wọn ni wọ́n mọ̀ pé Giriki ni baba rẹ̀. 4Bí wọ́n ti ń lọ láti ìlú dé ìlú, wọ́n ń sọ fún wọn nípa ìpinnu tí àwọn aposteli ati àwọn àgbààgbà ní Jerusalẹmu ṣe, wọ́n sì ń gbà wọ́n níyànjú pé kí wọ́n pa wọ́n mọ́. 5Bẹ́ẹ̀ ni àwọn ìjọ túbọ̀ ń lágbára sí i ninu igbagbọ, tí wọ́n sì ń pọ̀ sí i ní iye lojoojumọ.
Paulu Rí Ará Masedonia Kan ní Ojú Ìran
6Wọ́n gba ilẹ̀ Firigia ati Galatia kọjá. Ẹ̀mí Mímọ́ kò gbà wọ́n láàyè láti lọ waasu ọ̀rọ̀ Oluwa ní Esia. 7Nígbà tí wọ́n súnmọ́ Misia, wọ́n gbìyànjú láti lọ sí Bitinia. Ṣugbọn Ẹ̀mí Jesu kò gbà fún wọn. 8Nígbà tí wọ́n ti la Misia kọjá, wọ́n dé Tiroasi. 9Nígbà tí ó di alẹ́, Paulu rí ìran kan. Ó rí ọkunrin kan ará Masedonia tí ó dúró, tí ó ń bẹ̀ ẹ́ pé, “Sọdá sí Masedonia níbí kí o wá ràn wá lọ́wọ́.” 10Gbàrà tí ó rí ìran náà, a wá ọ̀nà láti lọ sí Masedonia; a pinnu pé Ọlọrun ni ó pè wá láti lọ waasu fún wọn níbẹ̀.
Lidia di Onigbagbọ
11Nígbà tí a wọ ọkọ̀ láti Tiroasi, a lọ tààrà sí Samotirake. Ní ọjọ́ keji a gúnlẹ̀ ní Neapoli. 12Láti ibẹ̀, a lọ sí Filipi tíí ṣe olú-ìlú ilẹ̀ Masedonia. Àwọn ará Romu ni wọ́n tẹ ìlú yìí dó. A bá wà níbẹ̀ fún ọjọ́ mélòó kan. 13Ní Ọjọ́ Ìsinmi a jáde lọ sẹ́yìn odi ìlú lẹ́bàá odò, níbi tí a rò pé a óo ti rí ibi tí wọn máa ń gbadura. A bá jókòó, a bá àwọn obinrin tí ó péjọ níbẹ̀ sọ̀rọ̀. 14Obinrin kan wà níbẹ̀ tí ó ń jẹ́ Lidia, ará Tiatira, tí ó ń ta aṣọ àlàárì. Ó jẹ́ ẹnìkan tí ó ń sin Ọlọrun. Ó fetí sílẹ̀, Ọlọrun ṣí i lọ́kàn láti gba ohun tí Paulu ń sọ. 15Òun ati àwọn ará ilé rẹ̀ gba ìrìbọmi. Lẹ́yìn náà, ó bẹ̀ wá pé, bí a bá gbà pé òun jẹ́ onigbagbọ nítòótọ́, kí á máa bọ̀ ní ilé òun kí á máa bá àwọn gbé. Ó tẹnu mọ́ ọn títí a fi gbà.
Wọ́n Ju Paulu ati Sila sẹ́wọ̀n ní Filipi
16Ní ọjọ́ kan, bí a ti ń lọ sí ibi adura, a pàdé ọdọmọbinrin kan tí ó ní ẹ̀mí àfọ̀ṣẹ. Ó ti ń mú èrè pupọ wá fún àwọn olówó rẹ̀ nípa àfọ̀ṣẹ rẹ̀. 17Ó ń tẹ̀lé Paulu ati àwa náà, ó ń kígbe pé, “Àwọn ọkunrin yìí ni iranṣẹ Ọlọrun Ọ̀gá Ògo; àwọn ni wọ́n ń waasu ọ̀nà ìgbàlà fun yín.”#16:17 Àwọn Bibeli àtijọ́ mìíràn sọ pé fún wa. 18Ó ń ṣe báyìí fún ọjọ́ pupọ. Nígbà tí ara Paulu kò gbà á mọ́, ó yipada, ó sọ fún ẹ̀mí náà pé, “Mo pàṣẹ fún ọ ní orúkọ Jesu, jáde kúrò ninu rẹ̀.” Ni ó bá jáde lẹ́sẹ̀ kan náà. 19Nígbà tí àwọn olówó ọdọmọbinrin náà rí i pé ọ̀nà oúnjẹ wọ́n ti dí, wọ́n ki Paulu ati Sila mọ́lẹ̀, wọ́n fà wọ́n lọ sọ́dọ̀ àwọn aláṣẹ ní ọjà. 20Wọ́n mú wọn wá siwaju àwọn adájọ́. Wọ́n ní, “Juu ni àwọn ọkunrin wọnyi, wọ́n sì ń da ìlú wa rú. 21Wọ́n ń kọ́ àwọn eniyan ní àṣà tí kò tọ́ fún wa láti gbà tabi láti ṣe nítorí ará Romu ni wá.” 22Ni àwọn eniyan bá bẹ̀rẹ̀ sí lu Paulu ati Sila.
Àwọn adájọ́ fa aṣọ ya mọ́ wọn lára, wọ́n pàṣẹ pé kí wọ́n nà wọ́n. 23Nígbà tí wọ́n ti nà wọ́n dáradára, wọ́n bá sọ wọ́n sẹ́wọ̀n. Wọ́n pàṣẹ fún ẹni tí ó ń ṣọ́ àwọn ẹlẹ́wọ̀n pé kí ó ṣọ́ wọn dáradára. 24Nígbà tí ó ti gba irú àṣẹ báyìí, ó sọ wọ́n sinu àtìmọ́lé ti inú patapata, ó tún fi ààbà kan ẹsẹ̀ wọn mọ́ igi.
25Nígbà tí ó di ọ̀gànjọ́, Paulu ati Sila ń gbadura, wọ́n ń kọrin sí Ọlọrun. Àwọn ẹlẹ́wọ̀n yòókù ń dẹtí sí wọn. 26Lójijì ni ilẹ̀ mì tìtì, tóbẹ́ẹ̀ tí ìpìlẹ̀ ilé ẹ̀wọ̀n mì. Lọ́gán gbogbo ìlẹ̀kùn ṣí; gbogbo ẹ̀wọ̀n tí a fi de àwọn ẹlẹ́wọ̀n sì tú. 27Nígbà tí ẹni tí ó ń ṣọ́ ilé ẹ̀wọ̀n jí lójú oorun, tí ó rí i pé ìlẹ̀kùn ilé ẹ̀wọ̀n ti ṣí, ó fa idà rẹ̀ yọ, ó fẹ́ pa ara rẹ̀, ó ṣebí àwọn ẹlẹ́wọ̀n ti sálọ ni. 28Paulu bá kígbe pè é, ó ní, “Má ṣe ara rẹ léṣe, nítorí gbogbo wa wà níhìn-ín.”
29Ẹni tí ń ṣọ́ ilé ẹ̀wọ̀n náà bá bèèrè iná, ó pa kuuru wọ inú iyàrá, ó ń gbọ̀n láti orí dé ẹsẹ̀. Ó wólẹ̀ níwájú Paulu ati Sila. 30Ó mú wọn jáde, ó ní, “Ẹ̀yin alàgbà, kí ni ó yẹ kí n ṣe kí n lè là?”
31Wọ́n dá a lóhùn pé, “Gba Jesu Oluwa gbọ́, ìwọ ati ìdílé rẹ yóo sì là.” 32Wọ́n bá sọ ọ̀rọ̀ Oluwa fún òun ati gbogbo ìdílé rẹ̀. 33Ní òru náà, ó mú wọn, ó wẹ ọgbẹ́ wọn. Lójú kan náà òun ati gbogbo ìdílé rẹ̀ sì ṣe ìrìbọmi. 34Ó bá mú wọn wọ ilé, ó fún wọn ní oúnjẹ. Inú òun ati gbogbo ìdílé rẹ̀ dùn pupọ nítorí ó ti gba Ọlọrun gbọ́.
35Nígbà tí ilẹ̀ mọ́, àwọn adájọ́ rán àwọn iranṣẹ sí ẹni tí ń ṣọ́ ilé ẹ̀wọ̀n pé, kí ó dá àwọn eniyan náà sílẹ̀.
36Ẹni tí ó ń ṣọ́ ilé ẹ̀wọ̀n náà bá lọ jíṣẹ́ fún Paulu pé, “Àwọn adájọ́ ti ranṣẹ pé kí á da yín sílẹ̀. Ẹ jáde kí ẹ máa lọ ní alaafia.”
37Ṣugbọn Paulu sọ fún wọn pé, “Wọ́n nà wá ní gbangba láì ká ẹ̀bi mọ́ wa lọ́wọ́, bẹ́ẹ̀ ọmọ-ìbílẹ̀ Romu ni wá. Wọ́n sọ wá sẹ́wọ̀n, wọ́n wá fẹ́ tì wá jáde níkọ̀kọ̀. Rárá o! Kí àwọn fúnra wọn wá kó wa jáde.”
38Àwọn iranṣẹ tí àwọn adájọ́ rán wá lọ ròyìn ọ̀rọ̀ wọnyi fún wọn. Ẹ̀rù bà wọ́n nígbà tí wọ́n gbọ́ pé ọmọ-ìbílẹ̀ Romu ni wọ́n jẹ́. 39Wọ́n bá wá, wọ́n bẹ̀ wọ́n. Wọ́n sìn wọ́n jáde, wọ́n bá rọ̀ wọ́n pé kí wọ́n kúrò ninu ìlú. 40Nígbà tí wọ́n jáde kúrò lẹ́wọ̀n, wọ́n lọ sí ilé Lidia. Lẹ́yìn tí wọ́n rí àwọn onigbagbọ, tí wọ́n sì gbà wọ́n níyànjú, wọ́n kúrò níbẹ̀.

Àwon tá yàn lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí:

ÌṢE ÀWỌN APOSTELI 16: YCE

Ìsàmì-sí

Pín

Daako

None

Ṣé o fẹ́ fi àwọn ohun pàtàkì pamọ́ sórí gbogbo àwọn ẹ̀rọ rẹ? Wọlé pẹ̀lú àkántì tuntun tàbí wọlé pẹ̀lú àkántì tí tẹ́lẹ̀