ÌṢE ÀWỌN APOSTELI 17
17
Ìdàrúdàpọ̀ ní Tẹsalonika
1Wọ́n kọjá ní Amfipoli ati Apolonia kí wọn tó dé Tẹsalonika. Ilé ìpàdé àwọn Juu kan wà níbẹ̀. 2Gẹ́gẹ́ bí àṣà Paulu, ó wọ ibẹ̀ tọ̀ wọ́n lọ. Fún ọ̀sẹ̀ mẹta ni ó fi ń bá wọn fi ọ̀rọ̀ wé ọ̀rọ̀ láti inú Ìwé Mímọ́. 3Ó ń ṣe àlàyé fún wọn, ó tún ń tọ́ka sí àkọsílẹ̀ inú Ìwé Mímọ́ láti fihàn pé dandan ni kí Mesaya jìyà, kí ó jinde kúrò ninu òkú. Lẹ́yìn náà ó sọ fún wọn pé, Mesaya yìí náà ni Jesu tí òun ń sọ̀rọ̀ rẹ̀ fún wọn. 4Àwọn kan ninu wọn gbàgbọ́, wọ́n fara mọ́ Paulu ati Sila. Ọ̀pọ̀ ninu wọn jẹ́ Giriki, wọ́n ń sin Ọlọrun; pupọ ninu àwọn obinrin sì jẹ́ eniyan pataki-pataki.
5Ṣugbọn ara ta àwọn Juu nígbà tí wọ́n rí i pé àwọn eniyan pupọ gba ọ̀rọ̀ Paulu ati Sila. Wọ́n bá lọ mú ninu àwọn tí wọ́n ń fẹsẹ̀ wọ́lẹ̀ kiri, àwọn jàgídíjàgan, wọ́n kó wọn jọ. Wọ́n bá dá ìrúkèrúdò sílẹ̀ ninu ìlú. Wọ́n lọ ṣùrù bo ilé Jasoni, wọ́n ń wá Paulu ati Sila kí wọ́n lè fà wọ́n lọ siwaju àwọn ará ìlú. 6Nígbà tí wọn kò rí wọn, wọ́n fa Jasoni ati díẹ̀ ninu àwọn onigbagbọ lọ siwaju àwọn aláṣẹ ìlú. Wọ́n ń kígbe pé, “Àwọn tí wọn ń da gbogbo ayé rú nìyí; wọ́n ti dé ìhín náà. 7Jasoni sì ti gbà wọ́n sílé. Gbogbo wọn ń ṣe ohun tí ó lòdì sí àṣẹ Kesari. Wọ́n ní: ọba mìíràn wà, ìyẹn ni Jesu!” 8Ọkàn àwọn eniyan ati àwọn aláṣẹ ìlú dààmú nígbà tí wọ́n gbọ́ báyìí. 9Wọ́n bá gba owó ìdúró lọ́wọ́ Jasoni ati àwọn yòókù, wọ́n bá dá wọn sílẹ̀.
Paulu ati Sila lọ sí Beria
10Nígbà tí ilẹ̀ ṣú, àwọn onigbagbọ tètè ṣe ètò láti mú Paulu ati Sila lọ sí Beria. Nígbà tí wọ́n dé ibẹ̀, wọ́n lọ sí ilé ìpàdé àwọn Juu. 11Àwọn yìí ṣe onínú rere ju àwọn Juu ti Tẹsalonika lọ. Wọ́n fi ìtara gbọ́ ọ̀rọ̀ náà. Lojoojumọ ni wọ́n ń wá inú Ìwé Mímọ́ wò láti rí bí àwọn ohun tí wọ́n kọ́ wọn rí bẹ́ẹ̀. 12Pupọ ninu wọn gbàgbọ́, ati pupọ ninu àwọn Giriki tí wọ́n jẹ́ eniyan pataki-pataki, lọkunrin ati lobinrin. 13Ṣugbọn nígbà tí àwọn Juu ní Tẹsalonika mọ̀ pé Paulu ti tún waasu ọ̀rọ̀ Ọlọrun ní Beria, wọ́n wá sibẹ láti ṣe màdàrú ati láti dá rúkèrúdò sílẹ̀. 14Lẹsẹkẹsẹ ni àwọn onigbagbọ bá ṣe ètò fún Paulu láti lọ sí èbúté. Ṣugbọn Sila ati Timoti dúró ní Beria. 15Àwọn tí ó sin Paulu lọ mú un dé Atẹni. Wọ́n wá gba ìwé pada fún Sila ati Timoti pé kí wọ́n tètè wá bá a.
Paulu ní Atẹni
16Nígbà tí Paulu ń dúró dè wọ́n ní Atẹni, ó rí ìlú náà bí ó ti kún fún ère oriṣa. Eléyìí sì dùn ún dọ́kàn. 17Nítorí náà, ó ń bá àwọn Juu ati àwọn olùfọkànsìn tí kì í ṣe Juu jiyàn ninu ilé ìpàdé ní ojoojumọ. Bẹ́ẹ̀ náà ni ó ń ṣe láàrin ọjà, ó ń bá ẹnikẹ́ni tí ó bá wà nítòsí sọ̀rọ̀. 18Àwọn ọ̀jọ̀gbọ́n kan ninu àwọn ọmọlẹ́yìn Epikurusi ati àwọn Sitoiki bẹ̀rẹ̀ sí bá a jiyàn. Àwọn kan ń sọ pé, “Kí ni aláhesọ yìí ń wí?”
Àwọn mìíràn ní, “Ó jọ pé òjíṣẹ́ oriṣa àjèjì kan ni!” Nítorí ó ń waasu nípa Jesu ati ajinde. 19Ni wọ́n bá ní kí ó kálọ sí Òkè Areopagu. Wọ́n wá bi í pé, “Ǹjẹ́ a lè mọ ohun tí ẹ̀kọ́ titun tí ò ń sọ̀rọ̀ rẹ̀ yìí jẹ́? 20Nítorí ohun tí ò ń sọ ṣe àjèjì létí wa. A sì fẹ́ mọ ìtumọ̀ rẹ̀.” 21(Gbogbo àwọn ará Atẹni ní tiwọn, ati àwọn àlejò tí ó ń gbé ibẹ̀, kí wọn ṣá máa ròyìn nǹkan titun tó bá ṣẹ̀ṣẹ̀ wọ̀lú ni iṣẹ́ tiwọn. Bí wọn bá ti gbọ́ èyí, ohun tí ó ń ṣe wọ́n tán.)
22Paulu bá dìde dúró láàrin ìgbìmọ̀ tí ó wà ní Òkè Areopagu, ó ní, “Ẹ̀yin ará Atẹni, ó hàn lọ́tùn-ún lósì sí ẹni tí ó bá wò ó pé ẹ kò fi ọ̀rọ̀ oriṣa ṣeré. 23Bí mo ti ń lọ tí mò ń bọ̀ ni mò ń fojú wo àwọn ohun tí ẹ̀ ń sìn. Mo rí pẹpẹ ìrúbọ kan tí ẹ kọ àkọlé báyìí sí ara rẹ̀ pé: ‘Sí Ọlọrun tí ẹnìkan kò mọ̀.’ Ohun tí ẹ kò mọ̀ tí ẹ̀ ń sìn, òun ni mò ń sọ̀rọ̀ rẹ̀ fun yín.#Ọgb 13:1 24Ọlọrun tí ó dá ayé ati gbogbo nǹkan tí ó wà ninu rẹ̀, Oluwa ọ̀run ati ayé, kì í gbé ilé oriṣa àfọwọ́kọ́;#1 A. Ọba 8:27; Ais 42:5; A. Apo 7:48 25bẹ́ẹ̀ ni kò sí ohun tí kò ní, tí a óo sọ pé kí eniyan fún un, nítorí òun fúnra rẹ̀ ni ó ń fún gbogbo eniyan ní ẹ̀mí, èémí ati ohun gbogbo.#2 Makab 14:35 26Òun ni ó dá gbogbo orílẹ̀-èdè láti inú ẹnìkan ṣoṣo láti máa gbé gbogbo ilẹ̀ ayé. Kí ó tó dá wọn, ó ti ṣe ìpinnu tẹ́lẹ̀ nípa ìgbà tí wọn yóo gbé ní ayé ati ààlà ibi tí wọn yóo máa gbé.#2 Makab 7:23 27Ó dá wọn láti máa wá òun Ọlọrun, bí ó bá ṣeéṣe, kí wọ́n fọwọ́ kàn án, kí wọ́n rí i. Kò sì kúkú jìnnà sí ẹnìkan kan ninu wa.#Ọgb 13:6-9 28Nítorí ẹnìkan sọ níbìkan pé:
‘Ninu rẹ̀ ni à ń gbé,
tí à ń rìn kiri,
tí a wà láàyè.’
Àwọn kan ninu àwọn akéwì yín pàápàá ti sọ ohun tó jọ bẹ́ẹ̀; wọ́n ní,
‘Ọmọ rẹ̀ ni a jẹ́.’
29Nígbà tí a jẹ́ ọmọ Ọlọrun, kò yẹ kí á rò pé Ọlọrun dàbí ère wúrà, tabi fadaka, tabi òkúta, ère tí oníṣẹ́ ọnà ṣe pẹlu ọgbọ́n ati èrò eniyan. 30Ọlọrun ti fojú fo àkókò tí eniyan kò ní ìmọ̀ dá. Ṣugbọn ní àkókò yìí, ó pàṣẹ fún gbogbo eniyan ní ibi gbogbo láti ronupiwada. 31Nítorí ó ti yan ọjọ́ tí yóo fi òdodo ṣe ìdájọ́ gbogbo ayé nípa ọkunrin tí ó ti yàn. Ó fi òtítọ́ èyí han gbogbo eniyan nígbà tí ó jí ẹni náà dìde kúrò ninu òkú.”
32Nígbà tí wọ́n gbọ́ pé òkú jinde, àwọn kan ń ṣe yẹ̀yẹ́, àwọn mìíràn ní, “A tún fẹ́ gbọ́ nípa ọ̀rọ̀ yìí nígbà mìíràn.” 33Paulu bá jáde kúrò láàrin wọn. 34Àwọn kan ninu wọn bá fara mọ́ ọn, wọ́n sì gbàgbọ́. Ọ̀kan ninu wọn ni Dionisu, adájọ́ ní kóòtù Òkè Areopagu, ati obinrin kan tí ń jẹ́ Damarisi ati àwọn ẹlòmíràn pẹlu wọn.
Àwon tá yàn lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí:
ÌṢE ÀWỌN APOSTELI 17: YCE
Ìsàmì-sí
Pín
Daako
Ṣé o fẹ́ fi àwọn ohun pàtàkì pamọ́ sórí gbogbo àwọn ẹ̀rọ rẹ? Wọlé pẹ̀lú àkántì tuntun tàbí wọlé pẹ̀lú àkántì tí tẹ́lẹ̀
Bible Society of Nigeria © 1900/2010