DANIẸLI 6:26-27

DANIẸLI 6:26-27 YCE

mo pàṣẹ pé ní gbogbo ìjọba mi, kí gbogbo eniyan máa wárìrì níwájú Ọlọrun Daniẹli, kí wọ́n sì máa bẹ̀rù rẹ̀. “Nítorí òun ni Ọlọrun Alààyè tí ó wà títí ayérayé. Ìjọba rẹ̀ kò lè parun lae, àṣẹ rẹ̀ yóo sì máa wà títí dé òpin. Ó ń gbani là, ó ń dáni nídè. Ó ń ṣiṣẹ́ àánú tí ó yani lẹ́nu ní ọ̀run ati ní ayé. Òun ni ó gba Daniẹli lọ́wọ́ agbára kinniun.”