Dan 6:26-27
Dan 6:26-27 Bibeli Mimọ (YBCV)
Mo paṣẹ pe, Ni gbogbo igberiko ijọba mi, ki awọn enia ki o ma warìri, ki nwọn si ma bẹ̀ru niwaju Ọlọrun Danieli, nitoripe on li Ọlọrun alãye, on si duro lailai, ati ijọba rẹ̀, eyi ti a kì yio le parun ni, ati agbara ijọba rẹ̀ yio si wà titi de opin. O ngbà ni, o si nyọ ni, o si nṣe iṣẹ-ami ati iṣẹ-iyanu li ọrun ati li aiye, ẹniti o gbà Danieli là lọwọ awọn kiniun.
Dan 6:26-27 Yoruba Bible (YCE)
mo pàṣẹ pé ní gbogbo ìjọba mi, kí gbogbo eniyan máa wárìrì níwájú Ọlọrun Daniẹli, kí wọ́n sì máa bẹ̀rù rẹ̀. “Nítorí òun ni Ọlọrun Alààyè tí ó wà títí ayérayé. Ìjọba rẹ̀ kò lè parun lae, àṣẹ rẹ̀ yóo sì máa wà títí dé òpin. Ó ń gbani là, ó ń dáni nídè. Ó ń ṣiṣẹ́ àánú tí ó yani lẹ́nu ní ọ̀run ati ní ayé. Òun ni ó gba Daniẹli lọ́wọ́ agbára kinniun.”
Dan 6:26-27 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
“Mo gbé àṣẹ kan jáde wí pé: ní gbogbo agbègbè ìjọba mi, gbogbo ènìyàn gbọdọ̀ bẹ̀rù, kí wọn kí ó sì bọ̀wọ̀ fún Ọlọ́run Daniẹli. “Nítorí òun ni Ọlọ́run alààyè Ó sì wà títí ayé; Ìjọba rẹ̀ kò le è parun ìjọba rẹ̀ kò ní ìpẹ̀kun Ó ń yọ ni, ó sì ń gbani là; ó ń ṣe iṣẹ́ ààmì àti ìyanu ní ọ̀run àti ní ayé. Òun ló gba Daniẹli là kúrò lọ́wọ́ agbára kìnnìún.”