DIUTARONOMI 25
25
1“Bí èdè-àìyedè kan bá bẹ́ sílẹ̀ láàrin àwọn ọmọ meji, tí wọ́n bá lọ sí ilé ẹjọ́, tí àwọn adájọ́ sì dá ẹjọ́ náà fún wọn, tí wọ́n dá ẹni tí ó jàre láre, tí wọ́n sì dá ẹni tí ó jẹ̀bi lẹ́bi, 2bí ó bá jẹ́ pé nínà ni ó yẹ kí wọ́n na ẹni tí ó jẹ̀bi, ẹni náà yóo dọ̀bálẹ̀ níwájú adájọ́, wọn yóo sì nà án ní iye ẹgba tí ó bá tọ́ sí i gẹ́gẹ́ bí ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀. 3Ṣugbọn wọn kò gbọdọ̀ nà án ju ogoji ẹgba lọ, ohun ìtìjú ni yóo jẹ́ fún un ní gbangba, bí wọ́n bá nà án jù bẹ́ẹ̀ lọ.#2 Kọr 11:24
4“Ẹ kò gbọdọ̀ dí mààlúù lẹ́nu nígbà tí ẹ bá ń lò ó láti fi pa ọkà.#Mat 22:24; Mak 12:19; Luk 20:28.
Ojúṣe Ẹni sí Arakunrin Ẹni Tí Ó Ṣaláìsí
5“Bí àwọn arakunrin meji bá jùmọ̀ ń gbé pọ̀, tí ọ̀kan ninu wọn sì kú láìní ọmọkunrin, aya ẹni tí ó kú kò gbọdọ̀ lọ fẹ́ ará ìta tabi àlejò. Arakunrin ọkọ rẹ̀ ni ó gbọdọ̀ ṣú u lópó, kí ó sì máa ṣe gbogbo ẹ̀tọ́ tí ó bá yẹ fún obinrin náà. 6Wọn yóo ka ọmọkunrin kinni tí opó yìí bá bí sí ọmọ ọkọ rẹ̀ tí ó kú, kí orúkọ ọkọ rẹ̀ náà má baà parẹ́ ní Israẹli. 7Bí ọkunrin yìí kò bá wá fẹ́ ṣú aya arakunrin rẹ̀ tí ó kú lópó, obinrin náà yóo tọ àwọn àgbààgbà lọ ní ẹnubodè, yóo sì wí pé, ‘Arakunrin ọkọ mi kọ̀ láti gbé orúkọ arakunrin rẹ̀ ró ní Israẹli, ó kọ̀ láti ṣe ojúṣe rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí arakunrin ọkọ mi.’ 8Àwọn àgbààgbà ìlú yóo pe ọkunrin náà, wọn óo bá a sọ̀rọ̀, bí ó bá kọ̀ jálẹ̀, tí ó wí pé, ‘Èmi kò fẹ́ fẹ́ ẹ,’ 9Lẹ́yìn náà, obinrin náà yóo tọ̀ ọ́ lọ lójú gbogbo àwọn àgbààgbà, yóo bọ́ bàtà ẹsẹ̀ rẹ̀, yóo tutọ́ sí i lójú, yóo sì wí pé, ‘Bẹ́ẹ̀ ni wọ́n ṣe sí ẹni tí ó bá kọ̀ láti kọ́ ilé arakunrin rẹ̀.’ 10Wọn yóo sì máa pe ìdílé rẹ̀ ní ìdílé ẹni tí wọ́n bọ́ bàtà lẹ́sẹ̀ rẹ̀.#Rut 4:7-8
Àwọn Òfin Mìíràn
11“Bí ọkunrin meji bá ń jà, tí iyawo ọ̀kan ninu wọn bá sáré wá láti gbèjà ọkọ rẹ̀ tí wọn ń lù, tí ó bá fa nǹkan ọkunrin ẹni tí ń lu ọkọ rẹ̀ yìí, 12gígé ni kí ẹ gé ọwọ́ rẹ̀, ẹ kò gbọdọ̀ ṣàánú rẹ̀ rárá.
13“O kò gbọdọ̀ ní oríṣìí ìwọ̀n meji ninu àpò rẹ, kí ọ̀kan kéré, kí ekeji sì tóbi. 14O kò gbọdọ̀ ní oríṣìí òṣùnwọ̀n meji ninu ilé rẹ, kí ọ̀kan kéré, kí ekeji sì tóbi. 15Ṣugbọn ìwọ̀n ati òṣùnwọ̀n rẹ gbọdọ̀ péye, kí ọjọ́ rẹ lè pẹ́ lórí ilẹ̀ tí OLUWA Ọlọrun rẹ fún ọ. 16Nítorí pé ẹnikẹ́ni tí ó bá ń ṣe aiṣootọ, ìríra ni lójú OLUWA Ọlọrun yín.#Lef 19:35-36
Òfin láti Pa Àwọn Ará Amaleki
17“Ẹ ranti ohun tí àwọn ará Amaleki ṣe sí yín nígbà tí ẹ̀ ń bọ̀ láti Ijipti. 18Wọn kò bẹ̀rù Ọlọrun, ṣugbọn wọ́n gbógun tì yín lójú ọ̀nà nígbà tí ó ti rẹ̀ yín, wọ́n sì pa gbogbo àwọn tí wọn ń bọ̀ lẹ́yìn. 19Nítorí náà nígbà tí OLUWA Ọlọrun yín bá fun yín ní ìṣẹ́gun lórí gbogbo àwọn ọ̀tá yín tí wọ́n wà ní àyíká yín, ní ilẹ̀ tí OLUWA Ọlọrun yín fun yín, pípa ni kí ẹ pa àwọn ará Amaleki run lórí ilẹ̀ ayé. Ẹ kò gbọdọ̀ gbàgbé.#Eks 17:8-14; 1 Sam 15:2-9
Àwon tá yàn lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí:
DIUTARONOMI 25: YCE
Ìsàmì-sí
Pín
Daako
![None](/_next/image?url=https%3A%2F%2Fimageproxy.youversionapistaging.com%2F58%2Fhttps%3A%2F%2Fweb-assets.youversion.com%2Fapp-icons%2Fyo.png&w=128&q=75)
Ṣé o fẹ́ fi àwọn ohun pàtàkì pamọ́ sórí gbogbo àwọn ẹ̀rọ rẹ? Wọlé pẹ̀lú àkántì tuntun tàbí wọlé pẹ̀lú àkántì tí tẹ́lẹ̀
Bible Society of Nigeria © 1900/2010