DIUTARONOMI 26

26
Ọrẹ Ìkórè
1“Nígbà tí o bá dé orí ilẹ̀ tí OLUWA Ọlọrun rẹ fún ọ, tí o gbà á, tí o sì ń gbé inú rẹ̀, 2mú ninu àkọ́so èso ilẹ̀ náà sinu agbọ̀n kan, kí o sì gbé e lọ sí ibi tí OLUWA Ọlọrun rẹ yóo yàn pé kí ẹ ti máa sin òun.#Eks 23:19 3Tọ alufaa tí ó wà lẹ́nu iṣẹ́ ní àkókò náà lọ, kí o sì wí fún un pé, ‘Mò ń wí fún OLUWA Ọlọrun mi lónìí pé, mo ti dé ilẹ̀ tí ó ti búra fún àwọn baba wa láti fún wa.’
4“Alufaa yóo gba agbọ̀n èso náà ní ọwọ́ rẹ, yóo sì gbé e kalẹ̀ níwájú pẹpẹ OLUWA Ọlọrun rẹ. 5Lẹ́yìn náà, o óo wí báyìí níwájú OLUWA Ọlọrun rẹ pé, ‘Ará Aramea, alárìnká, ni baba ńlá mi, ó lọ sí ilẹ̀ Ijipti, ó sì jẹ́ àlejò níbẹ̀. Wọn kò pọ̀ rárá tẹ́lẹ̀, ṣugbọn níbẹ̀ ni wọ́n ti di pupọ, wọ́n sì di orílẹ̀-èdè ńlá, tí ó lágbára, tí ó sì lókìkí. 6Àwọn ará Ijipti lò wá ní ìlò ìkà, wọ́n pọ́n wa lójú, wọ́n sì mú wa sìn bí ẹrú. 7A bá kígbe pe OLUWA Ọlọrun àwọn baba wa; ó gbọ́ ohùn wa, ó rí ìpọ́njú, ati ìṣẹ́, ati ìjìyà wa. 8OLUWA fi agbára rẹ̀ kó wa jáde láti Ijipti, pẹlu àwọn iṣẹ́ àmì ati iṣẹ́ ìyanu. 9Ó kó wa wá sí ìhín, ó sì fún wa ní ilẹ̀ yìí; ilẹ̀ tí ó ní ọ̀rá tí ó kún fún wàrà ati oyin. 10Nítorí náà, nisinsinyii, mo mú àkọ́so èso ilẹ̀ tí ìwọ OLUWA ti fi fún mi wá.’
“Lẹ́yìn náà, gbé e kalẹ̀ níwájú OLUWA Ọlọrun rẹ, kí o sì sìn ín; 11kí o sì bẹ̀rẹ̀ sí yọ̀ fún ohun tí OLUWA fún ìwọ ati ìdílé rẹ, kí àwọn ọmọ Lefi ati àwọn àlejò tí ń gbé ààrin yín náà sì máa bá ọ ṣe àjọyọ̀.
12“Ní ọdún kẹtakẹta, tíí ṣe ọdún ìdámẹ́wàá, tí o bá ti dá ìdámẹ́wàá gbogbo ìkórè oko rẹ, kí o kó wọn fún àwọn ọmọ Lefi, ati àwọn àlejò, ati àwọn aláìní baba, ati àwọn opó, kí wọ́n lè máa jẹ àjẹyó ninu ìlú yín.#Diut 14:28-29 13Lẹ́yìn náà, kí o wí níwájú OLUWA Ọlọrun rẹ pé, ‘Gbogbo ìdámẹ́wàá tíí ṣe ohun ìyàsímímọ́ ni mo ti mú kúrò ninu ilé mi, mo sì ti fi fún àwọn ọmọ Lefi ati àwọn àlejò, ati àwọn aláìní baba, ati àwọn opó, gẹ́gẹ́ bíi gbogbo àṣẹ tí o pa fún mi. N kò rú èyíkéyìí ninu àwọn òfin rẹ, bẹ́ẹ̀ ni n kò sì gbàgbé wọn. 14N kò jẹ ninu ìdámẹ́wàá mi nígbà tí mò ń ṣọ̀fọ̀, bẹ́ẹ̀ ni n kò kó èyíkéyìí jáde kúrò ninu ilé mi nígbà tí mo jẹ́ aláìmọ́, tabi kí n fi èyíkéyìí ninu wọn bọ òkú ọ̀run. Gbogbo ohun tí o wí ni mo ti ṣe, OLUWA Ọlọrun mi, mo sì ti pa gbogbo àṣẹ rẹ mọ́. 15Bojúwo ilẹ̀ láti ibùgbé mímọ́ rẹ lọ́run, kí o sì bukun Israẹli, àwọn eniyan rẹ, ati ilẹ̀ tí o ti fi fún wa gẹ́gẹ́ bí o ti ṣèlérí fún àwọn baba wa, ilẹ̀ tí ó kún fún wàrà ati oyin.’
Àwọn Eniyan OLUWA
16“OLUWA Ọlọrun rẹ pàṣẹ fún ọ lónìí, pé kí o máa pa gbogbo ìlànà ati òfin wọnyi mọ́. Nítorí náà, máa pa gbogbo wọn mọ́ tọkàntọkàn. 17O ti fi ẹnu ara rẹ sọ lónìí pé, OLUWA ni Ọlọrun rẹ, ati pé o óo máa rìn ní ọ̀nà rẹ̀, o óo máa pa gbogbo ìlànà ati òfin ati ìdájọ́ rẹ̀ mọ́, o óo sì máa gbọ́ tirẹ̀. 18OLUWA pàápàá sì ti sọ lónìí pé, eniyan òun ni ọ́, gẹ́gẹ́ bí ó ti ṣèlérí fún ọ, ati pé kí o pa gbogbo òfin òun mọ́. 19Ó ní òun óo gbé ọ ga ju gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè yòókù tí ó dá lọ. O óo níyì jù wọ́n lọ; o óo ní òkìkí jù wọ́n lọ, o óo sì lọ́lá jù wọ́n lọ. O óo jẹ́ ẹni ìyàsọ́tọ̀ fún OLUWA Ọlọrun rẹ, gẹ́gẹ́ bí ó ti ṣèlérí.”#Eks 19:5; Diut 4:20; 7:6; 14:2; Tit 2:14; 1 Pet 2:9

Àwon tá yàn lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí:

DIUTARONOMI 26: YCE

Ìsàmì-sí

Pín

Daako

None

Ṣé o fẹ́ fi àwọn ohun pàtàkì pamọ́ sórí gbogbo àwọn ẹ̀rọ rẹ? Wọlé pẹ̀lú àkántì tuntun tàbí wọlé pẹ̀lú àkántì tí tẹ́lẹ̀