GALATIA 4

4
1Ohun tí mò ń sọ ni pé nígbà tí àrólé bá wà ní ọmọde kò sàn ju ẹrú lọ́, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé òun ni ó ni gbogbo nǹkan tí Baba rẹ̀ fi sílẹ̀. 2Nítorí pé òun alára wà lábẹ́ àwọn olùtọ́jú, ohun ìní rẹ̀ sì wà ní ìkáwọ́ àwọn alámòójútó títí di àkókò tí baba rẹ̀ ti dá. 3Bẹ́ẹ̀ gan-an ni ó rí pẹlu wa. Nígbà tí a jẹ́ ọmọde, a jẹ́ ẹrú àwọn oríṣìíríṣìí ẹ̀mí tí a kò fojú rí. 4Ṣugbọn nígbà tí ó tó àkókò tí ó wọ̀, Ọlọrun rán Ọmọ rẹ̀ wá. Obinrin ni ó bí i, ó bí i lábẹ́ òfin àwọn Juu, 5kí ó lè ra àwọn tí ó wà lábẹ́ òfin pada, kí á lè sọ wá di ọmọ.#Rom 8:15-17
6Ọlọrun rán ẹ̀mí ọmọ rẹ̀ sinu ọkàn wa, Ẹ̀mí yìí ń ké pé, “Baba!” láti fihàn pé ọmọ ni ẹ jẹ́. 7Nítorí náà, ẹ kì í ṣe ẹrú mọ́ bíkòṣe ọmọ. Bí ẹ bá wá jẹ́ ọmọ, ẹ di ajogún nípasẹ̀ iṣẹ́ Ọlọrun.
Paulu Ní Àníyàn fún Àwọn Ará Galatia
8Ṣugbọn nígbà tí ẹ kò mọ Ọlọrun, ẹ di ẹrú àwọn ẹ̀dá tí kì í ṣe Ọlọrun. 9Nisinsinyii ẹ mọ Ọlọrun, tabi kí á kúkú wí pé Ọlọrun mọ̀ yín. Báwo ni ẹ ṣe tún fẹ́ yipada sí àwọn ẹ̀mí tí a kò fi ojú rí, tí wọ́n jẹ́ aláìlera ati aláìní, tí ẹ tún fẹ́ máa lọ ṣe ẹrú wọn? 10Ẹ̀ ń ya oríṣìíríṣìí ọjọ́ sọ́tọ̀, ẹ̀ ń ranti oṣù titun, àkókò ati àjọ̀dún! 11Ẹ̀rù yín ń bà mí pé kí gbogbo làálàá mi lórí yín má wá jẹ́ lásán!
12Ẹ̀yin ará, mo bẹ̀ yín ni, ẹ dàbí mo ti dà nítorí èmi náà ti dàbí yín. Ẹ kò ṣẹ̀ mí rárá. 13Ẹ mọ̀ pé àìlera ni ó mú kí n waasu ìyìn rere fun yín ní àkọ́kọ́. 14Ẹ kò kọ ohun tí ó jẹ́ ìdánwò fun yín ninu ara mi, bẹ́ẹ̀ ni ẹ kò fi mí ṣẹ̀sín, ṣugbọn ẹ gbà mí bí ẹni pé angẹli Ọlọrun ni mí, àní bí ẹni pé èmi ni Kristi Jesu. 15Kò sí bí inú yín kò ti dùn tó nígbà náà. Kí ni ó wá dé nisinsinyii! Nítorí mo jẹ́rìí yín pé bí ó bá ṣeéṣe nígbà náà ẹ̀ bá yọ ojú yín fún mi! 16Mo wá ti di ọ̀tá yín nítorí mo sọ òtítọ́ fun yín!
17Kì í ṣe ire yín ni àwọn tí wọn ń ṣaájò yín ń wá. Ohun tí wọn ń wá ni kí wọ́n lè fi yín sinu àhámọ́, kí ẹ lè máa wá wọn. 18Ó dára kí á máa wá ara ẹni ninu ohun rere nígbà gbogbo, kì í ṣe nígbà tí mo bá wà pẹlu yín nìkan. 19Ẹ̀yin ọmọ mi, ara ń ni mí nítorí yín, bí obinrin tí ń rọbí lọ́wọ́, títí ẹ óo fi di àwòrán Kristi. 20Ó wù mí bíi pé kí n wà lọ́dọ̀ yín nisinsinyii, kí n yí ohùn mi pada, nítorí ọ̀rọ̀ yín rú mi lójú.
Àkàwé Hagari ati Sara
21Ẹ sọ fún mi, ẹ̀yin tí ẹ fẹ́ wà lábẹ́ òfin: ṣé ẹ gbọ́ ohun tí òfin wí? 22Nítorí ó wà ní àkọsílẹ̀ pé Abrahamu ní ọmọ meji, ọ̀kan ọmọ ẹrubinrin, ọ̀kan ọmọ obinrin tí ó ní òmìnira.#a Jẹn 16:15; b Jẹn 21:2 23Ó bí ọmọ ti ẹrubinrin nípa ìfẹ́ ara, ṣugbọn ó bí ọmọ ti obinrin tí ó ní òmìnira nípa ìlérí Ọlọrun. 24Àkàwé ni nǹkan wọnyi. Obinrin mejeeji yìí jẹ́ majẹmu meji, ọ̀kan láti òkè Sinai, tí ọmọ rẹ̀ jẹ́ ẹrú; èyí ni Hagari. 25Hagari ni òkè Sinai ní Arabia tíí ṣe àpẹẹrẹ Jerusalẹmu ti òní. Ó wà ninu ipò ẹrú pẹlu àwọn ọmọ rẹ̀. 26Ṣugbọn Jerusalẹmu ti òkè wà ninu òmìnira. Òun ni ìyá wa. 27Nítorí ó wà ní àkọsílẹ̀ pé,#Ais 54:1
“Máa yọ̀, ìwọ àgàn tí kò bímọ rí.
Sọ̀rọ̀ kí o kígbe sókè, ìwọ tí kò rọbí rí.
Nítorí àwọn ọmọ àgàn pọ̀ ju ti obinrin tí ó ní ọkọ lọ.”
28Ṣugbọn ẹ̀yin, ará, ọmọ ìlérí bíi Isaaki ni yín. 29Ṣugbọn bí ó ti rí látijọ́, tí ọmọ tí a bí nípa ìfẹ́ ara ń ṣe inúnibíni ọmọ tí a bí nípa Ẹ̀mí, bẹ́ẹ̀ náà ni ó wà títí di ìsinsìnyìí.#Jẹn 21:9 30Ṣugbọn kí ni Ìwé Mímọ́ wí? Ó ní, “Lé ẹrubinrin ati ọmọ rẹ̀ jáde, nítorí ọmọ ẹrubinrin kò ní bá ọmọ obinrin tí ó ní òmìnira pín ogún baba wọn.”#Jẹn 21:10 31Nítorí náà, ará, a kì í ṣe ọmọ ẹrubinrin, ọmọ obinrin tí ó ní òmìnira ni wá.

Àwon tá yàn lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí:

GALATIA 4: YCE

Ìsàmì-sí

Pín

Daako

None

Ṣé o fẹ́ fi àwọn ohun pàtàkì pamọ́ sórí gbogbo àwọn ẹ̀rọ rẹ? Wọlé pẹ̀lú àkántì tuntun tàbí wọlé pẹ̀lú àkántì tí tẹ́lẹ̀