GALATIA 5

5
Òmìnira Onigbagbọ
1Irú òmìnira yìí ni a ní. Kristi ti sọ wá di òmìnira. Ẹ dúró ninu rẹ̀, kí ẹ má sì tún gbé àjàgà ẹrú kọ́rùn mọ́.
2Èmi Paulu ni mo wí fun yín pé bí ẹ bá kọlà, Kristi kò ṣe yín ní anfaani kankan. 3Mo tún wí pé gbogbo ẹni tí a bá kọ nílà di ajigbèsè; ó níláti pa gbogbo òfin mọ́. 4Ẹ ti ya ara yín kúrò lọ́dọ̀ Kristi, ẹ̀yin tí ẹ̀ ń fẹ́ ìdáláre nípa òfin. Ẹ ti yapa kúrò ní ọ̀nà oore-ọ̀fẹ́. 5Ṣugbọn ní tiwa, nípasẹ̀ Ẹ̀mí ni à ń retí ìdáláre nípa igbagbọ. 6Nítorí ọ̀ràn pé a kọlà tabi a kò kọlà kò jẹ́ nǹkankan fún àwọn tí ó wà ninu Kristi Jesu. Ohun tí ó ṣe kókó ni igbagbọ tí ó ń ṣiṣẹ́ nípa ìfẹ́.
7Ẹ ti ń sáré ìje dáradára bọ̀. Ta ni kò jẹ́ kí ẹ gba òtítọ́ mọ́? 8Ìyípadà ọkàn yín kì í ṣe láti ọ̀dọ̀ Ọlọrun tí ó pè yín. 9Ìwúkàrà díẹ̀ níí mú kí gbogbo ìyẹ̀fun wú sókè.#1 Kọr 5:6 10Mo ní ìdánilójú ninu Oluwa pé ẹ kò ní ní ọkàn mìíràn. Ṣugbọn ẹni tí ó ń yọ yín lẹ́nu yóo gba ìdájọ́ Ọlọrun, ẹni yòówù kí ó jẹ́.
11Ará, tí ó bá jẹ́ pé iwaasu pé kí eniyan kọlà ni mò ń wà, kí ló dé tí wọ́n fi ń ṣe inúnibíni sí mi? Ǹjẹ́ a ti mú ohun ìkọsẹ̀ agbelebu Kristi kúrò? 12Ìbá wù mí kí àwọn tí ó ń yọ yín lẹ́nu kúkú gé ara wọn sọnù patapata!
13Òmìnira ni a pè yín sí, ẹ̀yin ará, ṣugbọn kí ẹ má ṣe lo òmìnira yín fún ìtẹ́lọ́rùn ara yín, ìfẹ́ ni kí ẹ máa fi ran ara yín lọ́wọ́. 14Nítorí gbolohun kan kó gbogbo òfin já, èyí ni pé “Fẹ́ràn ẹnìkejì rẹ bí ara rẹ.”#Lef 19:18 15Ṣugbọn bí ẹ bá ń bá ara yín jà, tí ẹ̀ ń bu ara yín ṣán, ẹ ṣọ́ra kí ẹ má baà pa ara yín run.
Èso Ti Ẹ̀mí ati Àwọn Iṣẹ́ Ti Ara
16Ṣugbọn mò ń sọ fun yín pé kí ẹ jẹ́ kí Ẹ̀mí máa darí ìgbé-ayé yín, tí ẹ bá ń ṣe bẹ́ẹ̀ ẹ kò ní mú ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ ara ṣẹ. 17Nítorí ohun tí ara ń fẹ́ lòdì sí àwọn nǹkan ti Ẹ̀mí; bẹ́ẹ̀ sì ni ohun tí Ẹ̀mí ń fẹ́ lòdì sí àwọn nǹkan ti ara. Ẹ̀mí ati ara lòdì sí ara wọn. Àyọrísí rẹ̀ ni pé ẹ kì í lè ṣe àwọn ohun tí ó wù yín láti ṣe.#Rom 7:15-23 18Bí Ẹ̀mí bá ń darí yín, ẹ kò sí lábẹ́ òfin.
19Àwọn iṣẹ́ ara farahàn gbangba. Àwọn ni àgbèrè, ìwà èérí, wọ̀bìà; 20ìbọ̀rìṣà, oṣó, odì-yíyàn, ìjà, owú-jíjẹ, ìrúnú, ọ̀kánjúwà, ìyapa, rìkíṣí; 21inú burúkú, ìmutípara, àríyá àwọn ọ̀mùtí ati irú nǹkan bẹ́ẹ̀. Ohun tí mo ti sọ fun yín tẹ́lẹ̀, ni mo tún ń sọ fun yín, pé àwọn tí ó ń ṣe irú nǹkan bẹ́ẹ̀ kò ní jogún ìjọba Ọlọrun.
22Ṣugbọn èso ti Ẹ̀mí ni ìfẹ́, ayọ̀, alaafia, sùúrù, àánú, iṣẹ́ rere, ìṣòtítọ́, 23ìwà pẹ̀lẹ́, ìsẹ́ra-ẹni. Kò sí òfin kan tí ó lòdì sí irú nǹkan báwọ̀nyí. 24Àwọn tíí ṣe ti Kristi Jesu ti kan àwọn nǹkan ti ara mọ́ agbelebu pẹlu ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ ati ìgbádùn ara. 25Bí a bá wà láàyè nípa Ẹ̀mí, ẹ jẹ́ kí á máa gbé ìgbé-ayé ti Ẹ̀mí. 26Ẹ má jẹ́ kí á máa ṣe ògo asán, kí á má máa rú ìjà sókè láàrin ara wa, kí á má sì máa jowú ara wa.

Àwon tá yàn lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí:

GALATIA 5: YCE

Ìsàmì-sí

Pín

Daako

None

Ṣé o fẹ́ fi àwọn ohun pàtàkì pamọ́ sórí gbogbo àwọn ẹ̀rọ rẹ? Wọlé pẹ̀lú àkántì tuntun tàbí wọlé pẹ̀lú àkántì tí tẹ́lẹ̀