AISAYA 16

16
Kò sí Ìrètí fún Moabu Mọ́
1Wọ́n ti kó àgbò láti Sela, ní ọ̀nà aṣálẹ̀,
wọ́n fi ranṣẹ sí aláṣẹ ilẹ̀ náà, ní òkè Sioni.
2Àwọn ọmọbinrin Moabu dúró létí odò Anoni,
wọ́n ń rìn síwá, sẹ́yìn,
wọ́n ń lọ sókè, sódò,
bí ọmọ ẹyẹ tí a lé kúrò ninu ìtẹ́.
3“Gbà wá ní ìmọ̀ràn,
máa ṣe ẹ̀tọ́ fún wa.
Fi òjìji rẹ dáàbò bò wá,
kí ara lè tù wá lọ́sàn-án gangan,
bí ẹni pé alẹ́ ni.
Dáàbò bo àwọn tí a lé jáde;
má tú àṣírí ẹni tí ń sálọ.
4Jẹ́ kí àwọn tí a lé jáde ní Moabu, máa gbé ààrin yín.
Dáàbò bò wọ́n lọ́wọ́ àwọn apanirun.”
Nígbà tí aninilára kò bá sí mọ́ tí ìparun bá dópin,
tí atẹnimọ́lẹ̀ bá ti kúrò ní ilẹ̀ náà.
5Nígbà náà a óo fìdí ìtẹ́ múlẹ̀ pẹlu ìfẹ́ tí kì í yẹ̀.
Ẹnìkan tí ń ṣe ìdájọ́ ẹ̀tọ́ ati òdodo yóo jókòó lórí ìtẹ́ náà,
Yóo dúró lórí òtítọ́ ní ìdílé Dafidi.
6A ti gbọ́ ìròyìn ìgbéraga Moabu,
bí ó ṣe ń ṣe àfojúdi tí ó sì ń sọ ìsọkúsọ:
ṣugbọn lásán ni ìgbéraga rẹ̀.
7Nítorí náà, kí Moabu máa pohùnréré ẹkún,
kí gbogbo eniyan máa sun ẹkún arò ní Moabu.
Wọn óo sọkún tẹ̀dùntẹ̀dùn,
nígbà tí wọn ba ranti àkàrà Kiri Heresi,
tí ó ní èso àjàrà ninu.
8Gbogbo oko ni ó rọ ní Heṣiboni;
bẹ́ẹ̀ náà ni ọgbà Sibuma:
àwọn olórí orílẹ̀-èdè ti gé àwọn ẹ̀ka rẹ̀ lulẹ̀,
èyí tí ó tàn kálẹ̀ dé Jaseri títí dé inú aṣálẹ̀.
Ìtàkùn rẹ̀ tàn kálẹ̀,
wọ́n kọjá sí òdìkejì òkun.
9Nítorí náà mo sọkún fún ọgbà àjàrà Sibuma
bí mo ṣe sọkún fún Jaseri;
mo sì sọkún nítorí Heṣiboni ati Eleale,
mo sọkún, omi ń dà lójú mi pòròpòrò
nítorí gbogbo ìkórè yín, ati èso oko yín ni ogun ti kó lọ.
10Wọ́n ti kó ayọ̀ ati ìdùnnú lọ kúrò ninu oko eléso;
ẹnikẹ́ni kò kọrin bẹ́ẹ̀ ni kò sí ariwo híhó ninu ọgbà àjàrà wọn.
Kò sí àwọn tí ó ń pọn ọtí ninu rẹ̀ mọ́
bẹ́ẹ̀ ni a kò gbọ́ ariwo àwọn tí ń pọn ọtí mọ́.
11Nítorí náà, ẹ̀mí mi kọrin arò bíi ti dùùrù fún Moabu,
ọkàn mi kérora, fún Moabu ati Kiri Heresi.
12Nígbà tí Moabu bá wá siwaju,
tí ó fi gbogbo agbára gbadura ninu ilé oriṣa rẹ̀,
títí ó fi rẹ̀ ẹ́,
adura rẹ̀ kò ní gbà.
13Ọ̀rọ̀ tí OLUWA ti kọ́ sọ nípa Moabu tẹ́lẹ̀ nìyí. 14Ṣugbọn nisinsinyii, OLUWA ní, “Nígbà tí a óo fi rí ọdún mẹta, tíí ṣe iye ọdún alágbàṣe, a óo ti sọ ògo Moabu di ilẹ̀. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé eniyan inú rẹ̀ pọ̀, àwọn díẹ̀ ni yóo ṣẹ́kù, àárẹ̀ yóo sì ti mú wọn.”

Àwon tá yàn lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí:

AISAYA 16: YCE

Ìsàmì-sí

Pín

Daako

None

Ṣé o fẹ́ fi àwọn ohun pàtàkì pamọ́ sórí gbogbo àwọn ẹ̀rọ rẹ? Wọlé pẹ̀lú àkántì tuntun tàbí wọlé pẹ̀lú àkántì tí tẹ́lẹ̀