AISAYA 17
17
Ọlọrun Yóo Jẹ Siria ati Israẹli Níyà
1Ọ̀rọ̀ OLUWA sí ilẹ̀ Damasku nìyí:#Jer 49:23-27; Amo 1:3-5; Sek 9:1
“Damasku kò ní jẹ́ ìlú mọ́
òkítì àlàpà ni yóo dà.
2Àwọn ìlú rẹ̀ yóo di àkọ̀tì títí lae
wọn yóo di ibùjẹ àwọn ẹran,
níbi tí àwọn ẹran yóo dùbúlẹ̀,
tí ẹnikẹ́ni kò sì ní dẹ́rùbà wọ́n.
3Ìlú olódi kò ní sí mọ́ ní Efuraimu,
kò sì ní sí ìjọba mọ́ ní Damasku,
àwọn tí wọ́n bá ṣẹ́kù ní Siria
yóo sì dàbí ògo àwọn ọmọ Israẹli,
OLUWA àwọn ọmọ ogun ló sọ bẹ́ẹ̀.
4“Tó bá di ìgbà náà,
a óo rẹ ògo àwọn ọmọ Israẹli sílẹ̀,
ọrọ̀ wọn yóo di àìní.
5Yóo dàbí ìgbà tí eniyan kórè ọkà lóko,
tí ó kó ṣiiri ọkà kún apá.
Tí àwọn kan tún wá ṣa ọkà yòókù,
tí àwọn tí wọn kọ́ kórè ọkà gbàgbé ní àfonífojì Refaimu.
6Àṣàkù yóo kù níbẹ̀,
bí ìgbà tí eniyan gbọn igi olifi,
yóo ku meji tabi mẹta péré ní góńgó orí igi,
tabi bíi mẹrin tabi marun-un lórí ẹ̀ka igi.”
OLUWA Ọlọrun Israẹli ló sọ bẹ́ẹ̀.
7Tó bá di ìgbà náà, àwọn eniyan yóo bọ̀wọ̀ fún Ẹlẹ́dàá wọn, wọn yóo sì máa wo ojú Ẹni Mímọ́ Israẹli. 8Wọn kò ní náání pẹpẹ tí wọ́n fọwọ́ ara wọn tẹ́ bẹ́ẹ̀ ni wọn kò ní gbójúlé àwọn ère tí wọ́n fọwọ́ ara wọn ṣe, ìbáà jẹ́ oriṣa Aṣera tabi pẹpẹ turari. 9Tó bá di ìgbà náà, àwọn ìlú olódi ńláńlá wọn yóo dàbí àwọn ìlú tí àwọn ará Hifi ati àwọn ará Amori sá kúrò níbẹ̀, nígbà tí àwọn ọmọ Israẹli gbógun tì wọ́n; gbogbo rẹ̀ yóo di ahoro.
10Nítorí pé ẹ ti gbàgbé Ọlọrun olùgbàlà yín,
ẹ kò ranti Àpáta tí ó jẹ́ ààbò yín.
Nítorí náà bí ẹ tilẹ̀ gbin igi dáradára tí ẹ̀ ń bọ ọ́,
tí ẹ sì gbin òdòdó àjèjì tí ẹ̀ ń sìn ín;
11wọn ìbáà hù lọ́jọ́ tí ẹ gbìn wọ́n,
kí wọ́n yọ òdòdó ní òwúrọ̀ ọjọ́ tí ẹ lọ́ wọn
sibẹsibẹ kò ní sí ìkórè
ní ọjọ́ ìbànújẹ́ ati ìrora tí kò lóògùn.
A Ṣẹgun Àwọn Ọ̀tá
12Ẹ gbọ́ ariwo ọ̀pọ̀ eniyan,
wọ́n ń hó bí ìgbì òkun.
Ẹ gbọ́ ìró àwọn orílẹ̀-èdè
wọ́n ń hó bíi ríru omi òkun ńlá.
13Ìró àwọn orílẹ̀-èdè dàbí ti omi òkun ńlá
ṣugbọn OLUWA yóo bá wọn wí wọn óo sì sá lọ.
Wọn óo dàbí ìràwé tí afẹ́fẹ́ ń gbé lọ lórí òkè,
ati bí eruku tí ìjì líle ń fẹ́ kiri.
14Ìdágìrì yóo bá wọn ní ìrọ̀lẹ́,
kí ilẹ̀ tó mọ́ wọn kò ní sí mọ́;
bẹ́ẹ̀ ni yóo rí fún àwọn tí wọ́n fogun kó wa,
bẹ́ẹ̀ ni yóo rí fún àwọn tí wọ́n kó wa lẹ́rù lọ.
Àwon tá yàn lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí:
AISAYA 17: YCE
Ìsàmì-sí
Pín
Daako
Ṣé o fẹ́ fi àwọn ohun pàtàkì pamọ́ sórí gbogbo àwọn ẹ̀rọ rẹ? Wọlé pẹ̀lú àkántì tuntun tàbí wọlé pẹ̀lú àkántì tí tẹ́lẹ̀
Bible Society of Nigeria © 1900/2010