AISAYA 18

18
Ọlọrun yóo Jẹ Sudani Níyà
1Ó ṣe,#Sef 2:12
ní òkè àwọn odò kan ní ilẹ̀ Sudani
ibìkan wà tí àwọn ẹyẹ ti ń fò pẹ̀ẹ̀rẹ̀pẹ̀.
2Ẹni tí ó rán ikọ̀ lọ sí òkè odò Naili,
tí wọ́n fẹní ṣọkọ̀ ojú omi.
Ẹ lọ kíá, ẹ̀yin iranṣẹ ayára-bí-àṣá,
ẹ lọ sọ́dọ̀ orílẹ̀-èdè tí ó lágbára, tí ara wọn ń dán,
àwọn tí àwọn eniyan tí wọ́n súnmọ́ wọn
ati àwọn tí ó jìnnà sí wọn ń bẹ̀rù.
Orílẹ̀-èdè tí ó lágbára, tíí sìí máa ń ṣẹgun ọ̀tá,
àwọn tí odò la ilẹ̀ wọn kọjá.
3Gbogbo aráyé,
ẹ̀yin tí ń gbé orí ilẹ̀ ayé,
nígbà tí a bá gbé àsíá sókè lórí àwọn òkè,
ẹ wò ó, nígbà tí a bá fun fèrè ogun, ẹ gbọ́.
4Nítorí pé OLUWA sọ fún mi pé
òun óo fi pẹ̀lẹ́pẹ̀lẹ́ wolẹ̀ láti ibi ibùgbé òun
bí ìmọ́lẹ̀ ní ọ̀sán gangan,
ati bí ìkùukùu ninu ooru ìgbà ìkórè.
5Nítorí pé kí ó tó di ìgbà ìkórè,
lẹ́yìn tí ìtànná àjàrà bá ti rẹ̀, tí ó di èso,
tí àjàrà bẹ̀rẹ̀ sí gbó, tí ó ń pọ́n bọ̀,
ọ̀tá yóo ti dòjé bọ àwọn ìtàkùn àjàrà,
yóo sì gé gbogbo ẹ̀ka rẹ̀ kúrò.
6Gbogbo wọn yóo wà nílẹ̀,
wọn yóo di ìjẹ fún àwọn ẹyẹ orí òkè,
ati àwọn ẹranko inú ìgbẹ́.
Àwọn ẹyẹ yóo fi wọ́n ṣe oúnjẹ ní ìgbà ẹ̀ẹ̀rùn,
àwọn ẹranko yóo fi wọ́n ṣe oúnjẹ jẹ ní ìgbà òtútù.
7Ní àkókò náà, àwọn eniyan tí wọ́n ga, tí wọ́n sì ń dán,
tí àwọn tí wọ́n súnmọ́ wọn, ati àwọn tí wọ́n jìnnà sí wọn ń bẹ̀rù,
orílẹ̀-èdè tí ó lágbára, tíí sì í máa ń ṣẹgun ọ̀tá,
tí odò la ilẹ̀ wọn kọjá,
wọn óo mú ẹ̀bùn wá fún OLUWA àwọn ọmọ ogun,
ní orí òkè Sioni, tí àwọn eniyan ń jọ́sìn ní orúkọ OLUWA àwọn ọmọ ogun.

Àwon tá yàn lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí:

AISAYA 18: YCE

Ìsàmì-sí

Pín

Daako

None

Ṣé o fẹ́ fi àwọn ohun pàtàkì pamọ́ sórí gbogbo àwọn ẹ̀rọ rẹ? Wọlé pẹ̀lú àkántì tuntun tàbí wọlé pẹ̀lú àkántì tí tẹ́lẹ̀