AISAYA 40:30-31

AISAYA 40:30-31 YCE

Yóo rẹ àwọn ọ̀dọ́ pàápàá, agara óo sì dá wọn, àwọn ọdọmọkunrin yóo tilẹ̀ ṣubú lulẹ̀ patapata. Ṣugbọn àwọn tí ó bá dúró de OLUWA yóo máa gba agbára kún agbára. Wọn óo máa fi ìyẹ́ fò lọ sókè bí ẹyẹ idì. Wọn óo máa sáré, agara kò ní dá wọn; wọn óo máa rìn, kò sì ní rẹ̀ wọ́n.