JEREMAYA 6
6
Àwọn Ọ̀tá Yí Jerusalẹmu Ká
1Ẹ̀yin ọmọ Bẹnjamini, ẹ sá àsálà!
Ẹ sá kúrò ní Jerusalẹmu.
Ẹ fọn fèrè ogun ní Tekoa,
kí ẹ ṣe ìkìlọ̀ fún wọn ní Beti Hakikeremu,
nítorí pé nǹkan burúkú
ati ìparun ńlá ń bọ̀ láti ìhà àríwá.
2Jerusalẹmu, Ìlú Sioni dára, ó sì lẹ́wà,
ṣugbọn n óo pa á run.
3Àwọn ọba ati àwọn ọmọ ogun wọn yóo kọlù ú,
wọn yóo pa àgọ́ yí i ká,
ẹgbẹ́ ọmọ ogun kọ̀ọ̀kan yóo pàgọ́ sí ibi tí ó wù ú.
4Wọn yóo sì wí pé, “Ẹ múra kí á bá a jagun;
ẹ dìde kí á lè kọlù ú lọ́sàn-án gangan!”
Wọn óo tún sọ pé, “A gbé! Nítorí pé ọjọ́ ti lọ,
ilẹ̀ sì ti bẹ̀rẹ̀ sí ṣú!
5Ẹ dìde kí á lè kọlù ú, lóru;
kí á wó àwọn ilé ìṣọ́ rẹ̀ lulẹ̀!”
6Nítorí pé OLUWA àwọn ọmọ ogun ti pàṣẹ fún àwọn ọ̀tá pé:
“Ẹ gé àwọn igi tí ó yí Jerusalẹmu ká lulẹ̀;
kí ẹ fi mọ òkítì kí ẹ sì dótì í.
Dandan ni kí n fi ìyà jẹ ìlú náà,
nítorí kìkì ìwà ìninilára ló kún inú rẹ̀.
7Bí omi ṣé ń sun jáde ninu kànga,
bẹ́ẹ̀ ni ibi ń sun ní Jerusalẹmu.
Ìròyìn ìwà ipá ati ti jàgídíjàgan ń kọlura wọn ninu rẹ̀,
àìsàn ati ìpalára ni à ń rí níbẹ̀ nígbà gbogbo.
8Ẹ̀yin ará Jerusalẹmu! Ẹ gbọ́ ìkìlọ̀ tí mò ń ṣe fun yín,
bí bẹ́ẹ̀ kọ́, èmi pẹlu yín óo pínyà,
n óo sì sọ Jerusalẹmu di ahoro,
ẹnikẹ́ni kò sì ní gbé ibẹ̀ mọ́.”
Israẹli Ọlọ̀tẹ̀
9OLUWA àwọn ọmọ ogun ní:
“Ẹ ṣa àwọn ọmọ Israẹli yòókù jọ,
bí ìgbà tí eniyan bá ń ṣa èso àjàrà tókù lẹ́yìn ìkórè.
Tún dá ọwọ́ pada sẹ́yìn, kí o fi wọ́ ara àwọn ẹ̀ka,
bí ẹni tí ń ká èso àjàrà.”
10Mo ní, “Ta ni kí n bá sọ̀rọ̀, tí yóo gbọ́?
Ta ni kí n kìlọ̀ fún tí yóo gbà?
Etí wọn ti di, wọn kò lè gbọ́ràn mọ́.
Ọ̀rọ̀ OLUWA ń rùn létí wọn,
wọn kò fẹ́ gbọ́ mọ́.
11Ibinu ìwọ OLUWA mú kí inú mi máa ru,
ara mi kò sì gbà á mọ́.”
OLUWA bá sọ fún mi pé,
“Tú ibinu mi dà sórí àwọn ọmọde ní ìta gbangba,
ati àwọn ọdọmọkunrin níbi tí wọ́n péjọ sí.
Ogun yóo kó wọn, tọkọtaya,
àtàwọn àgbàlagbà àtàwọn arúgbó kùjọ́kùjọ́.
12Ilé wọn yóo di ilé onílé,
oko wọn, ati àwọn aya wọn pẹlu, yóo di ti ẹni ẹlẹ́ni.
Nítorí pé n óo na ọwọ́ ibinu mi sí àwọn tí ń gbé ilẹ̀ náà.
Èmi OLUWA ni mo sọ bẹ́ẹ̀.”
13OLUWA ní, “Láti orí àwọn mẹ̀kúnnù títí dé orí àwọn eniyan pataki pataki,
gbogbo wọn ni wọ́n fẹ́ràn èrè àjẹjù;
láti orí àwọn wolii títí dé orí àwọn alufaa,
èké ni gbogbo wọn.
14Wọn kò wẹ egbò àwọn eniyan mi jiná,#Isi 13:10
wọ́n ń kígbe pé: ‘Alaafia ni, alaafia ni’,
nígbà tí kò sí alaafia.
15Ǹjẹ́ ojú a tilẹ̀ máa tì wọ́n nígbà tí wọ́n bá ń hu ìwà ìbàjẹ́?#Jer 8:10-12
Rárá o, ojú kì í tì wọ́n; nítorí pé wọn kò lójútì.
Nítorí náà, àwọn náà óo ṣubú nígbà tí àwọn yòókù bá ṣubú,
a ó bì wọ́n ṣubú nígbà tí mo bá ń jẹ wọ́n níyà,
Èmi OLUWA ni mo sọ bẹ́ẹ̀.”
Israẹli Kọ Ọ̀nà Ọlọrun sílẹ̀
16OLUWA ní,
“Ẹ lọ dúró ní oríta kí ẹ wo òréré,
ẹ bèèrè àwọn ọ̀nà àtijọ́,
níbi tí ọ̀nà dáradára wà, kí ẹ sì máa tọ̀ ọ́.
Kí ẹ lè ní ìsinmi.”
Ṣugbọn wọ́n kọ̀, wọ́n ní,
“A kò ní tọ ọ̀nà náà.”
17Mo fi àwọn aṣọ́nà ṣọ́nà nítorí yín.
Mo wí fún wọn pé,
“Ẹ máa dẹtí sílẹ̀ sí fèrè ogun!”
Ṣugbọn wọ́n ní, “A kò ní dẹtí sílẹ̀.”
18OLUWA ní, “Nítorí náà, ẹ gbọ́, ẹ̀yin orílẹ̀-èdè,
kí ẹ̀yin eniyan sì mọ ohun tí yóo ṣẹlẹ̀ sí wọn.
19Gbọ́! Ìwọ ilẹ̀;
n óo fa ibi lé àwọn eniyan wọnyi lórí,
wọn óo jèrè èso ìwà burúkú wọn;
nítorí pé wọn kò fetí sí ọ̀rọ̀ mi,
wọ́n sì ti tàpá sí òfin mi.
20Kí ni anfaani turari,
tí wọn mú wá fún mi láti Ṣeba,
tabi ti ọ̀pá turari olóòórùn dídùn tí ó ti ilẹ̀ òkèèrè wá?
N kò tẹ́wọ́ gba ọrẹ ẹbọ sísun tí ẹ mú wá siwaju mi,
bẹ́ẹ̀ ni ẹbọ yín kò dùn mọ́ mi.
21Nítorí náà, n óo gbé ohun ìdínà sọ́nà fún àwọn eniyan wọnyi,
wọn óo sì fẹsẹ̀ kọ;
ati baba, àtọmọ wọn,
àtaládùúgbò, àtọ̀rẹ́,
gbogbo wọn ni yóo parun.”
Ogun láti Ìhà Àríwá
22OLUWA ní,
“Wò ó, àwọn eniyan kan ń bọ̀ láti ilẹ̀ àríwá,
orílẹ̀-èdè ńlá ń gbéra bọ̀ láti òpin ayé.
23Wọ́n ń kó ọrun ati ọ̀kọ̀ bọ̀,
ìkà ni wọ́n, wọn kò sì lójú àánú.
Ìró wọn dàbí híhó omi òkun,
bí wọ́n ti ń gun ẹṣin bọ̀.
Wọ́n tò bí àwọn tí ń lọ sójú ogun,
wọ́n dótì ọ́, ìwọ Jerusalẹmu!”
24A gbúròó wọn, ọwọ́ wa rọ;
ìdààmú dé bá wa,
bí ìrora obinrin tí ó ń rọbí.
25Ẹ má lọ sinu oko,
ẹ má sì ṣe rìn lójú ọ̀nà náà,
nítorí ọ̀tá mú idà lọ́wọ́,
ìdágìrì sì wà káàkiri.
26Ẹ̀yin eniyan mi,
ẹ wọ aṣọ ọ̀fọ̀, kí ẹ máa yí ninu eérú;
ẹ máa ṣọ̀fọ̀, bí ẹni tí ń ṣọ̀fọ̀ ọmọ rẹ̀ kanṣoṣo;
kí ẹ sì máa sunkún tẹ̀dùntẹ̀dùn,
nítorí pé lójijì ni àwọn apanirun yóo bò yín.
27Mo ti fi ọ́ ṣe ẹni tí yóo máa dán àwọn eniyan mi wò,
o óo máa dán wọn wò bí ẹni dán irin wò,
o óo gbìyànjú láti mọ ọ̀nà wọn,
kí o lè yẹ ọ̀nà wọn wò, kí o sì mọ̀ ọ́n.
28Ọlọ̀tẹ̀, aláìgbọràn ni gbogbo wọn,
wọn á máa sọ̀rọ̀ eniyan lẹ́yìn.
Wọ́n dàbí idẹ àdàlú mọ́ irin,
àmúlùmálà ni gbogbo wọn.
29Lóòótọ́ à ń fi ẹwìrì fẹ́ iná,
òjé sì ń yọ́ lórí iná;
ṣugbọn alágbẹ̀dẹ ń yọ́ irin lásán ni,
kò mú ìbàjẹ́ ara rẹ̀ kúrò.
30Ìdọ̀tí fadaka tí a kọ̀ tì ni wọ́n,
nítorí pé OLUWA ti kọ̀ wọ́n sílẹ̀.
Àwon tá yàn lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí:
JEREMAYA 6: YCE
Ìsàmì-sí
Pín
Daako

Ṣé o fẹ́ fi àwọn ohun pàtàkì pamọ́ sórí gbogbo àwọn ẹ̀rọ rẹ? Wọlé pẹ̀lú àkántì tuntun tàbí wọlé pẹ̀lú àkántì tí tẹ́lẹ̀
Bible Society of Nigeria © 1900/2010