JOBU 40
40
1OLUWA tún sọ fún Jobu pé,
2“Ṣé ẹni tí ń bá eniyan rojọ́ lè bá Olodumare rojọ́?
Kí ẹni tí ń bá Ọlọrun jiyàn dáhùn.”
3Nígbà náà ni Jobu dá OLUWA lóhùn, ó ní:
4“OLUWA, kí ni mo jámọ́,
tí n óo fi dá ọ lóhùn?
Nítorí náà, mo ti dákẹ́ jẹ́ẹ́.
5Mo ti sọ̀rọ̀ ju bí ó ti yẹ lọ,
n kò sì ní sọ̀rọ̀ mọ́.”
6Nígbà náà ni OLUWA tún bá Jobu sọ̀rọ̀ láti inú ìjì líle, ó ní,
7“Múra gírí bí ọkunrin,
mo ní ìbéèrè láti bi ọ́, o óo sì dá mi lóhùn.
8Ṣé o fẹ́ sọ pé mò ń ṣe àìdára ni?
O fẹ́ dá mi lẹ́bi kí á lè dá ọ láre?
9Ṣé o lágbára bí èmi Ọlọrun,
àbí o lè sán wàá bí ààrá, nígbà tí o bá ń sọ̀rọ̀?
10Bí ó bá rí bẹ́ẹ̀, fi ọlá ati ìyìn ṣe ara rẹ lọ́ṣọ̀ọ́,
kí o sì fi ògo ati ẹwà bo ara rẹ bí aṣọ.
11Fi ibinu rẹ hàn, wo gbogbo àwọn agbéraga,
kí o sì rẹ̀ wọ́n sílẹ̀.
12Wo gbogbo àwọn agbéraga, kí o sì sọ wọ́n di yẹpẹrẹ,
rún àwọn ẹni ibi mọ́lẹ̀ ní ipò wọn.
13Bo gbogbo wọn mọ́lẹ̀ papọ̀,
dì wọ́n ní ìgbèkùn sí ipò òkú.
14Nígbà náà ni n óo gbà pé,
agbára rẹ lè fún ọ ní ìṣẹ́gun.
15“Wo Behemoti, ẹran ńlá inú omi,
tí mo dá gẹ́gẹ́ bí mo ti dá ọ,
koríko ni ó ń jẹ bíi mààlúù!
16Wò ó bí ó ti lágbára tó!
Ati irú okun tí awọ inú rẹ̀ ní.
17Ìrù rẹ̀ dúró ṣánṣán bí igi kedari,
gbogbo iṣan itan rẹ̀ dì pọ̀.
18Egungun rẹ̀ dàbí ọ̀pá idẹ,
ọwọ́ ati ẹsẹ̀ rẹ̀ rí bí irin.
19“Ó wà lára àwọn ohun àkọ́kọ́ tí èmi Ọlọrun dá,
sibẹ ẹlẹ́dàá rẹ̀ nìkan ló lè pa á.
20Orí àwọn òkè ni ó ti ń rí oúnjẹ jẹ,
níbi tí àwọn ẹranko ìgbẹ́ ti ń ṣeré.
21Ó dùbúlẹ̀ lábẹ́ igi lotusi,
lábẹ́ ọ̀pá ìyè ninu ẹrẹ̀.
22Igi lotusi ni ó ń ṣíji bò ó,
igi tí ó wà létí odò yí i ká.
23Kò náání ìgbì omi,
kò bẹ̀rù bí odò Jọdani tilẹ̀ ru dé bèbè rẹ̀.
24Ṣé eniyan lè fi ìwọ̀ mú un?
Tabi kí á fi ọ̀kọ̀ lu ihò sí imú rẹ̀?
Àwon tá yàn lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí:
JOBU 40: YCE
Ìsàmì-sí
Pín
Daako
Ṣé o fẹ́ fi àwọn ohun pàtàkì pamọ́ sórí gbogbo àwọn ẹ̀rọ rẹ? Wọlé pẹ̀lú àkántì tuntun tàbí wọlé pẹ̀lú àkántì tí tẹ́lẹ̀
Bible Society of Nigeria © 1900/2010