JOBU 41

41
1“Ṣé o lè fi ìwọ̀ fa Lefiatani jáde,
tabi kí o fi okùn di ahọ́n rẹ̀?
2Ṣé o lè fi okùn sí imú rẹ̀,
tabi kí o fi ìwọ̀ kọ́ ọ ní àgbọ̀n?
3Ṣé yóo bẹ̀ ọ́,
tabi kí ó fi pẹ̀lẹ́pẹ̀lẹ́ bá ọ sọ̀rọ̀?
4Ṣé yóo bá ọ dá majẹmu,
pé kí o fi òun ṣe iranṣẹ títí lae?
5Ṣé o lè máa fi ṣeré bí ọmọ ẹyẹ,
tabi kí o dè é lókùn fún àwọn iranṣẹbinrin rẹ?
6Ṣé àwọn oníṣòwò lè yọwó rẹ̀?
Àbí wọ́n lè pín Lefiatani láàrin ara wọn?
7Ṣé o lè fi ọ̀kọ̀ gún ẹran ara rẹ̀,
tabi kí o fi ẹ̀sín àwọn apẹja gún orí rẹ̀?
8Lọ fọwọ́ kàn án;
kí o wo irú ìjà tí yóo bá ọ jà;
o kò sì ní dán irú rẹ̀ wò mọ́ lae!#O. Daf 74:14; 104:26; Ais 27:1
9“Ìrètí ẹni tí ó bá fẹ́ bá a jà yóo di òfo,
nítorí ojora yóo mú un nígbà tí ó bá rí i.
10Ta ló láyà láti lọ jí i níbi tí ó bá sùn sí?
Ta ló tó kò ó lójú?
11Ta ni mo gba nǹkan lọ́wọ́ rẹ̀ tí mo níláti dá a pada fún un?
Kò sí olúwarẹ̀ ní gbogbo ayé.
12“N kò ní yé sọ̀rọ̀ nípa ẹsẹ̀ rẹ̀,
tabi nípa agbára rẹ̀ tabi dídára ìdúró rẹ̀.
13Ta ló tó bó awọ rẹ̀,
tabi kí ó fi nǹkan gún igbá ẹ̀yìn rẹ̀?
14Ta ló tó ya ẹnu rẹ̀?
Gbogbo eyín rẹ̀ ni ó kún fún ẹ̀rù.
15Ẹ̀yìn rẹ̀ kún fún ìpẹ́ tí ó dàbí apata,
a tò wọ́n lẹ́sẹẹsẹ, wọ́n súnmọ́ ara wọn pẹ́kípẹ́kí bí èdìdì.
16Àwọn ìpẹ́ náà lẹ̀ mọ́ ara wọn tímọ́tímọ́,
tóbẹ́ẹ̀ tí afẹ́fẹ́ kò lè fẹ́ kọjá láàrin wọn.
17Wọ́n so pọ̀,
wọ́n lẹ̀ mọ́ ara wọn tóbẹ́ẹ̀,
tí ohunkohun kò lè ṣí wọn.
18Bí ó bá sín, ìmọ́lẹ̀ á tàn jáde ní imú rẹ̀,
ojú rẹ̀ ń tàn bíi ìmọ́lẹ̀ òwúrọ̀ kutukutu.
19Ahọ́n iná ń yọ lẹ́nu rẹ̀ bí iná tí ń ta jáde,
bẹ́ẹ̀ ni ahọ́n iná ń yọ lálá.
20Èéfín ń jáde ní imú rẹ̀,
bíi ti ìkòkò gbígbóná ati ìgbẹ́ tí ń jó.
21Èémí tí ó ń mí jáde dàbí ògúnná,
ahọ́n iná ń yọ ní ẹnu rẹ̀.
22Kìkì agbára ni ọrùn rẹ̀,
ẹ̀rù jẹ̀jẹ̀ sì ń bẹ níwájú rẹ̀.
23Ìṣẹ́po ẹran ara rẹ̀ lẹ̀ pọ̀ mọ́ ara wọn,
wọ́n lẹ̀ pọ̀, wọn kò sì ṣe é ṣí.
24Ọkàn rẹ̀ le bí òkúta,
ó le ju ọlọ lọ.
25Bí ó bá dìde, ẹ̀rù á ba àwọn alágbára,
wọn á bì sẹ́yìn, wọn á ṣubú lé ara wọn lórí.
26Bí idà tilẹ̀ bá a, kò ràn án,
bẹ́ẹ̀ náà ni ọ̀kọ̀, ati ọfà, ati ẹ̀sín.
27Irin kò yàtọ̀ sí koríko lójú rẹ̀,
idẹ sì dàbí igi tí ó ti rà.
28Bí wọn ta á lọ́fà, kò ní torí rẹ̀ sá,
àwọn òkúta kànnàkànnà dàbí àgékù koríko lójú rẹ̀.
29Kùmọ̀ dàbí koríko lára rẹ̀,
a sì máa fi ẹni tí ó ju ọ̀kọ̀ lù ú rẹ́rìn-ín.
30Ìpẹ́ ikùn rẹ̀ dàbí àpáàdì tí ó mú,
wọn ń fa ilẹ̀ tútù ya bí ọkọ́.
31Ó mú kí ibú hó bí omi inú ìkòkò,
ó ṣe òkun bí ìkòkò òróró ìpara.
32Bí ó bá ń rìn lọ, ipa ọ̀nà rẹ̀ a máa hàn lẹ́yìn rẹ̀,
eniyan á rò pé òkun ń hó bí ọṣẹ ni.
33Kò sí ohun tí a lè fi wé láyé,
ẹ̀dá tí ẹ̀rù kì í bà.
34Ó fojú tẹmbẹlu gbogbo ohun gíga,
ó sì jọba lórí gbogbo àwọn ọmọ agbéraga.”

Àwon tá yàn lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí:

JOBU 41: YCE

Ìsàmì-sí

Pín

Daako

None

Ṣé o fẹ́ fi àwọn ohun pàtàkì pamọ́ sórí gbogbo àwọn ẹ̀rọ rẹ? Wọlé pẹ̀lú àkántì tuntun tàbí wọlé pẹ̀lú àkántì tí tẹ́lẹ̀