MATIU 28
28
Ajinde Jesu
(Mak 16:1-10; Luk 24:1-12; Joh 20:1-10)
1Nígbà tí Ọjọ́ Ìsinmi ti kọjá, tí ilẹ̀ fẹ́rẹ̀ mọ́ ní ọjọ́ kinni ọ̀sẹ̀, Maria Magidaleni ati Maria keji wá wo ibojì Jesu. 2Ilẹ̀ mì tìtì, nítorí angẹli Oluwa sọ̀kalẹ̀ láti ọ̀run wá. Ó yí òkúta tí ó wà lẹ́nu ibojì kúrò, ó sì jókòó lórí rẹ̀. 3Ìrísí rẹ̀ dàbí mànàmáná. Aṣọ rẹ̀ funfun bí ẹ̀gbọ̀n òwú. 4Ẹ̀rù mú kí àwọn tí wọn ń ṣọ́ ibojì náà gbọ̀n pẹ̀pẹ̀, kí wọn sì kú sára.
5Angẹli náà sọ fún àwọn obinrin náà pé, “Ẹ má bẹ̀rù. Mo mọ̀ pé Jesu tí wọ́n kàn mọ́ agbelebu ni ẹ̀ ń wá. 6Kò sí níhìn-ín, nítorí ó ti jí dìde, gẹ́gẹ́ bí ó ti sọ. Ẹ wá wo ibi tí wọ́n tẹ́ ẹ sí. 7Ẹ lọ sọ fún àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ wéré, pé ó ti jí dìde kúrò ninu òkú. Ó ti ṣáájú yín lọ sí Galili; níbẹ̀ ni ẹ óo ti rí i. Ohun tí mo ní sọ fun yín nìyí.”
8Àwọn obinrin náà bá yára kúrò níbi ibojì náà pẹlu ìbẹ̀rùbojo ati ayọ̀ ńlá, wọ́n sáré lọ sọ fún àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀.
9Lójijì Jesu pàdé wọn, ó kí wọn, ó ní, “Ẹ pẹ̀lẹ́ o!” Wọ́n bá dì mọ́ ọn lẹ́sẹ̀, wọ́n júbà rẹ̀. 10Jesu wá sọ fún wọn pé, “Ẹ má bẹ̀rù. Ẹ lọ sọ fún àwọn arakunrin mi pé kí wọ́n lọ sí Galili; níbẹ̀ ni wọn yóo ti rí mi.”
Ìròyìn Àwọn tí Ń Ṣọ́ Ibojì
11Bí wọ́n ti ń lọ, àwọn kan ninu àwọn tí wọ́n fi ṣọ́ ibojì lọ sí inú ìlú láti sọ ohun gbogbo tí ó ṣẹlẹ̀ fún àwọn olórí alufaa. 12Nígbà tí àwọn olórí alufaa ti forí-korí pẹlu àwọn àgbà, wọ́n wá owó tí ó jọjú fún àwọn ọmọ-ogun náà. 13Wọ́n sì kọ́ wọn pé, “Ẹ sọ pé, ‘Àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ wá lóru láti jí òkú rẹ̀ nígbà tí a sùn lọ.’ 14Bí ìròyìn yìí bá dé etí gomina, a óo bá a sọ̀rọ̀, kò ní sí ohunkohun tí yóo ṣẹ̀rù bà yín.”
15Àwọn ọmọ-ogun náà bá gba owó tí wọ́n fún wọn, wọ́n ṣe bí wọ́n ti kọ́ wọn. Èyí náà sì ni ìtàn tí àwọn Juu ń sọ káàkiri títí di òní olónìí.
Jesu Rán Àwọn Ọmọ-ẹ̀yìn Rẹ̀ Níṣẹ́
(Mak 16:14-18; Luk 24:36-49; Joh 20:19-23; A. Apo 1:6-8)
16Àwọn ọmọ-ẹ̀yìn mọkanla lọ sí Galili, sí orí òkè tí Jesu ti sọ fún wọn.#Mat 26:32; Mak 14:28 17Nígbà tí wọn rí i, wọ́n júbà rẹ̀, ṣugbọn àwọn kan ninu wọn ń ṣiyèméjì. 18Jesu wá sọ́dọ̀ wọn, ó sọ fún wọn pé, “A ti fún mi ní gbogbo àṣẹ ní ọ̀run ati ní ayé. 19Nítorí náà kí ẹ lọ sọ gbogbo orílẹ̀-èdè di ọmọ-ẹ̀yìn mi; kí ẹ máa ṣe ìrìbọmi fún wọn ní orúkọ Baba ati ti Ọmọ ati ti Ẹ̀mí Mímọ́.#A. Apo 1:8 20Ẹ máa kọ́ wọn láti kíyèsí gbogbo nǹkan tí mo pa láṣẹ fun yín. Kí ẹ mọ̀ dájú pé mo wà pẹlu yín ní ìgbà gbogbo, títí dé òpin ayé.”
Àwon tá yàn lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí:
MATIU 28: YCE
Ìsàmì-sí
Pín
Daako
Ṣé o fẹ́ fi àwọn ohun pàtàkì pamọ́ sórí gbogbo àwọn ẹ̀rọ rẹ? Wọlé pẹ̀lú àkántì tuntun tàbí wọlé pẹ̀lú àkántì tí tẹ́lẹ̀
Bible Society of Nigeria © 1900/2010