MAKU Ọ̀rọ̀ Iṣaaju

Ọ̀rọ̀ Iṣaaju
Gbolohun tí Ìyìn Rere Maku fi bẹ̀rẹ̀ ọ̀rọ̀ rẹ̀ ni pé: èyí ni àkọsílẹ̀ nípa “ìyìn rere Jesu Kristi Ọmọ Ọlọrun.” Maku fi Jesu hàn bí oníṣẹ́ ati aláṣẹ. Àṣẹ rẹ̀ hàn ninu ìkọ́ni rẹ̀, ati ninu agbára tí ó ní lórí àwọn ẹ̀mí èṣù. Ó sì tún hàn ninu bí ó ṣe ń dárí ẹ̀ṣẹ̀ àwọn eniyan jì wọ́n. Jesu pe ara rẹ̀ ní Ọmọ-Eniyan tí ó wá láti fi ẹ̀mí rẹ̀ rúbọ kí ó lè gba àwọn eniyan kalẹ̀ lọ́wọ́ ẹ̀ṣẹ̀.
Gaaraga ni Maku sọ ìtàn Jesu, ọ̀rọ̀ rẹ̀ sì gúnni lọ́kàn. Àwọn ohun tí Jesu ṣe ni Maku tẹnumọ́ pupọ ju ọ̀rọ̀ tí Jesu sọ lọ. Lẹ́yìn ọ̀rọ̀ iṣaaju díẹ̀ tí ó sọ nípa Johanu Onítẹ̀bọmi ati nípa ìrìbọmi ati ìdánwò Jesu, kíá ni ẹni tí ó kọ ìyìn rere yìí ti bẹ̀rẹ̀ sí sọ nípa iṣẹ́ ìwòsàn ati ti ìkọ́ni tí Jesu ṣe. Bí ọjọ́ ti ń gorí ọjọ́ sí i ni ohun tí Jesu ń ṣe bẹ̀rẹ̀ sí yé àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ sí i, ṣugbọn inú túbọ̀ ń bí àwọn ọ̀tá rẹ̀ sí i ni. Orí bíi mélòó kan tí ó parí ìwé yìí sọ nípa ohun tí ó ṣẹlẹ̀ ninu ọ̀sẹ̀ ìkẹyìn ìgbé-ayé Jesu, pataki jùlọ nípa ìkàn-mọ́-àgbélébùú rẹ̀ ati ajinde rẹ̀.
Ó dàbí ẹni pé ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ ni ẹni tí ó kọ ọ̀rọ̀ ìparí kinni ati ekeji tí ó wà ní ìpẹ̀kun ìwé yìí.
Àwọn Ohun tí ó wà ninu Ìwé yìí ní Ìsọ̀rí-ìsọ̀rí
Ìbẹ̀rẹ̀ ìyìn rere 1:1-13
Iṣẹ́ gbangba tí Jesu ṣe ní Galili 1:14–9:50
Láti Galili dé Jerusalẹmu 10:1-52
Ọ̀sẹ̀ ìkẹyìn ní ìgboro Jerusalẹmu ati ní agbègbè rẹ̀ 11:1–15:47
Ajinde Jesu 16:1-8
Ìfarahàn ati Ìgòkè-re-ọ̀run Oluwa tí ó jinde 16:9-20

Àwon tá yàn lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí:

MAKU Ọ̀rọ̀ Iṣaaju: YCE

Ìsàmì-sí

Pín

Daako

None

Ṣé o fẹ́ fi àwọn ohun pàtàkì pamọ́ sórí gbogbo àwọn ẹ̀rọ rẹ? Wọlé pẹ̀lú àkántì tuntun tàbí wọlé pẹ̀lú àkántì tí tẹ́lẹ̀