NỌMBA 10
10
Àwọn Fèrè Fadaka
1OLUWA sọ fún Mose pé, 2“Fi fadaka tí wọ́n fi òòlù lù ṣe fèrè meji fún pípe àwọn ọmọ Israẹli jọ ati títú ibùdó palẹ̀. 3Nígbà tí àwọn afọnfèrè bá fọn fèrè mejeeji, gbogbo àwọn ọmọ Israẹli yóo wá sọ́dọ̀ rẹ ní ẹnu ọ̀nà Àgọ́ Àjọ. 4Ṣugbọn bí ó bá jẹ́ pé fèrè kan ni wọ́n fọn, àwọn olórí ẹ̀yà Israẹli nìkan ni yóo wá sọ́dọ̀ rẹ. 5Nígbà tí ẹ bá kọ́ fọn fèrè ìdágìrì, àwọn tí wọ́n pa àgọ́ sí ìhà ìlà oòrùn Àgọ́ yóo ṣí, wọn yóo sì tẹ̀síwájú. 6Bí ẹ bá fọn fèrè ìdágìrì lẹẹkeji, àwọn tí wọ́n pàgọ́ sí ìhà gúsù yóo ṣí, wọn yóo sì tẹ̀síwájú. Ìgbàkúùgbà tí ẹ bá fẹ́ tẹ̀síwájú ni kí ẹ máa fọn fèrè ìdágìrì. 7Nígbà tí ẹ bá fẹ́ pe àwọn ọmọ Israẹli jọ ẹ óo máa fọn fèrè, ṣugbọn kò ní jẹ́ ti ìdágìrì. 8Àwọn alufaa, ọmọ Aaroni ni yóo máa fọn fèrè náà.
“Fèrè yìí yóo sì jẹ́ ìlànà fún ìrandíran yín. 9Nígbà tí ẹ bá ń lọ bá àwọn ọ̀tá yín jà lójú ogun láti gba ara yín lọ́wọ́ àwọn tí ń ni yín lára, ẹ óo fọn fèrè ìdágìrì. OLUWA Ọlọrun yín yóo sì ranti yín, yóo sì gbà yín lọ́wọ́ àwọn ọ̀tá yín. 10Ẹ óo máa fọn àwọn fèrè náà ní ọjọ́ ayọ̀, ní àwọn ọjọ́ àjọ̀dún yín ati ní ọjọ́ kinni oṣù. Ẹ óo máa fọn wọ́n nígbà tí ẹ bá mú ọrẹ ẹbọ sísun ati ọrẹ ẹbọ alaafia yín wá fún Ọlọrun. Yóo jẹ́ àmì ìrántí fun yín níwájú Ọlọrun yín. Èmi ni OLUWA Ọlọrun yín.”
Àwọn Ọmọ Israẹli Ṣí Àgọ́ Wọn
11Ní ogúnjọ́ oṣù keji, ní ọdún keji tí àwọn ọmọ Israẹli jáde kúrò ní Ijipti, ìkùukùu tí ó wà ní orí ibi mímọ́ gbéra sókè. 12Àwọn ọmọ Israẹli sì bẹ̀rẹ̀ ìrìn àjò wọn láti aṣálẹ̀ Sinai, wọ́n tò lẹ́sẹẹsẹ. Ìkùukùu náà bá dúró ní aṣálẹ̀ Parani.
13Ìgbà kinni nìyí tí wọn yóo tẹ̀síwájú gẹ́gẹ́ bí àṣẹ tí OLUWA pa láti ẹnu Mose. 14Àwọn tí wọ́n wà lábẹ́ ọ̀págun ẹ̀yà Juda ni wọ́n kọ́kọ́ ṣí, wọ́n tò ní ìsọ̀rí-ìsọ̀rí. Naṣoni ọmọ Aminadabu ni olórí wọn. 15Netaneli ọmọ Suari ni olórí ẹ̀yà Isakari. 16Olórí ẹ̀yà Sebuluni sì ni Eliabu ọmọ Heloni.
17Nígbà tí wọ́n tú Àgọ́ Àjọ palẹ̀, àwọn ọmọ Geriṣoni ati àwọn ọmọ Merari tí ó ru Àgọ́ Àjọ náà ṣí tẹ̀lé àwọn tí wọ́n wà lábẹ́ ọ̀págun Juda.
18Lẹ́yìn náà ni àwọn tí wọ́n wà lábẹ́ ọ̀págun ẹ̀yà Reubẹni ṣí, wọ́n tò ní ìsọ̀rí-ìsọ̀rí. Elisuri ọmọ Ṣedeuri ni olórí wọn. 19Ṣelumieli ọmọ Suriṣadai ni olórí ẹ̀yà Simeoni. 20Olórí ẹ̀yà Gadi sì ni Eliasafu ọmọ Deueli.
21Lẹ́yìn wọn ni àwọn ọmọ Kohati tí wọ́n ru àwọn ohun èlò mímọ́ tó ṣí. Èyí jẹ́ kí àwọn ọmọ Geriṣoni ati àwọn ọmọ Merari rí ààyè láti pa Àgọ́ Àjọ náà kí àwọn ọmọ Kohati tó dé.
22Lẹ́yìn náà ni àwọn tí wọ́n wà lábẹ́ ọ̀págun ẹ̀yà Efuraimu ṣí, wọ́n tò ní ìsọ̀rí-ìsọ̀rí. Eliṣama ọmọ Amihudu ni olórí wọn. 23Gamalieli ọmọ Pedasuri ni olórí ẹ̀yà Manase. 24Olórí ẹ̀yà Bẹnjamini sì ni Abidani ọmọ Gideoni.
25Ní ìparí, àwọn ẹ̀yà tí wọ́n wà lábẹ́ ọ̀págun Dani ṣí, wọ́n tò ní ìsọ̀rí-ìsọ̀rí. Ahieseri ọmọ Amiṣadai ni olórí wọn. 26Pagieli ọmọ Okirani ni olórí ẹ̀yà Aṣeri. 27Olórí ẹ̀yà Nafutali sì ni Ahira ọmọ Enani. 28Bẹ́ẹ̀ ni ètò ìrìn àjò àwọn ọmọ Israẹli rí nígbà tí wọ́n ṣí kúrò ní ibùdó wọn.
29Mose sọ fún Hobabu ọmọ Reueli, baba iyawo rẹ̀, ará Midiani, pé: “Àwa ń lọ sí ilẹ̀ tí OLUWA ti ṣe ìlérí láti fún wa, máa bá wa kálọ, a óo sì ṣe ọ́ dáradára, nítorí OLUWA ti ṣe ìlérí ibukun fún Israẹli.”
30Ṣugbọn Hobabu dá a lóhùn pé: “Rárá o, n óo pada sí ilẹ̀ mi ati sọ́dọ̀ àwọn eniyan mi.”
31Mose sì wí pé: “Jọ̀wọ́ má fi wá sílẹ̀, nítorí pé o mọ aṣálẹ̀ yìí dáradára, o sì lè máa darí wa sí ibi tí ó yẹ kí á pa àgọ́ wa sí. 32Bí o bá bá wa lọ, OLUWA yóo fún ìwọ náà ninu ibukun tí ó bá fún wa.”
Àwọn Eniyan náà Tẹ̀síwájú
33Wọ́n bá gbéra kúrò ní Sinai, òkè OLUWA, wọ́n rìn fún ọjọ́ mẹta. Àpótí Majẹmu OLUWA sì wà níwájú wọn láti bá wọn wá ibi ìsinmi tí wọn yóo pàgọ́ sí. 34Bí wọ́n ti ń ṣí ní ibùdó kọ̀ọ̀kan, ìkùukùu OLUWA ń wà lórí wọn ní ọ̀sán.
35Nígbàkúùgbà tí Àpótí Majẹmu OLUWA bá ṣí, Mose á wí pé, “Dìde, OLUWA, kí o sì tú àwọn ọ̀tá rẹ ká, kí o sì mú kí àwọn tí ó kórìíra rẹ sá.” #O. Daf 68:1 36Nígbàkúùgbà tí ó bá sì dúró, yóo wí pé “OLUWA, pada sọ́dọ̀ ẹgbẹẹgbẹrun àwọn eniyan Israẹli.”
Àwon tá yàn lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí:
NỌMBA 10: YCE
Ìsàmì-sí
Pín
Daako
Ṣé o fẹ́ fi àwọn ohun pàtàkì pamọ́ sórí gbogbo àwọn ẹ̀rọ rẹ? Wọlé pẹ̀lú àkántì tuntun tàbí wọlé pẹ̀lú àkántì tí tẹ́lẹ̀
Bible Society of Nigeria © 1900/2010