NỌMBA 11
11
Ibi tí Wọn sọ ní Tabera
1Nígbà tí ó yá àwọn eniyan náà bẹ̀rẹ̀ sí kùn sí OLUWA nípa ìṣòro wọn. Nígbà tí OLUWA gbọ́ kíkùn wọn, inú bí i, ó sì fi iná jó wọn; iná náà run gbogbo àwọn tí wọ́n wà ní òpin ibùdó náà. 2Àwọn eniyan náà sì ké tọ Mose wá fún ìrànlọ́wọ́. Mose gbadura fún wọn, iná náà sì kú. 3Wọ́n pe orúkọ ibẹ̀ ní Tabera, nítorí níbẹ̀ ni iná OLUWA ti jó láàrin wọn.
Mose Yan Aadọrin Olórí
4Àwọn àjèjì tí wọ́n wà láàrin àwọn ọmọ Israẹli bẹ̀rẹ̀ sí kùn, pé àwọn kò rí ẹran jẹ bí ìgbà tí àwọn wà ní Ijipti. Àwọn ọmọ Israẹli pàápàá bẹ̀rẹ̀ sí sọkún àìrẹ́ran jẹ. Wọ́n ń sọ pé, “Ó mà ṣe o, a kò rí ẹran jẹ! 5Ní Ijipti, à ń jẹ ẹja ati apálà, ẹ̀gúsí, ewébẹ̀, alubọsa ati galiki. 6Ṣugbọn nisinsinyii, a kò lókun ninu mọ́, kò sí ohun tí a rí jẹ bíkòṣe mana yìí nìkan lojoojumọ.”
7Mana náà sì dàbí èso korianda, tí àwọ̀ rẹ̀ dàbí kóró òkúta bideliumi. 8Àwọn eniyan náà a máa lọ kó wọn láàárọ̀, wọn á lọ̀ ọ́ tabi kí wọn gún un lódó láti fi ṣe ìyẹ̀fun. Wọn á sè é ninu ìkòkò, wọn á fi ṣe bíi àkàrà, adùn rẹ̀ sì dàbí ti àkàrà dídùn tí a fi òróró olifi dín.#Eks 16:31 9Òròòru ni mana náà máa ń bọ́ nígbà tí ìrì bá ń sẹ̀ ní ibùdó.#Eks 16:13-15
10Mose gbọ́ bí àwọn eniyan náà ti ń sọkún lẹ́nu ọ̀nà àgọ́ wọn, olukuluku pẹlu àwọn ará ilé rẹ̀. Ọ̀rọ̀ náà dun Mose, ibinu OLUWA sì ru sí àwọn eniyan náà. 11Mose bá wí fún OLUWA pé, “Kí ló dé tí o ṣe mí báyìí? Kí ló dé tí n kò rí ojurere rẹ, tí o sì di ẹrù gbogbo àwọn eniyan wọnyi rù mí? 12Ṣé èmi ni mo lóyún wọn ni, àbí èmi ni mo bí wọn, tí o fi sọ fún mi pé kí n gbé wọn gẹ́gẹ́ bí ọmọ ọmú lọ sí ilẹ̀ tí o ti ṣe ìlérí fún àwọn baba wọn. 13Níbo ni kí n ti rí ẹran tí yóo tó fún àwọn eniyan wọnyi? Wò ó! Wọ́n ń sọkún níwájú mi; wọ́n ń wí pé kí n fún àwọn ní ẹran jẹ. 14Èmi nìkan kò lè ṣe àkóso àwọn eniyan wọnyi; ẹrù náà wúwo jù fún mi. 15Bí ó bá jẹ́ pé bí o óo ti ṣe mí nìyí, mo bẹ̀ ọ́, kúkú pa mí bí inú rẹ bá yọ́ sí mi, kí n má baà kan àbùkù.”
16OLUWA bá sọ fún Mose pé, “Yan aadọrin ninu àwọn àgbààgbà Israẹli, àwọn tí àwọn ọmọ Israẹli mọ̀ ní olórí, kí o sì mú wọn wá sí ẹnu ọ̀nà Àgọ́ Àjọ. Kí wọ́n dúró pẹlu rẹ níbẹ̀. 17N óo wá bá ọ sọ̀rọ̀ níbẹ̀. N óo mú lára ẹ̀mí tí ó wà lára rẹ, n óo fi sí wọn lára; kí wọn lè máa ràn ọ́ lọ́wọ́, láti gbé ẹrù àwọn eniyan náà, kí ìwọ nìkan má baà máa ṣe iṣẹ́ náà. 18Sọ fún àwọn ọmọ Israẹli pé kí ẹ ya ara yín sí mímọ́, ẹ óo jẹ ẹran lọ́la. OLUWA ti gbọ́ ẹkún ati ìráhùn yín pé, ‘Ta ni yóo fún wa ní ẹran jẹ, ó sàn fún wa jù báyìí lọ ní ilẹ̀ Ijipti.’ Nítorí náà OLUWA yóo fun yín ní ẹran. 19Kì í ṣe èyí tí ẹ óo jẹ ní ọjọ́ kan, tabi ọjọ́ meji, tabi ọjọ́ marun-un, bẹ́ẹ̀ ni kì í ṣe fún ọjọ́ mẹ́wàá, tabi fún ogúnjọ́. 20Ṣugbọn odidi oṣù kan ni ẹ óo fi jẹ ẹ́, títí tí yóo fi fẹ́rẹ̀ hù lórí yín, tí yóo sì sú yín, nítorí pé ẹ ti kọ OLUWA tí ó wà láàrin yín sílẹ̀, ẹ sì ti ráhùn níwájú rẹ̀ pé: ‘Kí ló dé tí a fi kúrò ní Ijipti.’ ”
21Mose sì sọ fún OLUWA pé, “Àwọn tí wọn tó ogun jà nìkan ninu àwọn eniyan tí mò ń ṣe àkóso wọn yìí jẹ́ ọgbọ̀n ọ̀kẹ́ (600,000) o sì wí pé o óo fún wọn ní ẹran jẹ fún oṣù kan. 22Ṣé a lè rí mààlúù tabi aguntan tí yóo tó láti pa fún wọn? Ǹjẹ́ gbogbo ẹja tí ó wà ninu òkun tó fún wọn bí?”
23OLUWA dá Mose lóhùn, ó ní, “Ǹjẹ́ nǹkankan wà tí ó ṣòro fún èmi OLUWA láti ṣe bí? O óo rí i bóyá ohun tí mo sọ fún ọ yóo ṣẹ, tabi kò ní ṣẹ.”
24Mose jáde, ó lọ sọ ohun tí OLUWA sọ fún àwọn ọmọ Israẹli; ó sì mú àwọn aadọrin olórí náà wá sí ẹnu ọ̀nà Àgọ́ Àjọ. 25OLUWA sọ̀kalẹ̀ ninu ìkùukùu láti bá Mose sọ̀rọ̀. Ó sì mú lára ẹ̀mí tí ó wà lára Mose, ó fi sára àwọn aadọrin olórí náà. Bí ẹ̀mí náà ti bà lé wọn, wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí sọ àsọtẹ́lẹ̀, ṣugbọn wọn kò sọ àsọtẹ́lẹ̀ mọ́ lẹ́yìn ọjọ́ náà.
26Meji ninu àwọn olórí náà: Elidadi ati Medadi, kò bá wọn lọ, wọ́n dúró sinu àgọ́ wọn. Ẹ̀mí Ọlọrun bà lé wọn, wọ́n sì ń sọ àsọtẹ́lẹ̀. 27Ọmọkunrin kan sáré wá sọ fún Mose pé Elidadi ati Medadi ń sọ àsọtẹ́lẹ̀.
28Nígbà náà ni Joṣua, ọmọ Nuni, iranṣẹ Mose, ọ̀kan ninu àwọn olùrànlọ́wọ́ rẹ̀ wí fún Mose pé, “Pa wọ́n lẹ́nu mọ́.”
29Mose dáhùn pé, “Kí ló dé tí o fi ń jowú nítorí mi? Inú mi ìbá dùn bí OLUWA bá lè fún gbogbo àwọn eniyan rẹ̀ ní ẹ̀mí rẹ̀ kí wọ́n sì máa sọ àsọtẹ́lẹ̀.” 30Lẹ́yìn náà Mose ati àwọn aadọrin olórí náà pada sí ibùdó.
OLUWA Darí Àwọn Àparò Sọ́dọ̀ Wọn
31OLUWA sì rán ìjì ńlá jáde, ó kó àwọn ẹyẹ kéékèèké kan wá láti etí òkun, wọ́n bà sí ẹ̀gbẹ́ ibùdó àwọn ọmọ Israẹli. Wọn kò fò ju igbọnwọ meji lọ sílẹ̀, wọ́n wà ní ẹ̀yìn ibùdó káàkiri ní ìwọ̀n ìrìn ọjọ́ kan. 32Àwọn eniyan náà kó ẹyẹ ní ọ̀sán ati ní òru, ẹni tí ó kó kéré jù ni ó kó òṣùnwọ̀n homeri mẹ́wàá. Wọ́n sì sá wọn sílẹ̀ yí ibùdó wọn ká. 33Nígbà tí wọn ń jẹ ẹran náà, ibinu OLUWA ru sí wọn, ó sì mú kí àjàkálẹ̀ àrùn jà láàrin wọn. 34Wọ́n pe orúkọ ibẹ̀ ní Kiburotu Hataafa, èyí tí ó túmọ̀ sí ibojì ojúkòkòrò, nítorí níbẹ̀ ni wọ́n sin òkú àwọn tí wọ́n ṣe ojúkòkòrò ẹran sí.
35Àwọn eniyan náà sì ṣí kúrò níbẹ̀ lọ sí Haserotu, wọ́n sì pàgọ́ wọn sibẹ.
Àwon tá yàn lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí:
NỌMBA 11: YCE
Ìsàmì-sí
Pín
Daako
Ṣé o fẹ́ fi àwọn ohun pàtàkì pamọ́ sórí gbogbo àwọn ẹ̀rọ rẹ? Wọlé pẹ̀lú àkántì tuntun tàbí wọlé pẹ̀lú àkántì tí tẹ́lẹ̀
Bible Society of Nigeria © 1900/2010