NỌMBA 12
12
Ìjìyà Miriamu
1Miriamu ati Aaroni sọ̀rọ̀ òdì sí Mose nítorí pé ó fẹ́ ọmọbinrin ará Kuṣi ní iyawo. 2Wọn ń wí pé, “Ṣé Mose nìkan ni OLUWA ti lò láti bá eniyan sọ̀rọ̀ ni? Ṣé kò ti lo àwa náà rí?” OLUWA sì gbọ́ ọ̀rọ̀ tí wọn ń sọ. 3Mose ni ó jẹ́ oníwà ìrẹ̀lẹ̀ jù ninu gbogbo ẹni tí ó wà láyé.#Sir 45:4
4Lójijì, OLUWA sọ fún Mose, Aaroni, ati Miriamu pé, “Ẹ wá sí ẹnu ọ̀nà Àgọ́ Àjọ.” 5OLUWA sì dúró ní ẹnu ọ̀nà Àgọ́ Àjọ ninu ọ̀wọ̀n ìkùukùu, ó sì pe Aaroni ati Miriamu, àwọn mejeeji sì jáde siwaju. 6OLUWA sì sọ fún wọn pé, “Ẹ gbọ́ ohun tí n óo sọ yìí: Nígbà tí àwọn wolii wà láàrin yín, èmi a máa fi ara hàn wọ́n ninu ìran, èmi a sì máa bá wọn sọ̀rọ̀ lójú àlá. 7Ṣugbọn ti Mose, iranṣẹ mi yàtọ̀. Mo ti fi ṣe alákòóso àwọn eniyan mi.#Heb 3:2 8Lojukooju ni èmi í máa bá a sọ̀rọ̀; ọ̀rọ̀ ketekete sì ni, kì í ṣe àdììtú ọ̀rọ̀. Kódà, òun a máa rí ìrísí OLUWA. Kí ló dé tí ẹ kò fi bẹ̀rù ati sọ̀rọ̀ òdì sí i?”
9Inú sì bí OLUWA sí àwọn mejeeji, ó sì kúrò lọ́dọ̀ wọn. 10Bí ọ̀wọ̀n ìkùukùu tí ó wà ní ẹnu ọ̀nà Àgọ́ Àjọ ti gbéra sókè ni ẹ̀tẹ̀ bo Miriamu, ó sì funfun bí ẹ̀gbọ̀n òwú. Nígbà tí Aaroni wo Miriamu ó ri wí pé ó ti di adẹ́tẹ̀. 11Aaroni sì wí fún Mose pe, “Olúwa mi, jọ̀wọ́ má jẹ́ kí á jìyà ẹ̀ṣẹ̀ ìwà àìgbọ́n wa. 12Má jẹ́ kí ó dàbí ọmọ tí ó ti kú kí á tó bí i, tí apákan ara rẹ̀ sì ti jẹrà.”
13Mose ké pe Ọlọrun kí ó wò ó sàn.
14OLUWA sì dáhùn pé, “Bí baba rẹ̀ bá tutọ́ sí i lójú, ṣé ìtìjú rẹ̀ kò ha ní wà lára rẹ̀ fún ọjọ́ meje ni? Nítorí náà, jẹ́ kí wọ́n fi sí ẹ̀yìn ibùdó fún ọ̀sẹ̀ kan, lẹ́yìn náà, kí wọ́n mú un pada.”#Nọm 5:2-3. 15Wọ́n sì fi Miriamu sí ẹ̀yìn ibùdó fún ọjọ́ meje, àwọn eniyan náà kò sì kúrò níbẹ̀ títí di ìgbà tí wọ́n mú un pada. 16Lẹ́yìn náà, wọ́n ṣí kúrò ni Haserotu, wọ́n sì pa àgọ́ wọn sí aṣálẹ̀ Parani.
Àwon tá yàn lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí:
NỌMBA 12: YCE
Ìsàmì-sí
Pín
Daako
Ṣé o fẹ́ fi àwọn ohun pàtàkì pamọ́ sórí gbogbo àwọn ẹ̀rọ rẹ? Wọlé pẹ̀lú àkántì tuntun tàbí wọlé pẹ̀lú àkántì tí tẹ́lẹ̀
Bible Society of Nigeria © 1900/2010