ÌWÉ ÒWE 14
14
1Ọlọ́gbọ́n obinrin a máa kọ́ ilé rẹ̀,
ṣugbọn òmùgọ̀ a máa fi ọwọ́ ara rẹ̀ tú tirẹ̀ palẹ̀.
2Ẹni tí ń rìn pẹlu òótọ́ inú yóo bẹ̀rù OLUWA,
ṣugbọn ẹni tí ń rin ìrìn ségesège yóo kẹ́gàn rẹ̀.
3Ọ̀rọ̀ ẹnu òmùgọ̀ dàbí pàṣán ní ẹ̀yìn ara rẹ̀,
ṣugbọn ọ̀rọ̀ ọlọ́gbọ́n a máa dáàbò bò ó.
4Níbi tí kò bá sí mààlúù tí ń tu ilẹ̀, kò lè sí oúnjẹ,
ṣugbọn agbára ọpọlọpọ mààlúù níí mú ọpọlọpọ ìkórè wá.
5Ẹlẹ́rìí òtítọ́ kì í parọ́,
ṣugbọn irọ́ ṣá ni ti ẹlẹ́rìí èké.
6Pẹ̀gànpẹ̀gàn a máa wá ọgbọ́n, sibẹ kò ní rí i,
ṣugbọn ati ní ìmọ̀ kò ṣòro fún ẹni tí ó ní òye.
7Yẹra fún òmùgọ̀,
nítorí o kò lè gbọ́ ọ̀rọ̀ ọlọ́gbọ́n lẹ́nu rẹ̀.
8Ohun tí ó jẹ́ ọgbọ́n fún ọlọ́gbọ́n
ni pé kí ó kíyèsí ọ̀nà ara rẹ̀,
ṣugbọn àìmòye àwọn òmùgọ̀ kún fún ìtànjẹ.
9Àwọn òmùgọ̀ a máa fi ọ̀rọ̀ ẹ̀ṣẹ̀ ṣe àwàdà,
ṣugbọn àwọn olódodo a máa rí ojurere.
10Kálukú ló mọ ìbànújẹ́ ọkàn ara rẹ̀,
kò sì sí àjèjì tí ń báni pín ninu ayọ̀.
11Ìdílé ẹni ibi yóo parun,
ṣugbọn ilé olódodo yóo máa gbèrú títí lae.
12Ọ̀nà kan wà tí ó dàbí ẹni pé ó tọ́ lójú eniyan,#Owe 16:25
ṣugbọn òpin rẹ̀, ikú ni.
13Eniyan lè máa rẹ́rìn-ín, kí inú rẹ̀ má dùn,
ìbànújẹ́ sì le gbẹ̀yìn ayọ̀.
14Alágàbàgebè yóo jèrè iṣẹ́ ọwọ́ rẹ̀ lẹ́kùn-únrẹ́rẹ́,
ẹni rere yóo sì jèrè ìwà rere rẹ̀.
15Òpè eniyan a máa gba ohun gbogbo gbọ́,
ṣugbọn ọlọ́gbọ́n a máa kíyèsí ibi tí ó ń lọ.
16Ọlọ́gbọ́n a máa ṣọ́ra, a sì máa sá fún ibi,
ṣugbọn òmùgọ̀ kì í rọra ṣe, kì í sì í bìkítà.
17Onínúfùfù a máa hùwà òmùgọ̀,
ṣugbọn onílàákàyè a máa ní sùúrù.
18Àwọn òpè a máa jogún àìgbọ́n,
ṣugbọn àwọn ọlọ́gbọ́n a máa dé adé ìmọ̀.
19Àwọn ẹni ibi yóo tẹríba fún àwọn ẹni rere,
àwọn eniyan burúkú yóo sì tẹríba lẹ́nu ọ̀nà àwọn olódodo.
20Àwọn aládùúgbò talaka pàápàá kórìíra rẹ̀,
ṣugbọn ọlọ́rọ̀ a máa ní ọpọlọpọ ọ̀rẹ́.
21Ẹni tí ó kẹ́gàn aládùúgbò rẹ̀ dẹ́ṣẹ̀,
ṣugbọn ayọ̀ ń bẹ fun ẹni tí ó bá ṣàánú talaka.
22Àwọn tí wọn ń pète ibi ti ṣìnà,
ṣugbọn àwọn tí wọn ń gbèrò ire yóo rí ojurere ati òtítọ́.
23Kò sí iṣẹ́ kan tí kò lérè,
ṣugbọn ọ̀rọ̀ ẹnu lásán láìsí iṣẹ́, a máa sọ eniyan di aláìní.
24Ọgbọ́n ni adé àwọn ọlọ́gbọ́n,
ṣugbọn ìwà aláìgbọ́n jẹ́ yẹ̀yẹ́ àwọn òmùgọ̀.
25Ẹlẹ́rìí tòótọ́ a máa gba ẹ̀mí là,
ṣugbọn ọ̀dàlẹ̀ ni òpùrọ́.
26Ninu ìbẹ̀rù OLUWA ni igbẹkẹle tí ó dájú wà,
níbẹ̀ ni ààbò wà fún àwọn ọmọ ẹni.
27Ìbẹ̀rù OLUWA ni orísun ìyè,
òun níí mú ká yẹra fún tàkúté ikú.
28Ọ̀pọ̀ eniyan ni ògo ọba,
olórí tí kò bá ní eniyan yóo parun.
29Ẹni tí kì í báá yára bínú lóye lọpọlọpọ,
ṣugbọn onínúfùfù ń fi ìwà òmùgọ̀ rẹ̀ hàn.
30Ìbàlẹ̀ ọkàn a máa mú kí ara dá ṣáṣá,
ṣugbọn ìlara a máa dá egbò sinu eegun.
31Ẹni tí ó bá ni talaka lára àbùkù Ẹlẹ́dàá rẹ̀ ni ó ń ta,
ṣugbọn ẹni tí ó ṣàánú fún àwọn aláìní ń bu ọlá fún Ẹlẹ́dàá rẹ̀.
32Eniyan burúkú ṣubú nítorí ìwà ibi rẹ̀,
ṣugbọn olódodo rí ààbò nípasẹ̀ òtítọ́ inú rẹ̀.
33Ọgbọ́n kún inú ẹni tí ó mòye,
ṣugbọn kò sí ohun tí ó jọ ọgbọ́n lọ́kàn òmùgọ̀.
34Òdodo ní ń gbé orílẹ̀-èdè lékè,
ṣugbọn ẹ̀ṣẹ̀ jẹ́ ẹ̀gàn fún orílẹ̀-èdè.
35Iranṣẹ tí ó bá hùwà ọlọ́gbọ́n a máa rí ojurere ọba,
ṣugbọn inú a máa bí ọba sí iranṣẹ tí ó bá hùwà ìtìjú.
Àwon tá yàn lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí:
ÌWÉ ÒWE 14: YCE
Ìsàmì-sí
Pín
Daako
Ṣé o fẹ́ fi àwọn ohun pàtàkì pamọ́ sórí gbogbo àwọn ẹ̀rọ rẹ? Wọlé pẹ̀lú àkántì tuntun tàbí wọlé pẹ̀lú àkántì tí tẹ́lẹ̀
Bible Society of Nigeria © 1900/2010