ÌWÉ ÒWE 15
15
1Ìdáhùn pẹ̀lẹ́ a máa mú kí ibinu rọlẹ̀,
ṣugbọn ọ̀rọ̀ líle níí ru ibinu sókè.
2Lẹ́nu ọlọ́gbọ́n ni ọ̀rọ̀ ìmọ̀ ti ń jáde,
ṣugbọn òmùgọ̀ a máa sọ̀rọ̀ agọ̀.
3Ojú OLUWA wà níbi gbogbo,
ó ń ṣọ́ àwọn eniyan burúkú ati àwọn eniyan rere.
4Ọ̀rọ̀ tí a fi pẹ̀lẹ́ sọ dàbí igi ìyè,
ṣugbọn ọ̀rọ̀ ẹ̀tàn a máa bani lọ́kàn jẹ́.
5Òmùgọ̀ ọmọ á kẹ́gàn ìtọ́sọ́nà baba rẹ̀,
ṣugbọn ọmọ tí ó gbọ́ ìkìlọ̀, ọlọ́gbọ́n ni.
6Ilé olódodo kún fún ọpọlọpọ ìṣúra,
ṣugbọn kìkì ìdààmú ni àkójọ èrè eniyan burúkú.
7Ẹnu ọlọ́gbọ́n a máa tan ìmọ̀ kálẹ̀,
ṣugbọn ti òmùgọ̀ kò rí bẹ́ẹ̀.
8Ohun ìríra ni ẹbọ eniyan burúkú lójú OLUWA,
ṣugbọn adura olódodo jẹ́ ìdùnnú rẹ̀.
9OLUWA kórìíra ìwà àwọn eniyan burúkú,
ṣugbọn ó fẹ́ràn àwọn tí ń hùwà òdodo.
10Ìbáwí pupọ ń bẹ fún ẹni tí ó yapa kúrò ní ọ̀nà rere,
ẹni tí ó bá kórìíra ìbáwí yóo kú.
11Isà òkú ati ìparun kò pamọ́ lójú OLUWA,
mélòó-mélòó ni ọkàn eniyan.
12Inú pẹ̀gànpẹ̀gàn kì í dùn sí ìbáwí,
kì í bèèrè ìmọ̀ràn lọ́wọ́ ọlọ́gbọ́n.
13Inú dídùn a máa múni dárayá,
ṣugbọn ìbànújẹ́ a máa mú kí ojú eniyan rẹ̀wẹ̀sì.
14Ẹni tí ó ní òye a máa wá ìmọ̀,
ṣugbọn agọ̀ ni oúnjẹ òmùgọ̀.
15Gbogbo ọjọ́ ayé ẹni tí a ni lára kún fún ìpọ́njú,
ṣugbọn ojoojumọ ni ọdún fún ẹni tí inú rẹ̀ dùn.
16Ó sàn kí á jẹ́ talaka, kí á sì ní ìbẹ̀rù OLUWA,
ju kí á jẹ́ ọlọ́rọ̀, kí á sì kún fún ìyọnu lọ.
17Ọbẹ̀ ẹ̀fọ́ pẹlu ìfẹ́,
sàn ju ẹran mààlúù tòun ti ìkórìíra lọ.
18Onínúfùfù a máa rú ìjà sókè,
ṣugbọn onínútútù a máa pẹ̀tù sí ibinu.
19Ẹ̀gún kún bo ọ̀nà ọ̀lẹ,
ṣugbọn ọ̀nà olódodo dàbí òpópó tí ń dán.
20Ọlọ́gbọ́n ọmọ a máa mú inú baba rẹ̀ dùn,
ṣugbọn òmùgọ̀ ọmọ níí kẹ́gàn ìyá rẹ̀.
21Ayọ̀ ni ìwà òmùgọ̀ jẹ́ fún aláìgbọ́n,
ṣugbọn ẹni tí ó ní òye a máa rìn ní ọ̀nà ẹ̀tọ́.
22Àìsí ìmọ̀ràn a máa mú kí ètò dàrú,
ṣugbọn ọpọlọpọ ìmọ̀ràn a máa mú kí ó yọrí sí rere.
23Ìdáhùn kíkún a máa fúnni láyọ̀,
kí ọ̀rọ̀ bọ́ sí àsìkò dára lọpọlọpọ!
24Ọ̀nà ọlọ́gbọ́n lọ tààrà sinu ìyè,
kí ó má baà bọ́ sinu isà òkú.
25OLUWA a máa wó ilé agbéraga,
ṣugbọn ó ṣe àmójútó ààlà opó.
26Ohun ìríra ni èrò ọkàn ẹni ibi lójú OLUWA,
ṣugbọn ọrọ̀ àwọn ẹni mímọ́ jẹ́ dídùn inú rẹ̀.
27Àwọn tí ń ṣojúkòkòrò èrè àìtọ́ ń kó ìyọnu bá ilé wọn,
ṣugbọn àwọn tí wọn kórìíra àbẹ̀tẹ́lẹ̀ yóo yè.
28Olódodo a máa ronú kí ó tó fèsì ọ̀rọ̀,
ṣugbọn ọ̀rọ̀ burúkú níí máa jáde lẹ́nu àwọn eniyan burúkú.
29OLUWA jìnnà sí eniyan burúkú,
ṣugbọn a máa gbọ́ adura olódodo.
30Ọ̀yàyà a máa mú inú dùn,
ìròyìn ayọ̀ a sì máa mú ara yá.
31Ẹni tó gbọ́ ìbáwí rere
yóo wà láàrin àwọn ọlọ́gbọ́n.
32Ẹni tí kò náání ìbáwí tàbùkù ara rẹ̀,
ṣugbọn ẹni tí ó bá gba ìmọ̀ràn yóo ní òye.
33Ìbẹ̀rù OLUWA níí kọ́ni lọ́gbọ́n,
ìwà ìrẹ̀lẹ̀ níí ṣáájú iyì.
Àwon tá yàn lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí:
ÌWÉ ÒWE 15: YCE
Ìsàmì-sí
Pín
Daako
Ṣé o fẹ́ fi àwọn ohun pàtàkì pamọ́ sórí gbogbo àwọn ẹ̀rọ rẹ? Wọlé pẹ̀lú àkántì tuntun tàbí wọlé pẹ̀lú àkántì tí tẹ́lẹ̀
Bible Society of Nigeria © 1900/2010