1
ÌWÉ ÒWE 15:1
Yoruba Bible
Ìdáhùn pẹ̀lẹ́ a máa mú kí ibinu rọlẹ̀, ṣugbọn ọ̀rọ̀ líle níí ru ibinu sókè.
Ṣe Àfiwé
Ṣàwárí ÌWÉ ÒWE 15:1
2
ÌWÉ ÒWE 15:33
Ìbẹ̀rù OLUWA níí kọ́ni lọ́gbọ́n, ìwà ìrẹ̀lẹ̀ níí ṣáájú iyì.
Ṣàwárí ÌWÉ ÒWE 15:33
3
ÌWÉ ÒWE 15:4
Ọ̀rọ̀ tí a fi pẹ̀lẹ́ sọ dàbí igi ìyè, ṣugbọn ọ̀rọ̀ ẹ̀tàn a máa bani lọ́kàn jẹ́.
Ṣàwárí ÌWÉ ÒWE 15:4
4
ÌWÉ ÒWE 15:22
Àìsí ìmọ̀ràn a máa mú kí ètò dàrú, ṣugbọn ọpọlọpọ ìmọ̀ràn a máa mú kí ó yọrí sí rere.
Ṣàwárí ÌWÉ ÒWE 15:22
5
ÌWÉ ÒWE 15:13
Inú dídùn a máa múni dárayá, ṣugbọn ìbànújẹ́ a máa mú kí ojú eniyan rẹ̀wẹ̀sì.
Ṣàwárí ÌWÉ ÒWE 15:13
6
ÌWÉ ÒWE 15:3
Ojú OLUWA wà níbi gbogbo, ó ń ṣọ́ àwọn eniyan burúkú ati àwọn eniyan rere.
Ṣàwárí ÌWÉ ÒWE 15:3
7
ÌWÉ ÒWE 15:16
Ó sàn kí á jẹ́ talaka, kí á sì ní ìbẹ̀rù OLUWA, ju kí á jẹ́ ọlọ́rọ̀, kí á sì kún fún ìyọnu lọ.
Ṣàwárí ÌWÉ ÒWE 15:16
8
ÌWÉ ÒWE 15:18
Onínúfùfù a máa rú ìjà sókè, ṣugbọn onínútútù a máa pẹ̀tù sí ibinu.
Ṣàwárí ÌWÉ ÒWE 15:18
9
ÌWÉ ÒWE 15:28
Olódodo a máa ronú kí ó tó fèsì ọ̀rọ̀, ṣugbọn ọ̀rọ̀ burúkú níí máa jáde lẹ́nu àwọn eniyan burúkú.
Ṣàwárí ÌWÉ ÒWE 15:28
Ilé
Bíbélì
Àwon ètò
Àwon Fídíò