ÌWÉ ÒWE 25

25
Àwọn Òwe Mìíràn tí Solomoni Pa
1Àwọn òwe mìíràn tí Solomoni pa,
tí àwọn òṣìṣẹ́ Hesekaya ọba Juda kọ sílẹ̀ nìwọ̀nyí.
2Ògo ni ó jẹ́ fún Ọlọrun láti fi nǹkan pamọ́,
ṣugbọn ògo ló sá tún jẹ́ fún ọba
láti wádìí nǹkan ní àwárí.
3Bí ọ̀run ti ga, tí ilẹ̀ sì jìn,
bẹ́ẹ̀ ni ẹnikẹ́ni kò lè mọ ohun tí ó wà lọ́kàn àwọn ọba.
4Yọ́ gbogbo ìdọ̀tí tí ó wà lára fadaka kúrò,
alágbẹ̀dẹ yóo sì rí fadaka fi ṣe ohun èlò.
5Mú àwọn olùdámọ̀ràn ibi kúrò lọ́dọ̀ ọba,
a óo sì fi ìdí ìjọba rẹ̀ múlẹ̀ pẹlu òdodo.
6Má ṣe gbéraga níwájú ọba,#Luk 14:8-10
tabi kí o jókòó ní ipò àwọn eniyan pataki,
7nítorí ó sàn kí ó wí fún ọ pé,
“Máa bọ̀ lókè níhìn-ín”,
jù pé kí ó rẹ̀ ọ́ sílẹ̀ níwájú ọlọ́lá kan lọ.
8Má fi ìwàǹwára fa ẹnikẹ́ni lọ sílé ẹjọ́,
nítorí kí ni o óo ṣe nígbà tí aládùúgbò rẹ bá dójútì ọ́.
9Bí o bá ń bá aládùúgbò rẹ ṣe àríyànjiyàn
má ṣe tú àṣírí ẹlòmíràn,
10kí ẹni tí ó bá gbọ́ má baà dójútì ọ́,
kí o má baà sọ ara rẹ lórúkọ.
11Ọ̀rọ̀ tí a sọ lákòókò tí ó yẹ
dàbí ohun ọ̀ṣọ́ wúrà tí a gbé sinu àwo fadaka.
12Ìbáwí ọlọ́gbọ́n dàbí òrùka wúrà,
tabi ohun ọ̀ṣọ́ tí a fi wúrà ṣe,
fún ẹni tí ó ní etí láti fi gbọ́.
13Bí òtútù yìnyín nígbà ìkórè,
bẹ́ẹ̀ ni olóòótọ́ iranṣẹ jẹ́, sí àwọn tí ó rán an,
a máa fi ọkàn àwọn oluwa rẹ̀ balẹ̀.
14Bí òjò tí ó ṣú dudu tí ó fẹ́ atẹ́gùn títí
ṣugbọn tí kò rọ̀,
ni ẹni tí ó ń fọ́nnu láti fúnni lẹ́bùn,
tí kò sì fúnni ní nǹkankan.
15Pẹlu sùúrù, a lè yí aláṣẹ lọ́kàn pada
ọ̀rọ̀ pẹ̀lẹ́ sì lè fọ́ eegun.
16Bí o bá rí oyin, lá a níwọ̀nba,
má lá a ní àlájù, kí o má baà bì.
17Má máa lọ sílé aládùúgbò rẹ lemọ́lemọ́,
kí ọ̀rọ̀ rẹ má baà sú u, kí ó sì kórìíra rẹ.
18Ẹni tí ó jẹ́rìí èké nípa aládùúgbò rẹ̀
dàbí kùmọ̀ ọmọ ogun, tabi idà, tabi ọfà tí ó mú.
19Igbẹkẹle ninu alaiṣootọ ní àkókò ìṣòro,
dàbí eyín tí ń ro ni, tabi ẹsẹ̀ tí ó rọ́.
20Bí ẹni tí a bọ́ṣọ rẹ̀ ninu òtútù,
tabi tí a da ọtí kíkan sójú egbò rẹ̀,
ni ẹni tí à ń kọrin fún ní àkókò tí inú rẹ̀ bàjẹ́.
21Bí ebi bá ń pa ọ̀tá rẹ, fún un ní oúnjẹ jẹ,
bí òùngbẹ bá ń gbẹ ẹ́, fún un ní omi mu.
22Nípa bẹ́ẹ̀ o óo wa ẹ̀yinná lé e lórí,#Rom 12:20
OLUWA yóo sì san ẹ̀san rere fún ọ.
23Bí ẹ̀fúùfù ìhà àríwá tíí mú òjò wá,
bẹ́ẹ̀ ni òfófó ṣíṣe máa ń fa kí a máa fi ojú burúkú woni.
24Ó sàn kí á máa gbé kọ̀rọ̀ kan lókè àjà,
ju pé kí eniyan máa bá oníjàngbọ̀n obinrin gbé ilé lọ.
25Gẹ́gẹ́ bí omi tútù ti rí fún ẹni tí òùngbẹ ń gbẹ,
ni ìròyìn ayọ̀ láti ilẹ̀ òkèèrè rí.
26Olódodo tí ó fi ààyè sílẹ̀ fún eniyan burúkú
dàbí odò tí omi rẹ̀ dàrú
tabi kànga tí a da ìdọ̀tí sí.
27Kò dára kí eniyan lá oyin ní àlájù,
bẹ́ẹ̀ ni kò dára kí eniyan máa wá iyì ní àwájù.
28Ẹni tí kò lè kó ara rẹ̀ níjàánu,
dàbí ìlú tí ọ̀tá wọ̀,
tí wọ́n sì wó odi rẹ̀ lulẹ̀.

Àwon tá yàn lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí:

ÌWÉ ÒWE 25: YCE

Ìsàmì-sí

Pín

Daako

None

Ṣé o fẹ́ fi àwọn ohun pàtàkì pamọ́ sórí gbogbo àwọn ẹ̀rọ rẹ? Wọlé pẹ̀lú àkántì tuntun tàbí wọlé pẹ̀lú àkántì tí tẹ́lẹ̀