ORIN DAFIDI 102
102
Adura Olùpọ́njú
1Gbọ́ adura mi, OLUWA;
kí o sì jẹ́ kí igbe mi dé ọ̀dọ̀ rẹ.
2Má yọwọ́ lọ́ràn mi lọ́jọ́ ìṣòro!
Dẹtí sí adura mi;
kí o sì tètè dá mi lóhùn nígbà tí mo bá ké pè ọ́.
3Nítorí ọjọ́ ayé mi ń kọjá lọ bí èéfín,
eegun mi gbóná bí iná ààrò.
4Ìdààmú bá ọkàn mi, mo rọ bíi koríko,
tóbẹ́ẹ̀ tí mo gbàgbé láti jẹun.
5Nítorí igbe ìrora mi,
mo rù kan eegun.
6Mo dàbí igúnnugún inú aṣálẹ̀,
àní, bí òwìwí inú ahoro.
7Mo dùbúlẹ̀ láìlè sùn,
mo dàbí ẹyẹ tí ó dá wà lórí òrùlé.
8Àwọn ọ̀tá ń fi mí ṣe yẹ̀yẹ́ tọ̀sán-tòru,
àwọn tí wọn ń pẹ̀gàn mi ń fi orúkọ mi ṣépè.
9Mò ń jẹ eérú bí oúnjẹ,
mo sì ń mu omijé mọ́ omi
10nítorí ìrúnú ati ibinu rẹ;
o gbé mi sókè,
o sì jù mí nù.
11Ọjọ́ ayé mi ń lọ bí òjìji àṣáálẹ́,
mo sì ń rọ bíi koríko.
12Bẹ́ẹ̀ sì ni ìwọ OLUWA gúnwà títí lae,
ọlá rẹ sì wà láti ìran dé ìran.
13Ìwọ óo dìde, o óo sì ṣàánú Sioni,
nítorí ó tó àkókò láti fi ojú àánú wò ó.
Àkókò tí o dá tó.
14Nítorí àwọn òkúta rẹ̀ ṣe iyebíye lójú àwọn iranṣẹ rẹ,
àánú rẹ̀ sì ṣeni bí ó tilẹ̀ ti wó dà sinu erùpẹ̀.
15Àwọn orílẹ̀-èdè yóo máa bẹ̀rù orúkọ OLUWA,
gbogbo ọba ayé ni yóo sì máa bẹ̀rù ògo rẹ̀.
16Nítorí OLUWA yóo tún Sioni kọ́,
yóo sì fara hàn ninu ògo rẹ̀.
17Yóo gbọ́ adura àwọn aláìní,
kò sì ní kẹ́gàn ẹ̀bẹ̀ wọn.
18Kí ẹ kọ èyí sílẹ̀ fún ìran tí ń bọ̀,
kí àwọn ọmọ tí a kò tíì bí lè máa yin OLUWA,
19pé OLUWA bojú wo ilẹ̀ láti òkè mímọ́ rẹ̀,
láti ọ̀run ni ó ti bojú wo ayé;
20láti gbọ́ ìkérora àwọn ìgbèkùn,
ati láti dá àwọn tí a dájọ́ ikú fún sílẹ̀.
21Kí á lè pòkìkí orúkọ OLUWA ní Sioni,
kí á sì máa yìn ín lógo ní Jerusalẹmu,
22nígbà tí àwọn orílẹ̀-èdè bá péjọ tàwọn tọba wọn,
láti sin OLUWA.
23Ó ti gba agbára mi ní àìpé ọjọ́,
ó ti gé ọjọ́ ayé mi kúrú.
24Mo ní, “Áà! Ọlọrun mi, má mú mi kúrò láyé láìpé ọjọ́,
ìwọ tí ọjọ́ ayé rẹ kò lópin.”
25Láti ìgbà laelae ni o ti fi ìpìlẹ̀ ayé sọlẹ̀,
iṣẹ́ ọwọ́ rẹ sì ni ọ̀run.
26Wọn óo parẹ́ ṣugbọn ìwọ yóo wà títí lae;
gbogbo wọn yóo gbó bí aṣọ,
o óo pààrọ̀ wọn bí aṣọ;
wọn yóo sì di ohun ìpatì.
27Ṣugbọn ìwọ wà bákan náà,
ọjọ́ ayé rẹ kò sì lópin.
28Ọmọ àwọn iranṣẹ rẹ yóo ní ibùgbé;
bẹ́ẹ̀ ni arọmọdọmọ wọn yóo fẹsẹ̀ múlẹ̀ níwájú rẹ.#Heb 1:10-12
Àwon tá yàn lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí:
ORIN DAFIDI 102: YCE
Ìsàmì-sí
Pín
Daako
Ṣé o fẹ́ fi àwọn ohun pàtàkì pamọ́ sórí gbogbo àwọn ẹ̀rọ rẹ? Wọlé pẹ̀lú àkántì tuntun tàbí wọlé pẹ̀lú àkántì tí tẹ́lẹ̀
Bible Society of Nigeria © 1900/2010