ORIN DAFIDI 43
43
Adura Ẹni tí A Lé ní Ìlú
1Dá mi láre, Ọlọrun, kí o sì gbèjà mi,
lọ́dọ̀ àwọn tí kò mọ̀ Ọ́;
gbà mí lọ́wọ́ àwọn ẹlẹ́tàn ati alaiṣootọ.
2Nítorí ìwọ ni Ọlọrun tí mo sá di.
Kí ló dé tí o fi ta mí nù?
Kí ló dé tí mo fi ń ṣọ̀fọ̀ kiri
nítorí ìnilára ọ̀tá?
3Rán ìmọ́lẹ̀ rẹ ati òtítọ́ rẹ jáde,
jẹ́ kí wọ́n máa tọ́ mi sọ́nà;
jẹ́ kí wọ́n mú mi wá sí orí òkè mímọ́ rẹ,
ati ibùgbé rẹ.
4Nígbà náà ni n óo lọ sí ibi pẹpẹ Ọlọrun,
àní, sọ́dọ̀ Ọlọrun, ayọ̀ ńlá mi.
Èmi óo sì yìn ọ́ pẹlu hapu,
Ọlọrun, Ọlọrun mi.
5Ìwọ ọkàn mi, kí ló dé tí o fi rẹ̀wẹ̀sì?
Kí ló dé tí ara rẹ kò fi balẹ̀ ninu mi?
Gbẹ́kẹ̀ rẹ lé Ọlọrun; nítorí pé n óo tún yìn ín,
olùrànlọ́wọ́ mi ati Ọlọrun mi.
Àwon tá yàn lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí:
ORIN DAFIDI 43: YCE
Ìsàmì-sí
Pín
Daako
Ṣé o fẹ́ fi àwọn ohun pàtàkì pamọ́ sórí gbogbo àwọn ẹ̀rọ rẹ? Wọlé pẹ̀lú àkántì tuntun tàbí wọlé pẹ̀lú àkántì tí tẹ́lẹ̀
Bible Society of Nigeria © 1900/2010