ORIN DAFIDI 88
88
Adura nígbà ìpọ́njú
1OLUWA, Ọlọrun, Olùgbàlà mi, mo ké pè ọ́ fún ìrànlọ́wọ́ ní ọ̀sán;
mo ké níwájú rẹ ní òru.
2Jẹ́ kí adura mi dé ọ̀dọ̀ rẹ;
tẹ́tí sí igbe mi.
3Nítorí pé ọkàn mi kún fún ìyọnu;
mo sì súnmọ́ isà òkú.
4Mo dàbí àwọn tí ó ń wọ ibojì lọ;
mo dà bí ẹni tí kò lágbára mọ.
5N kò yàtọ̀ sí ẹni tí a pa tì sí apá kan láàrin àwọn òkú,
mo dàbí ẹni tí a pa, tí ó sùn ninu ibojì,
bí àwọn tí ìwọ kò ranti mọ́,
nítorí pé wọ́n ti kúrò lábẹ́ ìtọ́jú rẹ.
6O ti fi mí sinu isà òkú tí ó jìn pupọ,
ninu òkùnkùn, àní ninu ọ̀gbun.
7Ọwọ́ ibinu rẹ wúwo lára mi,
ìgbì ìrúnú rẹ sì bò mí mọ́lẹ̀.
8O ti mú kí àwọn ọ̀rẹ́ kòríkòsùn mi fi mí sílẹ̀;
mo sì ti di ẹni ìríra lọ́dọ̀ wọn:
mo wà ninu àhámọ́, n kò sì lè jáde;
9ojú mi ti di bàìbàì nítorí ìbànújẹ́.
Lojoojumọ ni mò ń ké pè ọ́, OLUWA;
tí mò ń tẹ́wọ́ adura sí ọ.
10Ṣé òkú ni o óo ṣe iṣẹ́ ìyanu hàn?
Ṣé àwọn òkú lè dìde kí wọ́n máa yìn ọ́?
11Ṣé a lè sọ̀rọ̀ ìfẹ́ rẹ tí kì í yẹ̀ ninu ibojì?
Àbí ẹnìkan lè sọ̀rọ̀ òtítọ́ rẹ ninu ìparun?
12Ṣé a lè rí iṣẹ́ ìyanu rẹ ninu òkùnkùn ikú?
Àbí ìrànlọ́wọ́ ìgbàlà rẹ wà ní ilẹ̀ àwọn tí a ti gbàgbé?
13Ṣugbọn OLUWA, èmi ń ké pè ọ́;
ní òwúrọ̀ n óo gbadura sí ọ.
14OLUWA, kí ló dé tí o fi ta mí nù?
Kí ló dé tí o fi ojú pamọ́ fún mi?
15Láti ìgbà èwe mi ni a tí ń jẹ mí níyà,
tí mo sì fẹ́rẹ̀ kú,
mo ti rí ìjẹníyà rẹ tí ó bani lẹ́rù;
agara sì ti dá mi.
16Ìrúnú rẹ bò mí mọ́lẹ̀;
ẹ̀rù rẹ sì bà mí dójú ikú.
17Wọ́n yí mi ká tọ̀sán-tòru bí ìṣàn omi ńlá;
wọ́n ká mi mọ́ patapata.
18O ti mú kí ọ̀rẹ́ kòríkòsùn mi ati àwọn alábàárìn mi kọ̀ mí sílẹ̀;
òkùnkùn nìkan ni ó yí mi ká níbi gbogbo.
Àwon tá yàn lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí:
ORIN DAFIDI 88: YCE
Ìsàmì-sí
Pín
Daako
Ṣé o fẹ́ fi àwọn ohun pàtàkì pamọ́ sórí gbogbo àwọn ẹ̀rọ rẹ? Wọlé pẹ̀lú àkántì tuntun tàbí wọlé pẹ̀lú àkántì tí tẹ́lẹ̀
Bible Society of Nigeria © 1900/2010