ORIN DAFIDI 89

89
Majẹmu Ọlọrun pẹlu Dafidi#1A. Ọba 4:31
1OLUWA, n óo máa kọrin ìfẹ́ rẹ tí kì í yẹ̀ títí lae;
n óo máa fi ẹnu mi kéde òtítọ́ rẹ láti ìran dé ìran.
2Nítorí pé, a ti fi ìdí ìfẹ́ rẹ tí kì í yẹ̀ múlẹ̀ títí lae;
o sì ti fi ìdí òtítọ́ rẹ múlẹ̀ bí ojú ọ̀run.
3O sọ pé, “Mo ti dá majẹmu kan pẹlu
ẹni tí mo yàn,
mo ti búra fún Dafidi, iranṣẹ mi, pé,
4‘N óo fi ìdí àwọn ọmọ rẹ múlẹ̀ títí lae,
n óo sì gbé ìtẹ́ rẹ ró láti ìran dé ìran.’ ”#2Sam 7:12-16; 1Kron 17:11-14; O. Daf 132:11; A. Apo 2:30
5Jẹ́ kí ojú ọ̀run máa kọrin ìyìn iṣẹ́ ìyanu rẹ, OLÚWA;
kí àwọn eniyan mímọ́ sì máa kọrin ìyìn òtítọ́ rẹ.
6Nítorí ta ni a lè fi wé ọ ní ọ̀run, OLUWA?
Ta ni ó dàbí OLUWA láàrin àwọn ẹ̀dá ọ̀run?
7Ọlọrun, ìwọ ni a bẹ̀rù ninu ìgbìmọ̀ àwọn eniyan mímọ́,
o tóbi, o sì lẹ́rù ju gbogbo àwọn tí ó yí ọ ká lọ?
8OLUWA, Ọlọrun àwọn ọmọ ogun, ta ló lágbára bíi rẹ?
OLUWA, òtítọ́ rẹ yí ọ ká.
9Ò ń jọba lórí òkun tí ń ru;
nígbà tí ìgbì rẹ̀ bá ru sókè, ìwọ ni ò ń mú kí ó rọlẹ̀.
10Ìwọ ni o wó Rahabu#89:10 Rahabu: Orúkọ erinmi burúkú kan ninu ìtàn àwọn Heberu. mọ́lẹ̀ bí òkú ẹran;
o fi ọwọ́ agbára rẹ fọ́n àwọn ọ̀tá rẹ ká.
11Tìrẹ ni ọ̀run, tìrẹ sì ni ayé pẹlu;
ìwọ ni o tẹ ayé ati gbogbo ohun tí ó wà ninu rẹ̀ dó.
12Ìwọ ni o dá àríwá ati gúsù,
òkè Tabori ati òkè Herimoni ń fi ayọ̀
yin orúkọ rẹ.
13Alágbára ni ọ́;
agbára ń bẹ ní ọwọ́ rẹ;
o gbé ọwọ́ agbára rẹ sókè.
14Òdodo ati ẹ̀tọ́ ni ìpìlẹ̀ ìtẹ́ rẹ;
ìfẹ́ tí kì í yẹ̀ ati òtítọ́ ń lọ ṣiwaju rẹ.
15Ayọ̀ ń bẹ fún àwọn tí ó mọ ìhó ayọ̀ nnì,
àwọn tí ń rìn ninu ìmọ́lẹ̀ ojurere rẹ, OLUWA,
16àwọn tí ń yọ̀ nítorí orúkọ rẹ tọ̀sán-tòru,
tí sì ń gbé òdodo rẹ lárugẹ.
17Nítorí ìwọ ni ògo ati agbára wọn;
nípa ojurere rẹ sì ni a ti ní ìṣẹ́gun.
18Dájúdájú, OLUWA, tìrẹ ni ààbò wa;
ìwọ, Ẹni Mímọ́ Israẹli ni ọba wa.
Ìlérí Ọlọrun fun Dafidi
19Ní ìgbàanì, o sọ ninu ìran fún olùfọkànsìn rẹ pé,
“Mo ti fi adé dé alágbára kan lórí,
mo ti gbé ẹnìkan ga tí a yàn láàrin àwọn eniyan.
20Mo ti rí Dafidi, iranṣẹ mi;
mo ti fi òróró mímọ́ mi yàn án;
21kí ọwọ́ agbára mi lè máa gbé e ró títí lae,
kí ọwọ́ mi sì máa fún un ní okun.
22Ọ̀tá kan kò ní lè borí rẹ̀,
bẹ́ẹ̀ ni àwọn eniyan burúkú kò ní tẹ orí rẹ̀ ba.
23N óo run ọ̀tá rẹ̀ níwájú rẹ̀;
n óo sì bá àwọn tí ó kórìíra rẹ̀ kanlẹ̀.
24Òtítọ́ mi ati ìfẹ́ mi tí kì í yẹ̀ yóo wà pẹlu rẹ̀;
orúkọ mi ni yóo sì máa fi ṣẹgun.
25N óo mú ìjọba rẹ̀ gbòòrò dé òkun;
agbára rẹ̀ yóo sì tàn dé odò Yufurate
26Yóo ké pè mí pé, ‘Ìwọ ni Baba mi,
Ọlọrun mi, ati Àpáta ìgbàlà mi.’
27N óo fi ṣe àkọ́bí,
àní, ọba tí ó tóbi ju gbogbo ọba ayé lọ.
28N óo máa fi ìfẹ́ mi tí kì í yẹ̀ hàn án títí lae;
majẹmu èmi pẹlu rẹ̀ yóo sì dúró ṣinṣin.
29Arọmọdọmọ rẹ̀ ni yóo máa jọba títí lae;
ìtẹ́ rẹ̀ yóo sì máa bẹ níwọ̀n ìgbà tí ojú ọ̀run bá ń bẹ.#(a) 1 Sam 13:14; A. Apo 13:22 (b) 1 Sam 16:12 #Ifi 1:5
30“Bí àwọn ọmọ rẹ̀ bá kọ òfin mi sílẹ̀,
tí wọn kò sì tẹ̀lé ìlànà mi,
31bí wọ́n bá tàpá sí àṣẹ mi,
tí wọn kò sì pa òfin mi mọ́;
32n óo nà wọ́n lẹ́gba nítorí ẹ̀ṣẹ̀ wọn,
n óo sì nà wọ́n ní pàṣán nítorí àìdára wọn.
33Ṣugbọn ìfẹ́ mi tí kì í yẹ̀ kò ní kúrò lára rẹ̀,
bẹ́ẹ̀ ni n kò ní yẹ òtítọ́ mi.
34N kò ni yẹ majẹmu mi,
bẹ́ẹ̀ ni n kò ní yí ọ̀rọ̀ tí mo ti sọ pada.
35“Níwọ̀n ìgbà tí mo ti fi ìwà mímọ́ mi búra:
n kò ní purọ́ fún Dafidi.
36Arọmọdọmọ rẹ̀ ni yóo máa jọba títí lae,
ìtẹ́ rẹ̀ yóo sì máa wà níwájú mi, níwọ̀n ìgbà tí oòrùn bá ń yọ.
37A óo fi ìdí rẹ̀ múlẹ̀ bí òṣùpá títí lae,
yóo dúró ṣinṣin níwọ̀n ìgbà tí ojú ọ̀run bá ń bẹ.”
Ìdárò Ìṣubú Ọba
38Ṣugbọn nisinsinyii inú rẹ ti ru sí ẹni àmì òróró rẹ;
o ti ta á nù,
o sì ti kọ̀ ọ́ sílẹ̀.
39O ti pa majẹmu tí o bá iranṣẹ rẹ dá tì,
o ti ba adé rẹ̀ jẹ́, o ti fi wọ́lẹ̀.
40O ti wó gbogbo odi rẹ̀;
o sì ti sọ ilé ìṣọ́ rẹ̀ di ahoro.
41Gbogbo àwọn tí ń kọjá lọ ní ń kó o lẹ́rù;
ó ti di ẹni ẹ̀gàn lọ́dọ̀ àwọn aládùúgbò rẹ̀.
42O ti ran àwọn ọ̀tá rẹ̀ lọ́wọ́;
o ti mú kí àwọn ọ̀tá rẹ̀ yọ̀ ọ́.
43Àní, o ti ba gbogbo ohun ìjà rẹ̀ jẹ́,
o kò sì ràn án lọ́wọ́ lójú ogun.
44O ti gba ọ̀pá àṣẹ lọ́wọ́ rẹ̀;
o sì ti wó ìtẹ́ rẹ̀ palẹ̀.
45O ti gé ìgbà èwe rẹ̀ kúrú;
o sì ti da ìtìjú bò ó.
Adura ìdáǹdè
46Yóo ti pẹ́ tó, OLUWA? Ṣé títí lae ni o óo máa fi ara pamọ́ fún mi?
Yóo ti pẹ́ tó tí ibinu rẹ yóo máa jò bí iná?
47OLUWA, ranti bí ọjọ́ ayé ẹ̀dá ti gùn mọ,
ati pé ẹ̀dá lásán ni ọmọ eniyan!
48Ta ló wà láyé tí kò ní kú?
Ta ló lè gba ẹ̀mí ara rẹ̀ lọ́wọ́ agbára isà òkú?
49OLUWA, níbo ni ìfẹ́ rẹ ìgbàanì tí kì í yẹ̀ wà,
tí o búra fún Dafidi pẹlu òtítọ́ rẹ?
50OLUWA, ranti bí èmi, iranṣẹ rẹ, ti di ẹni yẹ̀yẹ́;
ati bí mo ti ń farada ẹ̀gàn àwọn eniyan,
51OLUWA àwọn ọ̀tá rẹ ń fi ẹni tí o fi àmì òróró yàn ṣe yẹ̀yẹ́,
wọ́n sì ń kẹ́gàn ìrìn ẹsẹ̀ rẹ̀.
52Ẹni ìyìn ni OLUWA títí lae!
Amin! Amin!
ÌWÉ ORIN KẸRIN
(Orin Dafidi 90–106)

Àwon tá yàn lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí:

ORIN DAFIDI 89: YCE

Ìsàmì-sí

Pín

Daako

None

Ṣé o fẹ́ fi àwọn ohun pàtàkì pamọ́ sórí gbogbo àwọn ẹ̀rọ rẹ? Wọlé pẹ̀lú àkántì tuntun tàbí wọlé pẹ̀lú àkántì tí tẹ́lẹ̀