SAKARAYA 1

1
OLUWA Pe Àwọn Eniyan Rẹ̀ Pada Sọ́dọ̀
1Ní oṣù kẹjọ, ọdún keji ìjọba Dariusi, OLUWA rán wolii Sakaraya, ọmọ Berekaya, ọmọ Ido, sí àwọn ọmọ Israẹli; ó ní, 2“Èmi OLUWA bínú sí àwọn baba ńlá yín. Nítorí náà, 3èmi OLUWA àwọn ọmọ ogun ní kí ẹ pada wá sọ́dọ̀ mi, èmi náà yóo sì pada sọ́dọ̀ yín. 4Ẹ má ṣe bí àwọn baba ńlá yín, tí àwọn wolii mi rọ̀ títí pé kí wọ́n jáwọ́ ninu ìgbé-ayé burúkú, kí wọ́n jáwọ́ ninu iṣẹ́ ibi, ṣugbọn tí wọ́n kọ̀, tí wọn kò gbọ́. 5Níbo ni àwọn baba ńlá yín ati àwọn wolii wà nisinsinyii? Ǹjẹ́ wọ́n wà mọ́? 6Ǹjẹ́ ọ̀rọ̀ mi ati ìlànà mi tí àwọn wolii, iranṣẹ mi, sọ kò ṣẹ sí àwọn baba ńlá yín lára?” Àwọn eniyan náà bá ronupiwada, wọ́n ní, “OLUWA àwọn ọmọ ogun ti ṣe wá bí ó ti pinnu láti ṣe, nítorí ìwà burúkú ati iṣẹ́ ibi wa.”#Ẹsr 4:24–5:1; 6:14
Ìran nípa Àwọn Ẹṣin
7Ní ọjọ́ kẹrinlelogun oṣù kọkanla tíí ṣe oṣù Ṣebati, ní ọdún keji ìjọba Dariusi, OLUWA fi ìran kan han wolii Sakaraya ọmọ Berekaya, ọmọ Ido. 8Mo rí ìran kan lóru. Ninu ìran náà, mo rí ọkunrin kan lórí ẹṣin pupa, láàrin àwọn igi kan tí wọ́n ń pè ní mitili, láàrin àfonífojì kan. Àwọn ẹṣin pupa, ati ẹṣin rẹ́súrẹ́sú ati ẹṣin funfun dúró lẹ́yìn rẹ̀. 9Mo bá bèèrè pé, “OLUWA mi, kí ni ìtumọ̀ kinní wọnyi?”#a Ifi 6:4 b Ifi 6:2
Angẹli tí ń bá mi sọ̀rọ̀ sì dáhùn pé, “N óo sọ ìtumọ̀ wọn fún ọ.” 10Ọkunrin tí ó dúró láàrin àwọn igi mitili náà bá dáhùn pé, “Àwọn wọnyi ni àwọn tí OLUWA rán láti máa rin ilẹ̀ ayé wò.”
11Wọ́n sì jíṣẹ́ fún angẹli OLUWA, tí ó dúró láàrin àwọn igi mitili náà pé, “A ti lọ rin ilẹ̀ ayé wò jákèjádò, a sì rí i pé wọ́n wà ní alaafia ati ìdákẹ́rọ́rọ́.”
12Angẹli OLUWA bá dáhùn pé, “OLUWA àwọn ọmọ ogun, yóo ti pẹ́ tó kí o tó yọ́nú sí Jerusalẹmu ati àwọn ìlú Juda, tí o tí ń bínú sí láti aadọrin ọdún sẹ́yìn?”
13OLUWA sì dá angẹli tí ń bá mi sọ̀rọ̀ lóhùn pẹlu ọ̀rọ̀ ìtùnú. 14Angẹli náà bá sọ fún mi pé kí n lọ kéde pé OLUWA àwọn ọmọ ogun ní, “Mo ní ìfẹ́ ati ìtara tí ó jinlẹ̀ pupọ fún Jerusalẹmu ati Sioni. 15Inú sì ń bí mi gidigidi sí àwọn orílẹ̀-èdè tí wọ́n dákẹ́ jẹ́ẹ́ tí wọ́n sì wà ní alaafia; nítorí pé, nígbà tí mo bínú díẹ̀ sí àwọn eniyan mi, wọ́n tún dá kún ìṣòro wọn ni. 16Nítorí náà, mo ti pada sí Jerusalẹmu láti ṣàánú fún un: a óo tún ilé mi kọ́ sibẹ, a óo sì tún ìlú Jerusalẹmu kọ́.”
17Angẹli náà tún sọ fún mi pé, “Lọ kéde pé OLUWA àwọn ọmọ ogun ní, àwọn ìlú òun yóo tún kún fún ọrọ̀ lẹ́ẹ̀kan sí i, òun OLUWA yóo tu Sioni ninu, òun óo sì tún yan Jerusalẹmu ní àyànfẹ́ òun.”
Ìran nípa Àwọn ìwo
18Bí mo ti gbé ojú sókè ni mo rí ìwo mààlúù mẹrin, 19mo sì bèèrè ìtumọ̀ ohun tí mo rí lọ́wọ́ angẹli tí ń bá mi sọ̀rọ̀.
Ó bá dá mi lóhùn pé, “Àwọn ìwo wọnyi dúró fún àwọn alágbára ayé tí wọ́n fọ́n Juda, Israẹli, ati Jerusalẹmu ká.”
20Lẹ́yìn náà, OLUWA fi àwọn alágbẹ̀dẹ mẹrin kan hàn mí. 21Mo bèèrè pé, “Kí ni àwọn wọnyi ń bọ̀ wá ṣe?”
Ó bá dáhùn pé, “Àwọn ìwo wọnyi dúró fún àwọn tí wọ́n fọ́n Juda ká patapata, tóbẹ́ẹ̀ tí kò ku ẹnìkan mọ́. Ṣugbọn àwọn alágbẹ̀dẹ wọnyi wá láti dẹ́rùba àwọn orílẹ̀-èdè tí wọ́n fọ́n Juda ká, ati láti fọ́n àwọn náà ká.”

Àwon tá yàn lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí:

SAKARAYA 1: YCE

Ìsàmì-sí

Pín

Daako

None

Ṣé o fẹ́ fi àwọn ohun pàtàkì pamọ́ sórí gbogbo àwọn ẹ̀rọ rẹ? Wọlé pẹ̀lú àkántì tuntun tàbí wọlé pẹ̀lú àkántì tí tẹ́lẹ̀